cleaned_text
stringlengths
6
2.09k
source
stringclasses
2 values
language
stringclasses
1 value
Nígbà èwe rẹ̀, Karemara jáfáfá nínu ìmọ̀ ìṣirò, ó sì maá n gbàá lérò láti sí ilé-iṣẹ́ bú..
wikipedia
yo
Karemera kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ National Conservatory of Theatre and Dance ní ìlú Brussels..
wikipedia
yo
Ní ọdún 1994, baba rẹ̀ pada sí orílẹ̀-èdè Bẹ́ljíọ̀m nítorí Ṣiṣẹ́mílò tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Rwanda nígbà náà..
wikipedia
yo
Karemera kó àkókò ipa nínú eré lórí ìpele ní ọdún 1996..
wikipedia
yo
Ó sì ti wá ṣe bẹ́ẹ̀ kópa nínu àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré ìpele míràn bíi The Trojan Women látọwọ́ Euripides, The Ghost Woman Látọwọ́ Kay Adshead, àti Anathema ṣááju kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe sinimá àgbéléwò..
wikipedia
yo
Laarin odun 2000 si 2004, o ko ipa olu-ẹ̀dá-itan ninu ere telifisonu ti akole re je Rwanda 94.Ni odun 2005, Karemara kopa gege bi Jeanne ninu fiimu Raoul Peck kan ti akole rẹ̀ jẹ Sometimes in April..
wikipedia
yo
Ọdún kan yìí náà ló pinnu láti máa gbé ní ìlú Kìgálì , orílẹ̀-èdè Rwanda..
wikipedia
yo
Lẹ́hìn tí ó padà sí orílẹ̀-èdè náà, Karemara kópa nínu àwọn iṣẹ́ àkànṣe tó níṣe pẹ̀lú àṣà orílẹ̀-èdè náà..
wikipedia
yo
Pẹlu àjọṣepọ̀ Cecilia kankonda, ó da “Sound Cathedral" sílẹ̀ láti máa gba iranti iṣẹlẹ aye àwọn eniyan silẹ ṣaaju ọdun 1994 ni Rwanda..
wikipedia
yo
Ní ọdún 2006, Karemara àti àwọn obìnrin méje míràn ṣe ìdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ shyo Arts ní ìlú Kìgálì léte láti gbé àṣà ìlú náà lákò.Karemara ti kópa gẹ́gẹ́ bi Beatrice nínú fíìmù Jùjú Factory ti ọdún 2007..
wikipedia
yo
O ti gba ami-eye ti oṣere ti o dara julọ nibii ayẹyẹ Festival cinema Africano, eyi to waye ni orilẹ-ede Italia..
wikipedia
yo
Christiana NkemdiLim Adelana tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí tàná Adelana (tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹrìnlélógún Oṣù kejìlá Ọdún 1984) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò, olóòtú, afẹ̀kasójú, atọ́kùn ètò agbọ̀n àti oníṣòwò ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà..
wikipedia
yo
Ó gbámin ẹyẹ ammúrálẹ́gbẹ̀ẹ́ olú-ẹ̀dá-ìtàn ti City People’s Movie Awards lọ́dún 2017, bẹ́ẹ̀ náà, ó gbamin-ẹyẹ the Future Awardsfún atọ́kùn ètò orí ìlú tó dára jù lọ lọ́dún 2011, àti Àmin-ẹ̀yẹ, The Grind Awards lọ́dún 2095..
wikipedia
yo
Tàná jẹ́ ọmọ igbó, láti ìdílé egbò.Ìgbà ewé ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ wọ́n bí tàná Adelana sí ìdílé ọba àti ìjọ Kátólíìkì lọ́dún 1984..
wikipedia
yo
O jẹ ọmọ bibi Nárà Unateze ni ijọba ibilẹ nkanu East LGA ni Ipinle Enugu..
wikipedia
yo
Òun ni àbígbẹ̀yìn nínú àwọn ọmọ mẹ́wàá tí àwọn òbí rẹ̀ bí..
wikipedia
yo
ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ ni treasure land Nursery and Primary School, Sùúrùlérè, ní ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ Nàìjíríà, bẹ́ẹ̀ náà ló tẹ̀ siwaju ní St..
wikipedia
yo
Francis Catholic Secondary School ni ìdìmú,ní Èkó bákan náà. Tàná kàwé gboyè dìgírì nínú ìmọ̀ àtọ̀ agbègbè àti ìlú, (Urban and Regional Planning) ní University of Lagos, Nàìjíríà..
wikipedia
yo
Lẹ́yìn èyí, ó kàwé gboyè dìlọ̀pọlọ nínú ìmọ̀ aṣaralóge ní London..
wikipedia
yo
Lẹ́yìn náà, ó lọ sí Metropolitan School of Business and Management, ní United Kingdom, ó sin gboyè dìgírì Kejì (Special Executive Masters Certificate).Iṣẹ́ Ìràwọ̀ tàná bẹ̀rẹ̀ sí ní tán lẹ́yìn tó pegedé nínú nínú ìdánwò Yw'lo’lo TV Show lọ́dún 2002 fún atọ́kùn ètò
wikipedia
yo
Bẹ́ẹ̀ náà òun ni ọmọ Nàìjíríà àkọ́kọ́ láti tòkun ètò lórí ìkànnìChannel ó níbẹ̀ ló ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré ṣíṣe lórí tẹlifísàn..
wikipedia
yo
Ó dá ilé iṣẹ́ sinimá tirẹ̀ sílẹ̀ lọ́dún 2013 tí ó pè ní tàná Adelana..
wikipedia
yo
Lára àwọn sinimá àgbéléwò wọ́n ní quick Sand, níbi tí Ufuoma Ejenobor, Chelsea Eze, Wale Macaulay, Anthony Monjárọ́, Femi Jacobs àti àwọn gbajúmọ̀ òṣèré mìíràn ti kópa.Àwọn Àmín-ẹ̀yẹ lọ́dún 2011, ó gbamin-èye atọ́kùn ètò fínà tó dára jù lọ ní Future Awards Àmin Ẹ̀yẹ Grind Awards lọ́dún 2015.
wikipedia
yo
Àmín Ẹyẹ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ olú ẹ̀dá ìtàn tí ó dára jù lọ ti City People's Movie Awards lọ́dún 2017.Àṣàyàn àwọn sinimá Remr..
wikipedia
yo
Revolution (2017)Body language (2017)Baby 2003’’ (2017)Àwọn Ìtọ́kasí..
wikipedia
yo
ṣọ́ra Agu jẹ́ ògbóntakú òṣèré orí-ìtàgé ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n bí ní ọdún 1956..
wikipedia
yo
Ó jẹ́ aláwàdà àti olùgbéré-jáde tí ó gba àmì-ẹ̀yẹ ti òṣèré kùrìn tó peregedé jùlọ nínú eré ìbílẹ̀ níbí ìsàmì ayẹyẹ Nollywood ní ọdún 2012..
wikipedia
yo
àwọn ọlọ́kàn-ó-jọ̀kan ìpèdè rẹ̀ tí ó ma ń lọ nínú eré ni ó sọọ́ di ààyò àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ àti lókè òkun.Ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé àwàdà jẹ́ ọ̀kan nínú irinṣẹ́ tí a lè máa lò láti gbé àṣà àti ìṣe orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ga ní ojú àwọn ènìyàn ilẹ̀ òkèrè.Agu ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú aya rẹ̀ nkéchi, wọ́n sì bí ọmọ [ọkùnrin]] mẹ́ta àti obìnrin méjì.Ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ reagu bẹ̀rẹ̀ eré ní pẹrẹu pẹ̀lú àwọn ipa ìrísírũr tí ó ti kó nínú àwọn eré onípele àtìgbà-dégbà tí wọ́n ma ń ṣàfihàn wọ́n lórí àwọn ìkànì èrò amóhùmáwòrán-máwòrán ilé wa ṣáájú kí wọ́n tó dá ilé-iṣẹ́ Nollywood sílẹ̀ ní nkan bí ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n sẹ́yìn sẹ́yìn..
wikipedia
yo
Agu tún kópa ní eré mìíràn bíi ẹ̀dá ìtàn fífàna.Àwọn Aṣayàn eré rẹa rí àkọsílẹ̀ tí ó fìdí rẹ.múlẹ̀ wípé Agu ti kópa ni u eré tí ó ti tó àádọ́ta.Àwọn sinimá àgbéléwò rẹàìgbọ́ra-ẹni yé tí ó wáyé lórí rẹagu fi ẹ̀hónú rẹ hàn wípé òun yóò ma bèrè fún owó gidi nígbà-kúùgba tí wọ́n bá fẹ́ kí òun kópa nínú eré kan tàbí òmíràn..
wikipedia
yo
ó sì tún ṣàfìwé Gibeah-wúyẹ́ tí ó ń jà ràìnkán ní ìgboro ẹnu lórí ihùwà ẹ̀gbin síni niínniq ìbálòpọ̀ ti ṣẹlẹ̀ ní agbo Nollywood gẹ́gẹ́ bí ìṣesí ọmọ ènìyàn..
wikipedia
yo
Ó tún fi kùn wípé àwọn olóríire ní àwọn òṣèré Nollywood.Àwọn ÌFISỌRÍ rẹwọn yàn án fún àmì-ẹ̀yẹ òṣèré ìbílẹ̀ tí ó gbayì jùlọ nínú eré ìbílẹ̀ ní u ayẹyẹ ìdánilólá ti Nollywood alákòókò irú rẹ̀ tí ó wáyé ní ọdún 2012, fún ipá rẹ̀ tí ó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ìtàn Nkwocha..
wikipedia
yo
Ipa ti Agu ko ninu ere The Maiìdens fun ni anfani lati je ki won yan an fun ami-eye ti "òṣèrékùnrin amúgbá-lẹgbẹẹ to peregede julo nibi aye ti Zulu African Film Academy Awards (ZAFAA London) 2011.Awon ami-eye reagu ni o gba ami-eye ti Nollywood alákòókò iru re ni odun 2012, fun òṣèrékùnrin ti o peregede julo ninu ere ibile..
wikipedia
yo
Ó sí tún gba ami-ẹ̀yẹ fún ipa rẹ̀ tí ó kó gẹ́gẹ́ bí èè-ìtàn Nkwo''. ìkakạ́ani málé Film Actorṣàwọn ènìyàn òlomale Actors from Enugu Stateàwọn Ọjọ́ìbí ni 1956datè of Birth Missing (Living People) Century Nigerian Malerin-21st Nigerian Malerin- Nigerian Malelógo..
wikipedia
yo
FRANÇOISE Ellong (tí a bí ní 8 Oṣù Kínní, Ọdún 1988) jẹ́ olùdarí fíìmù àti ònkọ̀wé ọmọ orílẹ̀-èdè KaKamẹrúùnù.I rẹ̀ a bí Ellong ní ìlú Douala, orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù ní ọdún 1988..
wikipedia
yo
Nígbà tó wà lọ́mọdún mọ́kànlá, ó gbé pẹ̀lú mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan ní ìlú Brunoy, níbi tí ó ti kọ àkọ́kọ́ ìtàn rẹ̀..
wikipedia
yo
Ellong kópa nínu ìdíje kan tó wà fún àwọn ònkọ̀wé elédè Faransé ní ọdún 2002..
wikipedia
yo
Nípasẹ̀ ìdíje náà, ó padà wá ní ìfẹ́ sí kíkọ ìtàn eré.Ní ọdún 2006, àkọ́kọ́ fíìmù oníṣókí rẹ̀ táa mọ àkọ́lé rẹ̀ ní Les Colocs, jẹ́ gbígbéjáde..
wikipedia
yo
Ellong darí àkọ́kọ́ fíìmù gúngùn rẹ̀ ní ọdún 2013, èyítí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ W.A.K.A..
wikipedia
yo
seramatu Kakouang lo ṣeto kikọ ere naa, sugbọn Ellong funra lo dabaa itan ere naa..
wikipedia
yo
W.A.K.A gba ami-eye nibi ayeye <i>Festival du cinema Africain de Khouribwe</i>, ati nibi ayeye Pan-African Festival of Cannes..
wikipedia
yo
Ekeji fiimu gùngùn rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ uriuri jẹ́ gbígbéjáde ní ọdún 2020..
wikipedia
yo
Eré náà dá lóri pípàdé àwọn ọ̀rẹ́ àtijọ́ tí wọ́n ti pínyà fún ìgbà pípẹ́..
wikipedia
yo
Ó rí ìwúrí láti ṣe fíìmù náà nínu ìròyìn kan tí ó rí lóri tẹlifíṣọ̀nù.Yàtọ̀ sí dídarí àti kíkọ ìtàn eré, Ellong tún ti ní àtẹ̀jáde ìwé tí àkọ́lé rẹ̀ n ṣe "Journal Intime d'un Meurkan," èyí tó jáde ní ọdún 2008..
wikipedia
yo
Ni ọdun 2016, o da pẹpẹ iroyin kan silẹ ti o pe ni "Le Film camerounais", eyiti o sokun fa awọn ami-eye ti LSTC..
wikipedia
yo
Christiane Chabi-Kao (tí a bí ní 30 Oṣù kẹẹ̀fà, Ọdún 1963) jẹ́ olùdarí eré àti ònkọ̀tàn ọmọ orílẹ̀-èdè Benin.Itọ̀ ayé rẹ̀ a bí Chabi-Kao ní ìlú Marseille, orílẹ̀-èdè Fránsì ní ọdún 1963..
wikipedia
yo
Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga <i>University of Reims Champagne-Ardennei</> láti ọdún 1984 sí 1986..
wikipedia
yo
Ó ṣe àkọ́kọ́ fíìmù rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Les Enen Esclaves ní ọdún 2005, eré tí n ṣe àpèjúwe àwọn ẹrú ode-oni.ní ọdún 2007, ó ṣe adarí fíìmù Les inseparables..
wikipedia
yo
Eré náà dá lóri ìtàn àwọn tẹ̀gbọ́ntàbúrò kan, Yawa àti Abi, tí bàbá wọn gbé tà fún àwọn agbọ́mọfiṣiṣẹ́..
wikipedia
yo
Ààjọ UNICEF àti Beninese National Radio and Television (ORBB) ni wọ́n ṣe onígbọ̀wọ́ fún ṣíṣe fíìmù náà..
wikipedia
yo
Chabi-Kao kọ fíìmù náà léte láti La àwọn èyàn lọ́yẹ̀ nípa gbígbé ọmọdé fi ṣiṣẹ́ àti láti dẹ́kun irú ìwà bẹ́ẹ̀..
wikipedia
yo
Fíìmù náà gba àmì-ẹ̀yẹ níbi àjọ̀dún Vues d'Afrique, èyí tí ó wáyé ní ìlú Montreal ní ọdún 2008, ó sì tún gba ẹ̀bùn tí Human Rights gbé kalẹ̀ níbi ayẹyẹ <i>Panafrican Film and Television Festival of Ouagadougou</i> ti ọdún 2009.Ní ọdún 2009, ó rọ́pò Monique mbeke Phoba gẹ́gẹ́ bi adarí fún ti ayẹyẹ àjọ̀dún Lafẹ́mages ti ìlú Kútọnu..
wikipedia
yo
O sise didari ajọdun naa fun ọpọlọpọ ọdun ṣaaju ki wọn to gbaa tọwọ́tẹsẹ̀ gẹgẹ bi oludari, o si ri iranlọwọ lati odo Deutsche Welle Academy fun kikọ bi o se le maa ṣeto ajọdun naa.Chabi-Kao lẹni ti o kọ itan ere Telifisonu les Chenapans ti ọdun 2013, to si tun dari rẹ..
wikipedia
yo
Sarah Magaajyia Silberfeld (tí a bí ní 30 Oṣù Kẹẹ̀jọ, Ọdún 1996) jẹ́ òṣèrébìnrin àti olùdarí eré ọmọ orílẹ̀-èdè Nìjẹ̀r àti Fránsì rẹ̀ Silberfeld jẹ́ ọmọ sí olùdarí eré táa mọ̀ sí Rahmatou Keïta àti oníṣẹ́ ìròyìn Antoine Silber..
wikipedia
yo
Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré ìtàgé ní agbègbè rẹ̀ nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mọ́kànlá..
wikipedia
yo
Silberfeld dàgbà ní orílẹ̀-èdè Fránsì, ṣùgbọ́n ó máa ń rin ìrìn-àjò nígbàgbogbo lọ sí orílẹ̀-èdè Gíríìsì, Nìjẹ̀r, àti Mali, bẹ́ẹ̀ ló sì tún gbé ní ìlú Los Angeles fún ọdún mẹ́ta..
wikipedia
yo
Ó kó àkọ́kọ́ ipa fíìmù rẹ̀ ní ọdún 2011 nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ La Lisière..
wikipedia
yo
Silberfeld kẹ́kọ̀ọ́ eré ṣíṣe ní ilé-ẹ̀kọ́ <i> Strasberg Institute</</i> ní ọdún 2013, àti ní Playhouse West Repertory Theatre ní ọdún 2014 àti ní Susan Batson Studio ní ọdún 2015..
wikipedia
yo
Nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún, ó kọ àkọ́kọ́ eré oníṣókí rẹ̀ tó sì tún darí rẹ̀..
wikipedia
yo
Yàtọ̀ sí eré rẹ̀ tí ó kò tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Me There, ó tún darí eré Ride or Die, èyítí ó ṣàfihàn Piper de Palma àti Roxane Departs.Ní ọdún 2016, Silberfeld ní àkókò ipa Olú-ẹ̀dá-ìtàn nínu eré The Wedding Ring, eré tí ìyá rẹ̀ darí..
wikipedia
yo
Ó kópa gẹ́gẹ́ bi tíyàá, ọmọbìnrin kan tí ó lọ kàwé ní ìlú Fránsì níbití ó ti pàdé tó sì yó fún ìfẹ́ ọmọkùnrin kan..
wikipedia
yo
Fíìmù náà jẹ́ àkọ́kọ́ fíìmù ti orílẹ̀-èdè Nìjẹ̀r tó jẹ́ wíwò níbi àwọn ayẹyẹ Academy Awards..
wikipedia
yo
Ní ọdún 2017, ó ṣe adarí fíìmù oníṣókí kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ VagaBonds, èyítí ó ṣàfihàn Danny Glover..
wikipedia
yo
Ní ọdún kan yìí náà ní Silberfeld gba oyè-ẹ̀kọ́ láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Sorbonne..
wikipedia
yo
Roukiata Ouedraogo (tí a bí ní 1979) jẹ́ ònkọ̀tàn, òṣèré àti apanilẹ́ẹ̀rín ọmọ orílẹ̀-èdè Bùrkínà Fasọ̀.Isẹ̀mí rẹ̀ Rouijù dàgbà ní ìlú dáátara N'Ma..
wikipedia
yo
Nígbà tí ó wà lọ́mọdé, Ouedraogo lọ sí ìlú Ouagadougou láti tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀..
wikipedia
yo
Nígbà tí ó wà ní ilé-ìwé girama, ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ìtàgé, èyí tí ó fún ní ànfààní láti káàkiri orílẹ̀-èdè náà..
wikipedia
yo
Ní àkókò náà, ó maá n dirun tó sì tún maá n ránṣọ́ fún àwọn èyàn láti máa fi bọ́ ararẹ̀..
wikipedia
yo
Lẹ́hìn ìparí ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó kó lọ sí ìlú Paris ní ọdún 2000, níbití ẹ̀gbọ́n rẹ̀ n gbé.Ó ti ṣiṣẹ́ rí gẹ́gẹ́ bi aṣaralóoge àti afẹwàṣiṣẹ́ láìmoye ọdún..
wikipedia
yo
Ní ọdún 2007, Ouedraogo pinnu láti gbájúmọ́ eré ìtàgé, ó sì rí ànfààní láti kópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù <i>Cours ṣo</i> lẹ́hìn àyẹ̀wò.Àwọn Ìtọ́kasí àwọn ènìyàn Alààyèàwọn Ọjọ́ìbí ní 1979..
wikipedia
yo
Mariam Kaba (tí a bí ní 9 Oṣù Kẹẹ̀jọ Ọdún 1961) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Fránsì àti Guinea.Itọ̀ rẹ̀ a bí Kaba ní ìlú Kankan, orílẹ̀-èdè Guinea..
wikipedia
yo
Ó kó lọ sí orílẹ̀-èdè Fránsì ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1980..
wikipedia
yo
Lẹ́hìn tí ó parí ẹ̀kọ́ girama rẹ̀, Kaba forúkọsílẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ École des nouveaux métiers de la communication ní àtẹ̀lé àkọ́ bàbá rẹ̀..
wikipedia
yo
Ó lọ ilé-ẹ̀kọ́ náà fún ọdún kan ṣoṣo, tó sì n lo owó tí bàbá rẹ̀ fi ránṣẹ́ sí láti fi kẹ́kọ̀ọ́ eré ṣíṣe lábẹ́ olùkọ́ Isabelle dodoyan.Àkọ́kọ́ ipa Kaba lóri ìpele wáyé gẹ́gẹ́ bi ìyàwó fún Toussaint Louverture, ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Benjamin Jules-Rosette, ẹni tí ó jẹ́ olùdarí..
wikipedia
yo
Lẹ́hìn ìgbà náà, ó tún kó ipa kan nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Marc and Sophie..
wikipedia
yo
Ní ọdún 1989, Kaba kó àkọ́kọ́ ipa sinimá àgbéléwò rẹ̀ nínu fíìmù táa pe àkọ́lé rẹ̀ ní Périgord noir, èyí tí Nicolas Ribowski darí..
wikipedia
yo
Ó kópa gẹ́gẹ́ bi Maina nínu eré náà, Ọ̀dọ́bìnrin kan tí ó n ṣiṣẹ́ ní agbègbè Périgord..
wikipedia
yo
Ní ọdún 1992, ó kó àkọ́kọ́ ipa rẹ̀ nínu sinimá àgbéléwò ti ilẹ̀ Áfíríkà, èyí tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Blanc d'ẹ́bène..
wikipedia
yo
Eré náà dá lóri Ogun Àgbáyé Ẹlẹ́ẹ̀kejì, tí olùdarí rẹ̀ síì jẹ́ Cheik Doukouré, níbití òun ti kó ipa nọ́ọ̀sì kan tí ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú olùkọ́ni Landìídì Kante..
wikipedia
yo
Kaba tún hàn nínu eré Idrissa Ouedraogo kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Samba Traoré ní ọdún 1992 bákan náà..
wikipedia
yo
Ó tún bá Doukouré ṣiṣẹ́ pọ̀ lẹ́ẹ̀kansi ní ọdún 1994 nínú ẹrẹ̀ lé Ballon d'Orrara bi ọmọkùnrin rẹ̀ ní ọdún 1999, ṣùgbọ́n ní ọdún 2000, Kaba tún hàn nínu eré gẹ́gẹ́ bí Pauline Lumumba, ìyàwó olóṣèlú Patrice Lumumba, nínú eré Raoul Peck kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Lumumba..
wikipedia
yo
Awa Sène Sarr jẹ́ òṣèrébìnrin àti apanilẹ́ẹ̀rín ọmọ orílẹ̀-èdè Sẹ́nẹ́gàl.Itọ̀ rẹ̀ Awa Sène Sarr lẹnìkan tí ó ní ìfẹ́ sí láti di amòfin tó sì ṣe bẹ́è kẹ́kọ̀ọ́ òfin ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ìlú Dakar..
wikipedia
yo
Lẹhin naa o forukọsilẹ lati kẹkọọ ere ṣiṣe ni National Institute of Arts of Dakar ni Orilẹ-ede Senegal, o si gboye ni ọdun 1980..
wikipedia
yo
Sarr ti kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ayẹyẹ àjọ̀dún fíìmù tó fi mọ́ ti Cannes ní ọdún 2005..
wikipedia
yo
Ní ọdún 2000, ó kó ipa gẹ́gẹ́ bi Mada nínu eré Ousmane Sembène kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Faat KinkeSarr ti kópa nínu àwọn eré tó lé ní ogójì, tó fi mọ́ eré tí àwọn ònkọ̀tàn bíi Marie n'aye, Ahmadou Kourouma, Catherine Anne àti Philippe Blasband kọ..
wikipedia
yo
Ó máa ń ṣe olóòtú ètò Horlonge du Sü Literary cafe ní gbogbo OṢOOṢÙ ní ìlú Brussels, léte láti gbé àṣà ilẹ̀ Áfíríkà lárugẹ..
wikipedia
yo
O se atọkun eto redio kan to da lori ewi ede Wolof ti akọle rẹ n jẹ Twayefi Doba rèéw lori ikanni redio radiodiffusion Television Sègaláìṣẹ̀ (RTS).Sarr ti ko ipa gege bi aje kan ninu awon fiimu meta ti Michel Ocelo.[2..
wikipedia
yo
Nnwaẹ̀gọ̀ (ẹ̀gọ̀) bọyọ̀ (Bii ní ọjọ́ kẹfà osu Kesan-an, ọdún 1968) je osere ni orile ede Naijiria ti o gbajumọ fun ipa Anne Háàaga ninu ere Checkmate..
wikipedia
yo
Òun ni Ààrẹ fún ẹgbẹ́ International Women Society (Iws) èyí tí wọ́n gbé kalẹ̀ ní ọdún 1957..
wikipedia
yo
O jẹ iyawo fun ọmahaMofẹ́ bọyọ̀ ti o jẹ ikan laarin awọn adari ni ile ise ọ́Gdo Plc.Iṣẹ ẹ̀gọ̀ bọyọ̀ bẹrẹ ere sise ni ọdun 1990 nigba ti o kopa ninu ere Checkmate..
wikipedia
yo
O bẹrẹ ile ise tire ti o pe ni Temple Productions ni odun 1996..
wikipedia
yo
O gbe ere a Hotel called Memory jade ni odun 2017, ere naa si gba ami eye Best experimental Film nibi ayeye Blackstar Film Festival ni orile ede philadelówómeje itọkasi..
wikipedia
yo
Samantha Mugatsia (tí a bí ní ọdún 1992) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Kẹ́nyà.Itọ̀ rẹ̀ a bí Mugatsia ní ọdún 1992..
wikipedia
yo
Ó dàgbà ní ìlú Nairobi, ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ẹ̀gbẹ́ àyàn kan tí wọ́n pè ní The Yellow Machine..
wikipedia
yo
Mugatsia kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀fin ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Catholic University of Eastern Africa, ṣùgbọ́n ó dáwọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀ dúró láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré rẹ̀..
wikipedia
yo
Ní oṣù kọkànlá ọdún 2016, ó pàdé olùdarí eré tí orúkọ rẹ̀ ń ṣe wwrí Kahiu, ẹnití ó pe Mugatsia láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú eré tuntun tí ó ń gbèrò láti gbé jáde, Mugatsia náà sìí faramọ́.Ní ọdún 2018, Mugatsia kópa gẹ́gẹ́ bi Kena Mwaura, ọ̀kan lára àwọn olú-ẹ̀dá-ìtàn ti eré Rafiki..
wikipedia
yo
Ìtàn náà dá lórí Iwe-Ìtàn Jambula Tree tí ònkọ̀wé ọmọ orílẹ̀-èdè Uganda kan kọ..
wikipedia
yo
Ní ìgbaradì fún ipa náà, Mugatsia ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbìyànjú láti ri dájú wípé yóò le ṣètò ipa náà pẹ̀lú irọrun..
wikipedia
yo
Wọ́n fi òfin de fiimu naa ní orílẹ̀-èdè Kenya, nítorí wípé òfin orílẹ̀-èdè náà kò fàyè gba ìbálòpọ̀ láàrin àwọn ẹlẹ́yà kannáà..
wikipedia
yo
Rafiki jẹ́ àkọ́kọ́ fíìmù ti Kenya tí ó jẹ́ wíwò níbi àwọn ayẹyẹ Cannes Film Festival..
wikipedia
yo
Nicole Amarteifio (tí a bí ní ọdún 1982) jẹ́ agbéréjáde, olùdarí àti ònkọ̀tàn eré ọmọ orílẹ̀-èdè Ghana.Itọ̀ rẹ̀ a bí Amarteifio ní orílẹ̀-èdè Ghánà ṣùgbọ́n ó gbé ní ìlú Lọ́ndọ̀nù fún ọdún mẹ́fà láti ìgbà tí ó fi wà lọ́mọ Oṣù mẹ́ta nítorí ìfipágbà tí ó ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè rẹ̀..
wikipedia
yo