cleaned_text
stringlengths
6
2.09k
source
stringclasses
2 values
language
stringclasses
1 value
Ní ìbẹ̀rẹ̀, Munyiva ṣeyèméjì láti kó ipa náà títí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan fi gbàá níyànjú tó sì ń jẹ́ kó mọ́ rírí ìdí tó fi gbọ́dọ̀ ṣe ipa náà..
wikipedia
yo
Wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé fíìmù náà ní ìlú Kẹ́nyà nígbà tó ṣe wípé òfin kò ọdún gba ìbálòpọ̀ obìnrin ṣọbinrin tàbí okùnrin sọ́sọ́..
wikipedia
yo
Rafiki ni àkọ́kọ́ fíìmù ilẹ̀ Kẹ́nyà tí yóó jẹ̀ẹ́ wíwò níbi ayẹyẹ Cannes Film Festival..
wikipedia
yo
Ann Hornaday gbóríyìn fún Munyiva àti akẹgbẹ́ rẹ̀ Samantha Mugatsia fún ipa wọn nínú eré náà..
wikipedia
yo
Wọ́n yan Munyiva fún àmì-ẹ̀yẹ òṣèré tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ Africa Movie Academy Awards.Ní ọdún 2019, Munyiva kó ipa Anna gẹ́gẹ́ bi òṣìṣẹ́ oníròyìn kan nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Country Queen..
wikipedia
yo
Ní Oṣù Keèje Ọdún 2019, Munyiva ṣe àkọ́kọ́ ipa rẹ̀ lórí ìpele nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Sarafina!
wikipedia
yo
Denise Newman jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfríkà.Isẹ̀mí rẹ̀ Newman dàgbà ní agbègbè Athlone tí ó wà ní ìlú Cape Town..
wikipedia
yo
O ṣe àpèjúwe ara rẹ pé òun máa sábà dá wà nígbà èwe òun, tó sìí kọ̀ láti rí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ bá ṣeré..
wikipedia
yo
Lẹhin ti o pari ẹkọ girama rẹ lati Athlone High School ni ọdun 1972, o lọ si Amẹrika fun eto-ẹkọ Post-matric Learnership..
wikipedia
yo
Newman padà sí orílẹ̀-èdè rẹ̀ ní ọdún 1974 láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ àwùjọ..
wikipedia
yo
Newman gba iṣẹ́ kan ní ilé-ìṣeré Space Theatre níbi tí ó ti n ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi olùtọ́jú ilé-ìṣeré náà, tó síì máa n ṣètò ilẹ̀ gbígbá àti aṣọ fífo ní ilé-ìṣeré náà..
wikipedia
yo
Ní ọdún 1979, wọ́n fún ní ipò alákòóso ìpele, èyí tí ó fún ní ànfààní láti kó àkọ́kọ́ ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi òṣèré nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Political Joke, èyí tí Jean Naidọ̀ ṣe olùdarí rẹ̀ tí Peter Snyders náà síì jẹ́ ònkọ̀tàn.Ní ọdún 1982, Newman kó àkọ́kọ́ ipa sinimá àgbéléwò rẹ̀ nínu eré City Lovers gẹ́gẹ́ bi Yvonne Jacobs, òṣìṣẹ́ ilé-ìtajà aláwọ̀dúdú kan tí ó yó ìfẹ́ okùnrin aláwọ̀funfun kan..
wikipedia
yo
Ní ọdún 1985, ó kópa nínu eré aláwàdà tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Two Weeks in Paradise.Ní ọdún 2009, Newman kó ipa Olú-ẹ̀dá-ìtàn nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Shirley Adams, èyí tí olùdarí rẹ̀ jẹ́ Olivier HerManus..
wikipedia
yo
Ó ṣe ìyá ọmọ ogún ọdún kan tí ó ń gbèrò láti ṣekú pa ararẹ̀ lẹ́hìn tí ó rọ lápá àti ẹsẹ̀..
wikipedia
yo
Newman gba àmì-ẹ̀yẹ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ òṣèré tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ Carthage Film Festival fún ipa rẹ̀ nínu eré náà.Newman kópa gẹ́gẹ́ bi ìyá sí Tin nínu eré The Endless River ní ọdún 2015, eré tí HerManus darí..
wikipedia
yo
Ó darapọ̀ mọ́ àwọn olùkópa eré tẹlifíṣọ̀nù Suidooster ní ọdún 2015..
wikipedia
yo
Newman sọ di mímọ̀ wípé òun fẹ́ràn ipa náà jù ti ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Daleen Meintji nínu eré 7de Laan lọ..
wikipedia
yo
Sana Mouziane (tí wọ́n bí ní ọdún 1980) jẹ́ òṣèrébìnrin àti akọrin ọmọ orílẹ̀-èdè Mòrókò.Itọ̀ rẹ̀ wọ́n bí Mouziane ní ìlú Casablanca..
wikipedia
yo
Nígbàtí àwọn òbí rẹ̀ kọrawọn sílẹ̀, ó di ẹni tí ó n gbẹ́ ní ìlú Marrakesh..
wikipedia
yo
Mouziane lọ sí ìlú Lọ́ndọ̀nù nígbà tí ó wà lọ́mọ ọdún mẹsan-an..
wikipedia
yo
O kẹkọọ nipa orin kikọ o si wa ninu ẹgbẹ orin kan..
wikipedia
yo
Àkọ́kọ́ orin rẹ̀ tí ó kọ lójú ọ̀pọ̀ ẹ̀rọ wáyé nígbà tí ó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún níbi ayẹyẹ Darlington International Festival..
wikipedia
yo
Ó sọ di mímọ̀ wípé gbígbé òun ní Ilẹ̀gẹ̀ẹ́sì tún kún láti la òun lọ́yẹ̀ nípa bi òun ti lè gbé ayé ìsọ̀ní.Mouziane ṣe àgbéjáde àkọ́kọ́ orin àdákọ rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "In Lhoub ní ọdún 2004..
wikipedia
yo
Ó kó àkọ́kọ́ ipa sinimá àgbéléwò rẹ̀ nínú eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Women in Search of Freedom ní ọdún 2005, èyí tí Ines Al °Heidi darí..
wikipedia
yo
Fíìmù náà dá lóri àwọn obìnrin tí wọ́n wà lááá, ó sì gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àmì-ẹ̀yẹ níbi ayẹyẹ àjọ̀dún fíìmù kan..
wikipedia
yo
Ní ọdún tí ó tẹ̀le, ó kópa nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Ashra Haramy..
wikipedia
yo
Ní ọdún 2007, Mouziane kópa gẹ́gẹ́ bi obìnrin tí ó ń ṣe àgbèrè pẹ̀lú àbúrò ọkọ rẹ̀ kan nínu eré Samira's Garden..
wikipedia
yo
Ipa yìí ni ó fún ní àmì-ẹ̀yẹ òṣèrébìnrin tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ Panafrican Film and Television Festival of Ouagadougou ní ọdún 2009..
wikipedia
yo
Ní ọdún 2012, Mouziane kó ipa Zahra nínu eré L'enfant Cheikh, èyí tí Hamid Bennani darí..
wikipedia
yo
ó kó ipa Martha ninu eré ti ọdún 2013 kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Bible..
wikipedia
yo
Ní ọdún 2017, Mouziane kópa nínu eré La nuit Ardente, èyí tí Bennani darí..
wikipedia
yo
Donia Massoud (tí wọ́n bí ní 2 Oṣù Kaàrún, Ọdún 1979) jẹ́ òṣèrébìnrin àti akọrin ọmọ orílẹ̀-èdè Ìjíptì.Isẹ̀mí rẹ̀ Massoud lẹni tí wọ́n bí tó sì dàgbà ní ìlú Alexandria..
wikipedia
yo
Nígbà tí ó pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, ó kó lọ sí ìlúKáírò..
wikipedia
yo
Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ akọrin àti òṣèré rẹ̀ ní ìlú Káírò.ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 2000, Massoud lo ọdún mẹ́ta láti fi gba ìtàn àti àwọn orin àṣà káàkiri ilẹ̀ Ìjíptì..
wikipedia
yo
Ó gba àwọn orin àṣà sílẹ̀ níbi àwọn ayẹyẹ àjọ̀dún àti ìgbéyàwó..
wikipedia
yo
Massoud ṣe àgbéjáde àkójọpọ̀ àwọn orin rẹ̀ kan ní ọdún 2009 tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ MaHatet Masr..
wikipedia
yo
Èyí tí ó gbajúmọ̀ jùlọ nínu àwọn orin rẹ̀ ní orin tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "Betnadeeny Tanki Leeh", èyí tí ó fi n BÉÈRÈ LỌ́WỌ́ ìmọ̀ rẹ̀ àtijọ́ ìdí tí ó ṣe ń pe ago rẹ̀ lẹ́hìn tí òun ti ní olólùfẹ́ míràn..
wikipedia
yo
Ó kọ orin náà káàkiri àgbáyé tó sì ṣe eré orin náà ní ilẹ̀ Africa, Europe, àti Asia.yàtọ̀ sí iṣẹ́ orin kíkọ rẹ̀, Massoud darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèré orí-ìtàgé kan tí wọ́n pè ní Al-Warha..
wikipedia
yo
Massoud ti kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ sinimá àgbéléwò àti eré tẹlifíṣọ̀nù lórílẹ̀ èdè Ìjíptì àti Swídìn lédè Lárúbáwá àti Gẹ̀ẹ́sì..
wikipedia
yo
Souhir Ben Amara (tí wọ́n bí ní 27 Oṣù Kọkànlá, Ọdún 1985) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Tùnísíà.Isẹ̀mí rẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú kíkópa nínu àwọn eré tẹlifíṣọ̀nù bíi Maktoub àti Choufli Hal ní ọdún 2008..
wikipedia
yo
Ó kópa gẹ́gẹ́ bi Maliha nínu eré Min Ayam Mliha ní ọdún 2010..
wikipedia
yo
Ben Amara kó àkọ́kọ́ ipa sinimá àgbéléwò rẹ̀ nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Always Brando (2011), èyí tí olùdarí rẹ̀ n ṣe Rit Béhi..
wikipedia
yo
Ó kó ipa Zña nínu eré náà, èyí tí ó rí ànfààní rẹ̀ lẹ́hìn tí olùdarí eré náà kò faramọ òṣèrébìnrin tí wọ́n kọ́kọ́ yàn fún ipa náà..
wikipedia
yo
Ní ọdún 2012, ben Amara kó ipa Aïcha nínu eré Miilleille, èyí tí olùdarí rẹ̀ n ṣe Nouri Boucham, tó síì n dá lóri àwọn pẹ̀lú tí ó rọ̀ mọ́ ibori àwọn obìnrin Musulumi.ní ọdún 2013, ó kó ipa DD nínú eré Yawmiyá Imraa..
wikipedia
yo
Ní ọdún 2019, ó kópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Kingdoms of Fire..
wikipedia
yo
ó tún kó ipa olú-ẹ̀dá-ìtàn nínú eré Sortile (2019), èyí tí alá edédine Slim ṣe adarí rẹ̀..
wikipedia
yo
Sandra Nkaké (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ 15 Oṣù kọkànlá, Ọdún 1973) jẹ́ òṣèrébìnrin àti akọrin ọmọ orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnùiṣẹ́ rẹ̀ wọ́n bí Nkaké ní ìlú Yaoundé, orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù ní ọdún 1973..
wikipedia
yo
Nígbà tí ó pé ọmọ ọdún 12, ó kó lọ sí orílẹ̀-èdè Fránsì..
wikipedia
yo
Nkaké ti fẹ́ràn orin kíkọ láti ìgbà èwe rẹ̀, àti pàápàá ó fẹ́ràn okùnrin akọrin kan tí wọ́n pè ní Prince..
wikipedia
yo
Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Sorbone tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Paris..
wikipedia
yo
Nigbati o pe ọmọ ogún ọdún, o yi ọkàn rẹ pada lati kojumọ eré ìtàgé ṣíṣe..
wikipedia
yo
Lẹ́hìnwá ni ó lọ ṣe àyẹ̀wò fún ipa eré kan tó sì tibẹ̀ di òṣèré..
wikipedia
yo
Nkaké kó àkọ́kọ́ ipa rẹ̀ nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Crucible ní ọdún 1994, èyí tí Thomas Ledouarec darí..
wikipedia
yo
Ní ọdún tí ó tẹ̀le, ó kópa nínu eré Le Dindon.Nkaké ṣe àkọ́kọ́ ipa sinimá àgbéléwò rẹ̀ nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Les Deux Pápás et la Maman ní ọdún 1996, èyí tí Jean-Marc Longval ṣe adarí rẹ̀..
wikipedia
yo
Lẹ́hìnwá rẹ̀, ó kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn sinimá àgbéléwò àti àwọn eré tẹlifíṣọ̀nù míràn, ṣùgbọ́n Nkaké gbìyànjú láti rí dájú wípé ó síì fọkàn sí iṣẹ́ orin rẹ̀ náà..
wikipedia
yo
Ní ọdún 1996, ó kópa nínu iṣẹ́ orin kan tí wọ́n pè ní Ollano trip-hop project ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Hélène Noguerra..
wikipedia
yo
Ní àkókò àwọn ọdún 2000, Nkaké fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn akọrin míràn bíi Jacques Higelin, Daniel YVinec and the National Jazz Orchestra, Julien Lourau, àti Rodolphe Burger..
wikipedia
yo
Ó tún ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú Gerald Toto àti David Walters fún ti iṣẹ́ àkànṣe Urban Kreol Project.Ní ọdún 2008, Nkaké ṣe àgbéjáde àkọ́kọ́ àkójọpọ̀ àwọn orin rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Mansaadi, èyí tí ó kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eré orin sínú tó fi mọ́ àwọn eré orin tí ó ṣe ní ilẹ̀ Áfríkà àti Brasil..
wikipedia
yo
Ní ọdún 2012, ó ṣe àgbéjáde ẹ̀kejì àkójọpọ̀ àwọn orin rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Nothing for Granted, ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Ji Dr..
wikipedia
yo
Láti ilé-iṣẹ́ orin tí wọ́n pè ní Jazz Village Record Label ni ó ti gbé orin náà jáde..
wikipedia
yo
Ó gba àmì-ẹ̀yẹ kan níbi ayẹyẹ Victoires du Jazz ní Oṣù Keèje Ọdún 2012..
wikipedia
yo
Wajiha Jendoubi (tí wọ́n bí ní ọdún 1972) jẹ́ òṣèrébìnrin àti apanilẹ́rìn-ín ọmọ orílẹ̀-èdè Tùnísíà.Isẹ̀mí rẹ̀ Jendoubi lẹni tí wọ́n bí ní ọdún 1960 tó sì jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Káíròu, orílẹ̀-èdè Tùnísíà..
wikipedia
yo
Láti ṣe ọ̀kan nínú àwọn ojúṣe rẹ̀ fún ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀, Jendoubi àti akẹ́kọ̀ọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀ kan dì jọ kọ ìtàn-eré kan tí wọ́n síì kó àwọn ipa eré náà..
wikipedia
yo
Àwọn olùdarí eré tó ń bẹ ní orílẹ̀-èdè Tùnísíà ṣe àkíyèsí rẹ̀ tí wọ́n sì fún ní ànfààní láti kópa nínú àwọn eré bíi Mnamet Aropersia, Iikhwa wa Zaman àti Aoudat Al Minyar..
wikipedia
yo
Eré Aoudat Al Minyar jẹ́ èrè tí àwọn ènìyàn mọ̀ọ́ mọ́ jùlọ..
wikipedia
yo
Ní ọdún 2010, ó kópa nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Season of Men.Jendoubi kópa nínu eré kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Madame Kenza ní ọdún 2010, eré tí òun nìkan dá ṣe..
wikipedia
yo
Ó rí ìdùndùn látara lánìkan wà lóri ìpele fún ṣíṣe eré náà.ní ọdún 2015, wọ́n yan òun pẹ̀lú Myriam Belkad àti Emna Louzyr Ayarí láti lọ sójú orílẹ̀-èdè Tùnísíà níbi àpèjọ kan tí ó wà fún ìjíròrò lórí fífi òpin sí ẹ̀yà ẹ̀yà sí àwọn obìnrin.ní ọdún 2017, Jendoubi kópa gẹ́gẹ́ bi Bahjá nínú fíìmù Gogu kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ el Jaida Jaida..
wikipedia
yo
Wọ́n yẹsí ní ọdún 2019 pẹ̀lú oyè ìlú kan tí wọ́n pè ní Officer of the Order of the Republic..
wikipedia
yo
Ní Oṣù kejìlá Ọdún 2019, Jendoubi sọ di mímọ̀ wípé òun kò gba owó lọ́wọ́ ilé-iṣẹ́ ìkànnì Attessia TV fún iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ṣe níbi àwọn ètò lé Pside, FLAshback àti Ali Chouerreb.Ó ti ṣe ìgbéyàwó, ó sì ti ní àwọn ọmọ méjì..
wikipedia
yo
Soumaya Akaaboune (tí wọ́n bí ní ọjọ́ 16 Oṣù Kejì, Ọdún 1974) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Mòrókò.Isẹ̀mí rẹ̀ Akaaboune lẹni tí wọ́n bí tó sì dàgbà ní ìlúTaner, orílẹ̀-èdè Mòrókò..
wikipedia
yo
Ní ìgbà tí ó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá, ọ̀sẹ̀~re ijó kan tí wọ́n pè ní Maurice Bejart ṣe àópọ̀ wípé Akaaboune ní ẹ̀bùn ijó tó sì pèé láti wá darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ oníjó rẹ̀..
wikipedia
yo
Ó gbà láti darapọ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní kẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ Maurice Bejart..
wikipedia
yo
Akaaboune káàkiri gbogbo ilẹ̀ Yú láti ṣeré ijó ní àwọn ìlú bíi Paris, Spéìn àti Lọ́ndọ̀nù..
wikipedia
yo
Ní àkókò tí ó wà ní ìlú Lọ́ndọ̀nù, ó kómọ eré orí-ìtàgé ṣíṣe tó sì kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eré olórin..
wikipedia
yo
Òpin dé bá iṣẹ́ ijó jíjó rẹ̀ nígbà tí ó ní ìfarapa níbi ẹsẹ̀ rẹ̀ ní ọdún 1989..
wikipedia
yo
Ní ìlú Lọ́ndọ̀nù, Akaaboune pàdé Sandra Bernhard, ẹnití ó pèé láti kópa nínu ètò ìfihàn rẹ̀ tí ó pe àkọ́lé rẹ̀ ní "Up All Night" àti Lẹ́hìnwá nínú ètò "I am Still Here Damn It".Akaaboune kọ́ ẹ̀kọ́ eré ṣíṣe ní ilé-ìṣeré Lof Studio..
wikipedia
yo
Ní ọdún 2010, ó kópa pẹ̀lú Matt dámọn nínu fíìmù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Green Zone..
wikipedia
yo
Akaaboune ní àwọn ipa nínu eré aláwàdà afìfẹ́hàn kan tí ọdún 2012 tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Playing for Keeps àti eré Lovelace ní ọdún 2013..
wikipedia
yo
Ó tún wà nínú ètò ìfihàn ti ọdún 2013 kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Les Vráì Housewives..
wikipedia
yo
Laarin odun 2015 si 2016, Akaaboune kópa gẹ́gẹ́ bi Fttouma nínu eré tẹlifíṣọ̀nù kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ wádìí, tí olùdarí rẹ̀ n ṣe Yassine Ferdààyè..
wikipedia
yo
Ipa rẹ̀ dá lórí ọmọbinrin kan tí ó kó ìwà ìbàjẹ́ ati àìṣedéédé tọkàntọkàn..
wikipedia
yo
Ní ọdún 2019, ó kó ipa Marcelle nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Spy.Akaaboune pàdé Peter Rodger ní ọdún 1999..
wikipedia
yo
Àwọn méjéèjì fẹ́rawọn tí wọ́n sì bí ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Jazz..
wikipedia
yo
Peter Rodger ti bí ọmọ kan ríṣe tí orúkọ rẹ̀ n ṣe Elliot Rodger, ẹni tí ó ṣe ẹ̀mí àwọn ènìyàn lófò ní ọdún 2014..
wikipedia
yo
Elliot Rodger ti gbàá lérò ríi láti ṣekú pa Akaaboune náà..
wikipedia
yo
Akaaboune padà sí orílẹ̀-èdè Mòrókò ní ìgbẹ̀yìn ọdún 2014..
wikipedia
yo
Mariama Sylla Faye jẹ́ olùdarí fíìmù Sègalese àti oludasiṣẹ.Isẹ̀mí rẹ̀ wọ́n bí Sylla ní ìlú Dakar ó síì jẹ́ àbúrò sí ònkọ̀tàn kan tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Khady Sylla..
wikipedia
yo
Ìyá rẹ̀ náà ṣiṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ kan tí ó ń rí sí sinimá..
wikipedia
yo
Sylla ti ní ìfẹ́ sí eré sinimá ṣíṣe láti ìgbà tí ó wà lọ́mọ ọdún méje, nígbà tó jẹ́ wípé wọ́n maá n lọ ilé wọn láti fi ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù.Sylla dá ilé-iṣẹ́ agbéréjáde kan sílẹ̀ ní ọdún 2003, èyítí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Guiss Guiss Communication..
wikipedia
yo
Ó ṣe adarí eré oníṣókí kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Dakar Deuk raw ní ọdún 2008, èyítí ó ṣe àyẹ̀wò ẹ̀yà Les111 ní ìlú Dakar..
wikipedia
yo
Gertrude Webster Kamkwatira jẹ́ òṣèré àti olùdarí eré lórílẹ̀-èdè Màláwì..
wikipedia
yo
Ó di adarí fún Wakhumbàtà Edúrúte Theatre ní ọdún 1999 lẹ́hìn ikú olùdásílẹ̀ rẹ̀..
wikipedia
yo
lẹhìn ìgbà tí O fi ẹgbẹ náà sílẹ̀, O ẹgbẹ wanna-dò kalẹ̀..
wikipedia
yo
Oun ni Aare fun National Theater Association ti Malawi ati Alaga fun Copyright Society ni Malawi..
wikipedia
yo
Kamkwa ko eré mẹtala ni èdè Gẹẹsi, lara awon ere naa ni it's My Uria, Jesús Reterial ati Breaking The News..
wikipedia
yo
Aïcha Thiam (tí wọ́n bí ní 27 Oṣù Kẹẹ̀wá Ọdún 1979) jẹ́ olùdarí eré ọmọ orílẹ̀-èdè Bẹ́ljíọ̀m àti SègaLàwọn ènìyàn ÀAlààyèàwọn Ọjọ́ìbí ní 1979..
wikipedia
yo
Nidhal Guiga (tí wọ́n bí ní 11 Oṣù Kẹẹ̀ta, Ọdún 1975) jẹ́ òṣèrébìnrin, ọkọtan, àti olùdarí eré ọmọ orílẹ̀-èdè Leagbọ̀nàwọn ènìyàn àtíàwọn Ọjọ́ìbí ní 1975..
wikipedia
yo
Fatou Bintou Kandé Senghor (tí wọ́n bí ní 9 Oṣù Kínní, Ọdún 1971) jẹ́ olùdarí eré, ònkọ̀tàn àti olùyàwòrán ọmọ orílẹ̀-èdè Sègaláwọn ènìyàn ÀAlààyèàwọn Ọjọ́ìbí ní 1971..
wikipedia
yo
Sabrina Draoui (tí wọ́n bí ní 24 Oṣù kọkànlá, Ọdún 1977) jẹ́ olùdarí eré àti olùyàwòrán ọmọ orílẹ̀-èdè Algeria.àwọn ènìyàn Alààyèàwọn Ọjọ́ìbí ní 1977..
wikipedia
yo
Hana el Zhed (tí wọ́n bí ní 5 Oṣù Kínní, Ọdún 1994) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Egypt.Àwọn Ènìyàn Alààyèàwọn Ọjọ́ìbí ní 1994itan ìgbésí ayé Reel Zdd a bí ní ọdún 1994..
wikipedia
yo