cleaned_text
stringlengths
6
2.09k
source
stringclasses
2 values
language
stringclasses
1 value
Ìjàpá lọ bá alákàn ṣe àdéhùn kó fún òun ní omi, òun yóò ma fún ní iṣu paro..
wikipedia
yo
Ìjàpá ni ki Alákàn ran ọmọ rẹ̀ tẹ̀lé Òun ló gba iṣu, Alákàn ran àbígbẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀lé ìjàpá, nígbàtí ọmọ alákàn tẹ̀lé ìjàpá délẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí níí kọrin bú báyìíorin Alọ́bọ délẹ̀ ó kankan àlùgbgó p’o sápá kángun kangùn àlùg ó p'ó ṣe ẹsẹ̀ kángun kangún àlùgáàdì ó pe ẹ̀yìn ẹ̀yìn ló fi ń rin họg ìjàpá pa ọmọ Alákàn, ó sì ṣeé jẹ nígbà tí Alákàn reti ọmọ rẹ̀ títí tí kò rí, ó tún rán ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ, bí ìjàpá tún ṣe rí eléyìí orin ló mú sí ẹnu tó sì fọ́ póńpó mọ́ lórí, tó sì pa..
wikipedia
yo
Alákàn ní àwọn ọmọ òun bàjẹ́ púpọ̀, ó rán ìkẹta ìkẹrin , ẹ̀karùn, ẹ̀kẹfà àti èkeje, nígbàtí èkeje dé bẹ̀ ó dọ̀bálẹ̀ fún ìjàpá, ó bèèrè àwọn àbúrò rẹ̀,Alabahùn ni òun kò rí wọn ó ní bàbá òun ni kí òun gba iṣu wá, ìjàpá bá tún mú orin èébú sí ẹnu, ló bá fọ́ igi mọ́ lórí..
wikipedia
yo
Ni alákàn bá gbéra ó dilé Alabahun, igbà tó dé ibẹ̀, ìjàpá ni ilé ni òhún wà látàárọ̀, òun kò ri ọmọ kankan, orí alákàn gbóná, ó fura pé ìjàpá ti pa àwọn ọmọ òun, ó pa mọ́ra, ó fi ẹ̀jẹ̀ sínú tu itọ́ funfun jáde, àwọn méjèèjì jọ nwá ọmọ kiri, ibẹ̀ ni Alákàn ti rí igbá eyín àwọn ọmọ rẹ̀, ó sọ fún ìjàpá pé ilẹ̀ ti ṣú kí olúkúlùkù padà sílé, ó gba iṣu lọ́wọ́ ìjàpá kó má baà fura pé òun ti mọ..
wikipedia
yo
Ní ọjọ́ kejì ìjàpá lọ sí ilé Alákàn láti gba omi, Alákàn gba garawa lọ́wọ́ ìjàpá, ó wọ inú ihò rẹ̀ lọ, ó ga owó Ẹmúga rẹ̀ sílẹ̀, ó ní kí ìjàpá na ọwọ́ kó fa garawa omi rẹ̀ síta, ìjàpá na ọwọ́ rẹ̀ kò tó omi, alákàn ni kò náwó dáadáa kò gbó rí wọlé, bí Alákàn ṣe fi ẹmu mú lọ́rùn mọ́lẹ̀ ní yìí tó sì pa ìjàpá.Èkó ààlọ́v yìí kọ́ wa wípé òwú jíjẹ kò dára, ìtẹ́lọ́rùn ló dára, bí ènìyàn bá ń jowú ọ̀nà àti bá nkan jẹ ni yóò máa san.Àwọn ìtọ́kasí..
wikipedia
yo
ààlọ̀ ìjàpá àti ajá ààlọ́ ooooo ààlọ́ mi dá fíríò, ó dá lórí ìjàpá àti Àjàní ìlú kan ní ayé àtijọ́, àwọn ẹranko méjì kan wà tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́..
wikipedia
yo
Àwọn ọ̀rẹ́ méjì náà ní Ìjàpátìrókò ọkọ yánníbo àti ajà..
wikipedia
yo
Ìyàn mú púpọ̀ ní ìlú yìí débi wípé gbogbo igi wọ́wé tán, àgbàdo kò kọ́ gbó, àwọn ọlọ́mọge lóyún, oyún gbẹ́ mọ́ wọn lára..
wikipedia
yo
Ṣugbọn bí ìyàn ti mú tòò, ajá kò mọ ìyàn kankan, ṣe ni ara rẹ̀ ń dán yóo..
wikipedia
yo
Bí ajá ṣe ń dán tí ó tún sanra nínú iyán yìí ń kọ ìjàpá lóminú..
wikipedia
yo
Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ sí ro ohun ti yio ṣe.Nigba ti ó ṣe ìjàpá tó ọ̀rẹ́ rẹ̀ ajá lọ..
wikipedia
yo
Ó bẹ́ẹ̀ pé kí ó dákun ṣàánú òun kí ebi má lu òun àti àwọn ẹbí òun pa..
wikipedia
yo
Ajá sọ fún ìjàpá pé kó wu òun náà kí ẹbí máa paá ṣùgbọ́n ìwà àgàbàgebè rẹ̀ ni kò jẹ́ kí òun sọ àṣírí ibi tí òun ti ń rí oúnjẹ jẹ..
wikipedia
yo
Ìjàpá bẹ ajá pé òun kò ni dá'lé, àti pé òun yíò fi ọwọ́ sí ibi tí owó gbé.Nígbà tí ẹ̀bẹ pọ̀, ajá gbà láti mú ìjàpá lọ..
wikipedia
yo
Ajá mú ìjàpá lọ sí oko iṣu kan tí a kò mọ ẹni tí ó ni oko náà..
wikipedia
yo
Bí wọ́n ṣe dé’bẹ̀ ni ajá wa iṣu tí ó lẹ́rù, ó sì ti múra láti padà sílé..
wikipedia
yo
Nígbà tí ó dìí, ó rí wípé òun kò lè gbé, ó ti pọ̀ jù èyí tí òun lè gbé lọ..
wikipedia
yo
Ajá bẹ̀rẹ̀ sí pariwo kí ó yára ṣùgbọ́n ọ̀kánjúà ojú rẹ̀ kò jẹ́ kí ó gbọ́ igbe ajá..
wikipedia
yo
Níbi ti Ìjàpá ti ń bá ẹrù iṣu jà ni olóko dé ti ó si mú ìjàpá lọ si ilé ọba..
wikipedia
yo
Ni ilé ọba, Ìjàpá jẹ́wọ́ pé ajá ni ó mú òun lọ sí inú oko ti àwọn ti lọ jí iṣu wá..
wikipedia
yo
Bí ajá ti dé ilé ni ó ti mọ̀ pé wàhálà ti dé, ó dá ọgbọ́n, ó di ẹyin adìyẹ sí kóró ẹ̀rẹ̀kẹ́ méjèèjì, ó sì ṣe bí ẹni ti ara rẹ̀ kò yá, ó píroro bí ẹni tí ó sùn lọ..
wikipedia
yo
Ọba sì pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú ajá tí wọ́n jíṣẹ́ fún un pé ọba ń pè é, ó fi ẹ̀yìn tẹ ọ̀kan nínú ẹ̀yin tí ó fi sí kóró ẹ̀rẹ̀kẹ́, ẹ̀yin fọ́, ó sì dà sílẹ̀ bí ẹni tí èébì gbé..
wikipedia
yo
Bí wọ́n ṣe dé ilé ọba tí ọba sì bí léèrè bóyá òun ni ó mú ìjàpá lọ jí iṣu wà lóko olóko, ajá ní kì í ṣe oun torí pé òun ti ń ṣe àìsàn fún bíi ọ̀sẹ̀ kan..
wikipedia
yo
Bí ó sì ti wí báyìí ni ó tún fi ẹ̀yìn tẹ ẹ̀yìn tí ó wà ní kọ̀rọ̀ ẹ̀rẹ̀kẹ́ kejì ó sì dá sílẹ̀ goorogo, ó dà bí pé ajá ń bì..
wikipedia
yo
Ọba gba ohun tí ajá sọ pé ara òun kò yá fún bí ìgbà díẹ̀..
wikipedia
yo
Ọba wá pàṣẹ pé kí wọ́n ti ojú ìjàpá yọ idà, kí wọ́n sì ti ẹyin rẹ̀ tì bọ̀ọ̀.Ẹ̀kọ́ inú ààlọ́ ìtàn yìí kọ́ wa wí pé kò yẹ kí á máa ṣe àṣejù sí gbogbo nǹkan.Edẹwárẹwà …
wikipedia
yo
Ó fẹ́ di olókìkí àti gbajúgbajà látàrí bẹ́ẹ̀.Ìjàpá wà akèrègbè, ó rìn láti ìlú rẹ̀ sí òmíràn káàkiri láti wá gbogbo ọgbọ̀n ayé jọ..
wikipedia
yo
Nigbati o ṣe, o pada si ilu rẹ, o wa okun ti o nipọn lati fi sọ akèrègbè naa..
wikipedia
yo
Ṣugbọn gbogbo ìgbà tí ìjàpá bá tan àkùkọ lọ sọ́dọ̀ kọ́lọkọ̀lọ ni kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ máa ń sá fún àkùkọ..
wikipedia
yo
Àkùkọ̀ kò fura pé ìjàpá fẹ́ se òun ní ìjàmbá ni.Ìjàpá ṣe ìbéèrè lọ́wọ́ kọ́lọkọ̀lọ ìdí tí ó fi ń sá fún àkókò, kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ dáa lóhùn pé iná orí àkùkọ ní òun sá fún, pé ó lè jó òun..
wikipedia
yo
Ìjàpá jẹ́ kó yẹ kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ pé kí ṣe iná, ẹran jóbojobo ni, Ọlọrun lọ dá a pẹlu rẹ̀ kí ó lè dà bó bò ó lọ́wọ́ ọ̀tá..
wikipedia
yo
Ìjàpá ni kí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ wá kí àwọn lọ sílé àkùkọ lálẹ́ kí ó lè rí ìdánilójú nítorípé àkùkọ má ń tètè sùn bẹ́ẹ̀ni yóò sì tètè jí kí ó lè kéde fún àwọn ènìyàn pé ilẹ̀ ti mọ́..
wikipedia
yo
Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ gbà láti tẹ̀lé ìjàpá lọ sí ilé àkùkọ, ìjàpá di ọgbẹ́ orí àkùkọ mú, ó sì ki kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ láyà pé kí ó wá di imú, tí ó sì ri pé ẹran ní ọgbẹ́ orí adìẹ kì í ṣe iná..
wikipedia
yo
Láti ìgbàyí ni àgbẹ̀ ti ń sin adìẹ, tí adìẹ ti di èrò ilé, kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì di ọ̀tá adìẹ di òní; bẹ́ẹ̀ ni kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì kúndùn adìẹ.Èkó ààlọ̀ àlọ́ yí kọ́ wa pé" ẹ̀hìnkùlé lọ̀tá wà, ilé làseni ńgbé.” Ìjàpá tó jẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ àkùkọ ló fi ọgbẹ́ orí rẹ̀ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ jẹ..
wikipedia
yo
ààlọ̀ ooooo ààlọ́ ààlọ́ mi dá fìríò, ó dá lórí ìjàpá àti ẹlẹ́dẹ̀..
wikipedia
yo
Ni ọjọ́ kan, Ìjàpá ló yá owó lọ́wọ́ Ẹlẹ́dẹ̀ pẹ̀lú ìlérí pé titi ọjọ́ mẹta òhun yio dá owó yìí padà..
wikipedia
yo
Ṣùgbọ́n lẹ́hìn ọjọ́ mẹ́ta, ìjàpá kò rí owó yìí dá padà fún ẹlẹ́dẹ̀ ..
wikipedia
yo
Ẹlẹ́dẹ̀ béèrè si para ọ̀dọ́ ìjàpá lati gba owó rẹ̀ padà ṣùgbọ́n pàbó ló jásí..
wikipedia
yo
Ní ọjọ́ kan bí ìjàpá ṣe gbúrò pé Ẹlẹ́dẹ̀ tún ń bọ̀ ní ilé òun láti wá sìn gbèsè ti òhún jẹ , báyìí ni ìjàpá wá dá ọgbọ́n ẹ̀wẹ́..
wikipedia
yo
Ìjàpá sùn sílẹ̀ , ó sí aya sókè , ló bá ní kí yánníbo, ìyàwó rẹ kí o maa lo ata ní aya ohun..
wikipedia
yo
Ìgbà tí Ẹlẹ́dẹ̀ dé tí ó béèrè ìjàpá láti gba owó rẹ̀ , yánníbo dá Ẹlẹ́dẹ̀ lóhùn pé ìjàpá kò sí nílé ..
wikipedia
yo
Inú bí ẹlẹ́dẹ̀ ló bá fi ìbínú ju ohun tí yánníbo fi ń lọ ata nù ..
wikipedia
yo
Báyìí ni ìjàpá sáré wọlé tí ó ń béèrè ohun tí yánníbo fi ń lo ata..
wikipedia
yo
Ọ̀nàlọ bá ṣe àlàyé fún ìjàpá pé ọ̀rẹ́ rẹ̀ elédẹ̀ ti fi ìbínú jù sí ìta ni ìgbà tí kò bá ìjàpá nílé..
wikipedia
yo
Ìjàpá bá kọjú sí Ẹlẹ́dẹ̀ pé , Págà ! Owó tí òhun jẹ́ Ẹlẹ́dẹ̀ tí òhun fẹ́ san padà wà nínú ohun tí yánníbo fi ń lo ata tí Ẹlẹ́dẹ̀ jù sí ìta..
wikipedia
yo
Ìjàpá sọ fún Ẹlẹ́dẹ̀ ki ó yára lọ gbé e wá padà bi bẹ́ẹ̀kọ́ Ẹlẹ́dẹ̀ kò níí rí owó rẹ̀ gbà..
wikipedia
yo
Ìgbátí ẹlẹ́dẹ̀ dé ibi tí ó ju ohun tí yánníbo fi ń lo ata sí, kàyéfì ńlá ló jẹ́ fún torípé kò rí ohun kóhun níbẹ̀ ..
wikipedia
yo
Báyìí ni ẹlẹ́dẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí níí fi imú tu ilẹ̀ kiri títí di òní tí ó ń wá ọlọ ata yánníbo kiri o.Iko inú Pìjọbaitan yìí kọ́ wa pé kí á máa ní sùúrù pẹ̀lú ohun gbogbo tí a bá nse.Àwọn ìtọ́kasí..
wikipedia
yo
Ọwọ́ kan náà ni wọ́n jọ ń ṣe, awọ ni wọ́n ń ta, ibi kan náà ni wọ́n sì pa òfo sí..
wikipedia
yo
Oníṣòwò awọ ni Asin naa, Asin àti Ọ̀kẹ́rẹ́ wọn jọ wà ni ẹ̀gbẹ́ ará wọnnì ọjà ti Ìjàpá si ta kété si wọn.Ni ọjọ́ kan, Ọ̀kẹ́rẹ́ pé lọ s'Ọjà, Ìjàpá ló n dúró de nitori pé Ìjàpá kò lè rin kánmọ́-Oko..
wikipedia
yo
asín ti ru àwo tiẹ̀ dé ọjà, àwọn oníbàárà rẹ̀ tí ń rà á kọ̀bí-aládé kí ọ̀kẹ́rẹ́ tó dé..
wikipedia
yo
Ìgbà tí òkèrè dé, ohun náà tó’gba tirẹ̀, ṣùgbọ́n eṣinṣin ni yọ owó imí..
wikipedia
yo
Inú bẹ̀rẹ̀ síni bí òkèrè, bẹ́ẹ̀ni ní òkèrè bẹ̀rẹ̀ sini da gbogbo nkan rù, ó si ń kọrin òwe, ó n sọ oko ọrọ̀ si Asin, Asin kò si da lóhùn..
wikipedia
yo
asín kò gbìn bẹ́ẹ̀ ni kò dùn pọ̀bọ̀.Ní ìgbà tó yá, ọmọ tí asín gbé wá sí ọjà, ọmọdé náà ti bẹ̀rẹ̀ sí níí rà, asín sì sọọ́ kalẹ́ nígbà tó nta jà fún àwọn oníbárà rẹ̀, ọmọ yìí ń rà kiri, ó ń ṣeré..
wikipedia
yo
Nígbà tí Ọ̀kẹ́rẹ́ pa àtẹ awo rẹ̀ kalẹ́, ọmọdé yìí rà lọ sí ibẹ̀ ó fi ọwọ́ kan ọ̀kan nínú àwo, ara ti kan aláwọ̀ yìí nígbà tí òun kò tà, ìyá ọmọdé yìí ló ń ta látàárọ̀, tìkanra tìkanra ló fi gba owó ọmọdé yìí, tó já àwọ̀ rẹ̀ gbà, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní bu ìyá ọmọ yìí ni mẹsan an mẹwa.asín gbìyànjú láti fún òkèrè ní sùúrù ṣùgbọ́n etí òdì ló fi ń gbọ́ gbogbo àlàyé asín, báyìí ni asín pẹ̀lú òkèrè bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ipògangan..
wikipedia
yo
Wọ́n ń bú ara wọn ní abójú abọ́mu láìpẹ́ àwọn mejeeji kọlu ara wọn,wọ́n fi ìjà pẹẹ́ta..
wikipedia
yo
asín kò lágbára tó òkèrè tẹ́lẹ̀, èrò pé òun yóò fìyà jẹ asín ló wà lọ́kàn òkèrè tó fi sọ ọ̀rọ̀ di ìjàkadì..
wikipedia
yo
Ẹsẹ̀ ń kú bí òjò, ariwo ń sọ gèè, wọ́n fọ́ awọ ara wọn, àwọn kan ń wòran, àwọn kan ń la ìjà nígbàtí àwọn kan ń dá kún ìjà..
wikipedia
yo
Ìròyìn kan Ìjàpá lára pé Asin àti Ọ̀kẹ́rẹ́ n jà, igi ni Ìjàpá fàyọ, gẹ́gẹ́ bi àti mo pe ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ Ìjàpá ni Ọ̀kẹ́rẹ́, ti ó bá na Ọ̀kẹ́rẹ́ ni igi kan, mẹ́wàá ni yóò na Asin, nigbà ti Asin ri wípé Ìjàpá kò là wọ́n ni ijà, ijà ọ̀rẹ́ rẹ Ọ̀kẹ́rẹ́ ló n gbé ti owó rẹ si le ju Ọ̀kẹ́rẹ́ ti òun n bá jà lọ, Asin fi Ọ̀kẹ́rẹ́ silẹ̀ ó si toro mọ́ Ìjàpá ó dè yín dé ni igi imú, ẹyin Asin wọlé ṣinṣin, ẹ̀jẹ̀ n ṣàn ewé lati igi imú Ìjàpá..
wikipedia
yo
Ó ké pe èrò ọjà kí wọ́n gba òun lọ́wọ́ asín ó f’orin sí, ó ń pe;orin ààlọ́ asín t’òun t’ókù mi jọàwọn ni wọ́n jọ ń jáọ́ mi jọìjà rèé mo wá làjó mi Joasìn bu mi nímú jẹjkó mi Joe gbà mí lọ́wọ́ rẹ̀ ọjọ́ọ́ mi jọawo mi ń bẹ lọ́jàjòó mi jọìjàpá àti gbogbo àwọn èrò tí ó wà ní ọjà bẹ̀rẹ̀ sí níí bẹ asín , gan ń bẹ asín ṣùgbọ́n tí asín di ojú pin tí kò sì fi ìjàpá sílẹ̀ títí tí imú ìjàpá fi já mọ́ lẹ́nu báyìí, ni àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí níí dá ìjàpá lẹ́bi wípé kò la ìjà náà ní túbi-n-nu-nu, wípé ìjàpá ńṣe ojúṅru láàrin wọn,láti ìgbà náà ni imú ìjàpá ti kú kan.Ẹ̀kọ́ inú ààbọ̀ lọ́ yìí kọ́ wa pé kò yẹ kí a máa la ìjà àbòsí, bí oníwó bá ń jà, ọ̀tún àtọ̀sí ló yẹ ká dá lé kún, a kò gbọdọ̀ kó pò mọ́ ẹnìkan ká máa na ẹni kejì o, Ọlọ́run má jẹ́ kí ọ̀ràn dí an o o..
wikipedia
yo
Ninu ìtàn, ọpọlọpọ àwọn olórí ni wọ́n ti fún ara wọn ní orúkọ bíi “Ọmọ Ọlọrun”, tabi ọmọ ọ̀run.Ọ̀rọ̀ yìí, “Ọmọ Ọlọrun”, ni wọ́n ti kọ́kọ́ lò ninu Bíbélì èdè Heberu, gẹ́gẹ́ bí orúkọ mìíràn tí wọ́n fi ń pe eniyan tí ó bá súnmọ́ Ọlọrun tabi ẹni tí ó bá ní ìbáṣepọ̀ tó dán manrán pẹlu Ọlọrun..
wikipedia
yo
Nínú ìwé Ẹ́kísódù, wọ́n máa ń pe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àkọ́bí ọmọkùnrin Ọlọ́run..
wikipedia
yo
Bákan náà, wọ́n máa ń pe àwọn angẹli, àwọn ènìyàn mímọ́ àti àwọn ọba Ísírẹ́lì ní “Ọmọ Ọlọ́run” nínú ìwé májẹ̀mú tuntun ti Bíbélì Mímọ́ àwọn ẹlẹ́sìn ọmọ lẹ́yìn Jesu, Jesu ni wọ́n ń pè ní “Ọmọ Ọlọ́run” ní ọ̀pọ̀ ìgbà..
wikipedia
yo
Níbi ìṣẹ̀lẹ̀ meji ninu Bíbélì, a gbọ́ wípé ohun kan ti ọ̀run wà, tí ó pe Jesu ní “Ọmọ Ọlọrun”
wikipedia
yo
Jesu pàápàá fúnra rẹ̀ pe ara rẹ̀ ní “Ọmọ Ọlọrun”, bákan náà ọ̀pọ̀ eniyan pè é ní “Ọmọ Ọlọrun” ninu majẹmu tuntun inú Bíbélì..
wikipedia
yo
Wọ́n pe Jesu ní Ọmọ Ọlọrun, tí wọ́n sì pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní “Àwọn ọmọ Ọlọrun” ní ti Jesu, wọ́n ń pè é ní Ọmọ Ọlọrun nítorí ipá tí ó kó gẹ́gẹ́ bí Mesaya, (Olùgbàlà aráyé) tabi Christ, Ọba tí Olodumare yàn..
wikipedia
yo
Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà, pípé Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run tàbí Messiah jù bẹ́ẹ̀ lọ fún ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tí wọ́n sì ń ṣe àkàwé àti ìwádìí rẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.Ẹ má ṣe jẹ́ kí á ṣe àṣìlò ọ̀rọ̀ yìí, “Ọmọ Ọlọ́run” pẹ̀lú “Ọlọ́run Ọmọ” (), èyí ẹnìkejì nínú Mẹ́talọ́kan nínú ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Christianity, àwọn àtẹ̀lé Jésù..
wikipedia
yo
Ẹ̀kọ́ nípa Mẹ́talọ́kan ṣàlàyé pé Jesu ni “Ọlọrun ọmọ”, ẹ̀kọ́ náà ṣàlàyé pé Ọlọrun ati Ọlọrun ọmọ jẹ́ ẹnì kan náà ṣugbọn pẹlu àlàyé pé ọ̀kan jẹ́ Ọlọrun Baba tí ekeji sì jẹ́ Ọlọrun Ọmọ..
wikipedia
yo
Bakan naa, awon elesin Kírísítẹ́nì tí wọ́n kò gbàgbọ́ nínú Mẹ́talọ́kan gbàgbọ́ pé Jésù jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, bí ó ṣe wà nínú Májẹ̀mú Tuntun ti Bíbélì.Àwọn ìtọ́kasí..
wikipedia
yo
Bethlehem (; ) jẹ́ ìlú nlá kan tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Palestine ní apá ìwọ̀ Oòrùn ìpínlẹ̀ tí ó tó kìlómítà mẹ́wá Convert|10|km|mi|wbr=in}} sí Ìlànà Oòrùn Jerusalem..
wikipedia
yo
Iye àwọn olùgbé ibẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́kanlẹ́lẹgbẹ́ ẹ̀nìyàn (25,000,000), orílẹ̀-èdè náà..
wikipedia
yo
Ibẹ̀ ni wọ́n fẹnu kò sí wípé wọ́n ti bí Jésù ní inú abúlé kan tí ó wà níbẹ̀ tí wọ́n ń pè ní Nazareth .Ohun tí jẹ́ nkan àmúṣọrọ̀ àwọn ènìyàn Bethlehem ní ìrìn-àjò ìgbafẹ́ pàá pàá jùlọ lásìkò òdú Kérésìmesì tí àwọn elési ìgbàgbọ́ ma ń ṣe àbẹ̀wò sí ibẹ̀ pàá pàá jùlọ Church of the Tíbàávity.Ibi tí ó tún ṣe pàtàkì ní ìlú yí ní [ibojì RachelRachel èyí tí ó wà ní ẹnu àbáwọlé Gúsù ìlú Bethlehem, bí obtilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn ọmọ ìlú kìí fi bẹ́ẹ̀ láánfàní sí ibẹ̀ látàrí bí àwọn ènìyàn iṣllọ́wọ́fínní ṣe gbégi dínà ibẹ̀..
wikipedia
yo
ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n dárúkọ ìlú Betata ní ní ọdún 1350-1330 BCE tí wọ́n fi lẹ́tà kan ránṣẹ́ nígbà tí àwọn ọmọ kanáánì sì ń gbé ibẹ̀..
wikipedia
yo
Nínú Bíbélì Hebrew, ni wọ́n ti ṣàlàyé bí wọ́n ṣe kò Bethlehem gẹ́gẹ́ kí ó lè jẹ́ ààbò fún ìlú Wàyíam, ìlú (Aramu yí ni wọ́n fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé wọ́n ti da òróró lé Dafidi lórí gẹ́gẹ́ bí ọbailẹ̀ Ísírẹ́lì..
wikipedia
yo
Látinú Mathew àti Lúùkù ni ó sọ wípée inú ìlú Bethlehem ni wọ́n ti bí JÉSÙ..
wikipedia
yo
Ọba Hadrian bá ìlú Bethlehem jẹ́ lásìkò ọ̀rundu Kejì nínú Ogun Bar Kokhba rẹ̀volt; àmọ́ tí Ọbabìnrin Helena, tí ó jẹ́ ìyá fún Constantine The Great, ni ó ṣe ìfilọọlé Kano Ilé ìjọ́sí àgbàyanu Church of the Tíbàávity ní ọdún 327 CE.Àwọn XIV tún bá ilé ìjọsìn náà bàjẹ́ gidigidi lásìkò ogun 529, àmọ́ Ọba Justinian í ṣe àtúnkọ rẹ̀ lẹ́yìn ọ̀rúndún kan tí ogun náà wáyé.Ìlú Bethlehem di ìkan lára ìlú Amọna àwọn Mùsùlùmí lábẹ́ àwọn ẹlẹ́sìn mùsùlùmí jund Asostin lẹ́yìn tí wọ́n gba ilé náà ní ọdún 639..
wikipedia
yo
Wọ́n sì ṣàkóso ìlú náà títí di ọdún 1099 tí àwọn ọmọ ogun onigbagbọ crusader tí wọ́n yí ìlànà ìjọ́sìn ìlú náà pada sí ti Latin láti èdè èdè Latini..
wikipedia
yo
Láàrín ọ̀rúndún kẹtàlá, àwọn ọmọ ogun Mamluks wó odi ìlú náà, àmọ́ wọ́n tún odi ìlú yí kọ́ padà lábẹ́ ìjọba Ottomans níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹrìndínlógún..
wikipedia
yo
Ìṣàkóso ìlú Bethlehem kúrò láti ọwọ́ ọba Ottomans bọ́ sí ọwọ́ àwọn Britẹni níparí ogun àgbáyé ẹlẹ́kejì..
wikipedia
yo
Wọ́n dá ìlú Bethlehem mọ́ ìjọba Jọdani lásìkò ogun tí ó wáyé láàrin àwọn Lárúbáwá ati Isreal ní ọdún 1948, àmọ́ tí àwọn isreal mókè ninu ogun náà ní ọdún 1967 tiiṣe ogún ọjọ́-mẹfa..
wikipedia
yo
Láti ọdún 1995 ni ìjọba Palestine ti ń ṣe àkóso lórí ìlú Bethlehem..
wikipedia
yo
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìlú Bethlehem jẹ́ ìlú tí àwọn Mùsùlùmí pọ̀ sí Jùlọ, síbẹ̀ àwọn ẹlẹ́sìn Ìgbàgbọ́ náà kò gbẹ́yìn..
wikipedia
yo
àwọn olùgbé àti ọmọ orílẹ̀-èdè Isreal ti ta ápe si inú ilẹ̀ Bethlehem tí wọ́n sì lé àwọn Mùsùlùmí àti onígbàgbọ́ tí wọ́n gbé níbíe ní ìrẹ́pọ̀, wọ́n sì tún ń di ìjẹ inú wọn lọ́wọ́ pẹ̀lú.Ìpìlẹ̀ orúkọ ìlú yí Bethlehem (), jẹ́ ìlú ńlá kan tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Palestine ní apá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè náà..
wikipedia
yo
Ibẹ̀ ni wọ́n fẹnu kò sì wípé wọ́n ti bí Jesu ní inú abúlé kan tí ó wà níbẹ̀ tí wọ́n ń pè ní Nazareth .Bethlehem tí ìtumọ̀ rẹ̀ ń jẹ ilé búrẹ́dì tàbí ilé oúnjẹ..
wikipedia
yo
Wọ́n ń pe ìlú ní èdè , àti ní èdè.Ibi àkọ́kọ́ tí wọ́n ti kọ́kọ́ dárúkọ Bethlehem gẹ́gẹ́ ayé kan ni nínú àtẹ̀jíṣẹ́ Amarna Correspondence (), ni èyí tí ó tọ́ka sí ibẹ̀ gẹ́gẹ́ bí bit-mimi, orúkọ tó jẹ́ wípé wọ́n fàá yọ láti ibi tí a kò lè tọ́ka sí..
wikipedia
yo
amọ̀, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé orúkọ náà ni wọ́n yó láti Mesopotamian tàbí cankùnkùn tí wọ́n ń pè ní lárùmú tí ń ṣe ọ̀laọrùn àráàyun..
wikipedia
yo
AlBRBR gbà wípé agbásílẹ̀ ètò tí ọ̀jọ̀gbọ́n Otto Schroeder, ní ó "ṢE Regi"
wikipedia
yo
AlBRBR sọ wípé ÌṢẸNUPÈ Lálahmu ni ó ti wá bẹ́ẹ̀ láti fún ìkàntadẹ́gbẹ̀tata ọdún amọ̀, wọ́n ń lòó fún orírí ìtumọ́ bíi “Tẹ́ḿpìlì Ò Láìtànná ní Kenaani, ‘Ilé Búrẹ́dì' ní Èdè Hebrew àti èdè Árámáíkì, wọ́n tún ń pèé ní ‘Ilé ẹran jíjẹ́ jíjẹ́ èdè èdè Lárúbáwá..
wikipedia
yo
Nígbà tí àgbékalẹ̀ “ Schroeder’s kò jẹ́ ìtànẹ́wò gbà, láti lè jẹ́ kí Resewò wálé ìwádí rẹ nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀..
wikipedia
yo
Johanu Onítẹ̀bọmi jẹ oníwàásù ní agbègbè odò Jọdani ní àkókò tirẹ̀.Àwọn ìtọ́kasí..
wikipedia
yo
Frank Santọpadre (February 7, 1961) jẹ́ òǹkọ̀wé ará Amẹ́ríkà.Àwọn ìtọ́kasí..
wikipedia
yo
àìsùn Kérésìmesì ní ọjọ́ tàbí ìrọ̀lẹ́ tí ó kan kí ó tó kan ọjọ́ Kérésìmesì, ìjọ tí a fi ń ṣe ayẹyẹ ìbí Jesu..
wikipedia
yo
Ìjọ Kérésìmesì jẹ́ ọjọ́ tí àwọn ènìyàn yẹ sí káàkiri àgbáyé, àìsùn Kérésìmesì sì wà lára àwọn ọjọ́ tí wọ́n yẹ sí ní ìrètí ọjọ́ Kérésìmesì..
wikipedia
yo
Wọ́n ma ń ka ọjọ́ mejeeji gẹ́gẹ́ bi ọjọ́ ayẹyẹ ti ó ṣe pàtàkì jùlọ ni àwùjọ àwọn Kristẹni Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ìjọ ma ń kóra jọ pọ̀ lati ṣe ìsìn, kọrin Kérésìmesì àti lati ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan mìíràn lati ṣe ayẹyẹ ibi Jesu..
wikipedia
yo
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ó kó jọ pẹ̀lú ara àti ìdílé wọn, àwọn mìíràn a kọrin Kérésìmesì, àwọn míràn a fi iná àti àwọn nkan míràn ṣe ilé ní ọ̀ṣọ́, wọn ó sì ma gbà àti fún ní ní ẹ̀bùn.Àwọn ìtọ́kasí..
wikipedia
yo
Ní àwùjọ Kristẹni, ọmọlẹ́yìn ní àwọn tí ó ti pinu láti tẹ̀lé Jesu..
wikipedia
yo
Wọ́n lo ọ̀rọ̀ yìí ní májẹ̀mú titun nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere àti ìwé Ìṣe àwọn Àpósítélìní ayé àtijọ́, ọmọlẹ́yìn jẹ́ ẹni tí ó ti pinu láti tẹ̀lé olùkọ́ rẹ̀..
wikipedia
yo
Ọmọlẹ́yìn nínú Bíbélì jẹ́ ẹni tí ó ń ṣe àfarawé ayé àti ẹ̀kọ́ olùkọ́ rẹ̀, ó yàtọ̀ sí akẹ́kọ̀ọ́ tí ń ṣe àfarawé ayé olùkọ́ rẹ̀..
wikipedia
yo
O jẹ ikẹkọ lati ọdọ olukọ ẹrọ lati mu ki ayé akẹ́kọ̀ọ́ dabi ti olukọ tabi oga rẹ.Majẹmu titun sọ nipa ọpọlọpọ ọmọlẹ́yìn Jésù nigba iṣẹran rẹ.Awọn itọkasi..
wikipedia
yo
Àwọn ìwé ìhìnrere Lúùkù àti Matiu ṣàpèjúwe ibi Jesu..
wikipedia
yo