cleaned_text
stringlengths
6
2.09k
source
stringclasses
2 values
language
stringclasses
1 value
Yorùbá gbàgbọ́ wí pé Elédùmarè ni olùdájọ́ ìyè nì wí pé Elédùmarè ni adájọ́ tó ga jù láyé àtọ̀run, òun ni ọba adáke dájọ́, àwọn òrìṣà lọ, máa ń jẹ àwọn orufin níyà ṣùgbọ́n Ọlọ́run ló ń dájọ́..
wikipedia
yo
Bí àpẹẹrẹ ni ìgbper kan láyé ọjọ́un àwọn òrìṣà fẹ̀sùn kan Ọ̀rúnmìlà níwájú Elédùmarè, lẹ́yìn tí tọ̀tùn tòsì wọn ròjò tán Elédùmarè dá Ọ̀rúnmìlà láre..
wikipedia
yo
Òdú Ifá kan ó báyìí wí pé ọ̀kánjúà kìí jẹ́ kí á mọ nǹkanán-pín, Adia run ọdú mẹ́rìndínlógún níjọ́ tí wọ́n ń jìjà àgbà lọ ilé Elédùmarè, nígbà tí àwọn ọmọ irúnmọlẹ̀ mẹ́rìndínlógún ń jíjà tani ẹ̀gbọ́n tàn í àbúrò, wọn kí ejò lọ sí ọ̀dọ̀ Elédùmarè, níkẹyìn Elédùmarè dájọ́ wí pé èjìǹ ni àgbà fún àwọn odù yókù..
wikipedia
yo
Yorùbá gbàgbọ́ wi pé onidajọ òdodo ni Elédùmarè ìdí ní yí tí Yorùbá fi máa ń sọ wí pé Ọlọ́run mún-un tàbí ó wà lábẹ́..
wikipedia
yo
Pàṣán elédùmarè ní ọ̀nà míràn Yorùbá gbàgbọ́ wípé ọ̀tá àìkú ni Elédùmarè Yorùbá máa ń sọ wípé rerekufẹ a kì í gbọ́ ikú Elédùmarè..
wikipedia
yo
Ní àkótán Yorùbá gbàgbọ́ wí pé ọba tó mọ ọba ti jẹ ní èérí ni Elédùmarè ń ṣe..
wikipedia
yo
Òun ni àwọn Yorùbá ń pè ní àlàfunfunfunfun ọkàn àwọn Yorùbá gbàgbọ́ wí pé bí àwọn Angelú ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún elédùmarè lóde ọ̀run bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn òrìṣà jẹ́ òrurànlọ́wọ́ fún elédùmarè lóde ayé..
wikipedia
yo
Àwọn òrìṣà wọ̀nyí sì ni wọ́n jẹ́ alágbàwí fún àwọn ènìyàn lóde elédùmarè.Àwọn ìtọ́ka si..
wikipedia
yo
Ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ-ẹ̀dá jẹ́ ẹ̀kọ́ kan pàtàkì tí kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn..
wikipedia
yo
Kò sí ẹ̀dá alààyè tó dá wà láì ní Olùtan tàbí alájo..
wikipedia
yo
Orísirísi ènìyàn ló parapọ̀ di àwùjọ-bàbá, ìyá, ará, ọ̀rẹ́, olùbátan ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ..
wikipedia
yo
Bí ìyá ṣe ń bí ọmọ, tí bàbá ń wo ọmọ àti bí ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ ṣe ń báni gbé, bẹ́ẹ̀ ni ìbá gbépọ̀ ẹ̀dá n gbòòrò si..
wikipedia
yo
Àti ẹ̀ni tí a bá tan, àti ẹni tí a kò tan mọ́, gbogbo wa náà la parapọ̀ di àwùjọ-ẹ̀dá..
wikipedia
yo
Ní ilẹ̀ Yorùbá ati níbi gbogbo ti ẹ̀dá ènìyàn ń gbé, ìbágbépọ̀ ẹ̀dá ṣe pàtàkì púpọ̀..
wikipedia
yo
Bí ẹnìkan bá ní òun ò bá ẹnikẹ́ni gbé, tí kò bá gbé nígbó, yóó wábi gbàlọ..
wikipedia
yo
Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn bá ń gbé papọ̀, ó rọrùn lati jọ parapọ̀ dojú kọ ogun tàbí ọ̀tẹ̀ tí ó bá fẹ́ wá láti ibikíbi..
wikipedia
yo
Gbígbé papọ̀ yìí máa ń mú ìdádúró láì sí ìbẹ̀rù dání nítorí bí òṣùṣù ọwọ̀ ṣe le láti ṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwùjọ tó fohùn ṣọ̀kan..
wikipedia
yo
Èyí jẹ́ oun pàtàkì lára àǹfàní tó wà nínú ìṣọ̀kan nínú àwùjọ-ẹ̀dá..
wikipedia
yo
Nídà kejì, bí ọ̀rọ̀ àwùjọ-ẹ̀dá bá jẹ́ kónkó-jabele, ẹ̀tẹ́ àti wàhálà ni ojú ọmọ ènìyàn yóó máa rí..
wikipedia
yo
Ìdàgbàsókè tí ó máa ń wà nínú àwùjọ kò sẹ̀yìn ìfọwọ́sowọ́pọ̀ bí àti ránmú ùn gángan ò ti sẹ̀yìn èékánná..
wikipedia
yo
Ó yẹ kí á mọ̀ pé nítorí ìdàgbàsókè ni ẹ̀dá fì n gbé papọ̀..
wikipedia
yo
Bí igi kan ò ṣe lè dágbó ṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹnìkan ò lè dálùúgbé..
wikipedia
yo
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló máa ń dá ọgbọ́n jọ fún ìdàgbàsókè ìlú..
wikipedia
yo
Bí Ọgbọ́n kan kò bá parí iṣẹ́, Ọgbọ́n mìíràn yóó gbè é lẹ́yìn..
wikipedia
yo
Níbi tí orísirísi ọgbọ́n bá ti parapọ̀, ìlọsíwájú kò ní jìnnà sí irú agbègbè bẹ́ẹ̀..
wikipedia
yo
Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ àǹfàní tó wà ní àwùjọ-ẹ̀dá tí kò sì ṣe é fi sílẹ̀ láì mẹ́nu bà..
wikipedia
yo
Nínú ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ-ẹ̀dá, a tún máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìsòro tó ń kojú ìbágbépọ̀ ẹ̀dá..
wikipedia
yo
A kò lè ronú lọ́nà kan ṣoṣo, nítorí náà, ìjà àti asọ̀ máa ń jẹ́ àwọn nnkan tí a kò lè ṣàì má rì í níbi tí àwọn ẹ̀nìyàn bá n gbé..
wikipedia
yo
Wàhálà máa ń fa ọ̀tẹ̀, ọ̀tẹ̀ ń di ogun, ogun sì ń fa ikú àti fífi dúkàá ṣòfò..
wikipedia
yo
Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ara àwọn ìṣòro tó ń kojú àwùjọ-ẹ̀dá..
wikipedia
yo
Kò sí bí ìlú tàbí orílẹ̀-èdè kan kò ṣe ní ní ọ̀kan nínú àwọn àwọn ìṣòro wọ̀nyí..
wikipedia
yo
Ṣùgbọ́n, a gbọ́dọ̀ mọ̀ wí pé àwọn ànfàní àti àwọn ìṣòro wọ̀nyí ti wà láti ìgbà pípẹ́ wá..
wikipedia
yo
Tí a bá wo àwọn ìtàn àtijọ́ gbogbo, a ó ri pé gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí kò jẹ́ tuntun..
wikipedia
yo
Ọgbọ́n ọmọ ènìyàn ni ó fi ṣe ọkọ̀ orí-ìlẹ, ti orí-omi àti ti òfúrifú fún ìrìnkèrindò tí ó rọrùn..
wikipedia
yo
Àwùjọ-ẹ̀dá ti ṣe àwọn nnkan dáradára báyìí náà ni wọ́n n ṣe àwọn ohun tí ò le pa ẹ̀nìyàn lára..
wikipedia
yo
Àwọn ohun ìjà wọ̀nyí ni wọ́n lò ní ogun àgbájé kìnní tí o wáyé ní ọdun 1914 sí 1918 àti ti èkejì ní odún 1939 sí 1945..
wikipedia
yo
Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ló ti wá tí ó sì tún wà síbẹ̀ di òní..
wikipedia
yo
Lákòótán, ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ-ẹ̀dá jẹ́ ẹ̀kọ́ tó lárinrin..
wikipedia
yo
Ohun kan tí a gbọ́dọ̀ mọ̀ nip é, kò ṣe é ṣe kí ẹ̀dá máa gbé ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan..
wikipedia
yo
Ìdí ni pé gbígbé papọ̀ pẹ̀lú ìsọ̀kan àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ló lè mú ìtẹ̀síwájú àti ìdàgbà-sókè wá..
wikipedia
yo
Ilu iwọ jẹ ilu ni IpinleOsun Osun ni Naijiria.Awon ilu ati Abule ni Naijiria..
wikipedia
yo
Ògbómọ̀sọ́ jẹ́ ìlú kan tó gbajúmọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yo lórílẹ̀-èdè Nàíjíríà.ìtàn nípa ìlú Ògbómọ̀sọ́ ÒGÚNd jẹ́ ọdẹ, ìtaritari, tí ó MON nípa òdee ṣiṣẹ́ ó fẹ́ láti máa lọ ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀kọ́ tí a máa maa ní ìlú Ògbómọ̀sọ́ tí a pè ní Igbó igbale, ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí tí ó jẹ́ ÒGÚNLỌ ṣe Baale adugbo ti ó ÒGÚNLÁ gbé nígbà náà..
wikipedia
yo
Orùn ò ríi wí pé ÒGÚNd gbé adutu àròkọ náà lọ sí ọ̀dọ̀ Aláàfin..
wikipedia
yo
Aláàfin àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ yìí àròkọ náà títí, wọ́n sì mọ ọ́ tí..
wikipedia
yo
Pẹ̀lú LIHHH, ìfòyà, àìbalẹ̀ ọkàn nípa ogun ogbóro tí ń bẹ lọ dé Ọ̀yọ́, kò mú wọn ṣe ohunkohun lórí ọ̀rọ̀ Ògúnlọlá, wọ́n sì fi í pamọ́ sí ilẹ̀ olòṣì títí wọn yóò fi rí ìtumọ̀ sí àròkọ náà.Ní ọjọ́ kan, Ògúnlọlá ń ṣe ọdẹ nínú Igbó igbalé-àdúgbò i bí ti gbọ̀ngàn ìlú ógbìmọ̀ wà lónìí..
wikipedia
yo
Igbó yìí, igbó kìjikìji ni, ó sọ̀rọ̀ dojúkọ kí jẹ́ pé ọdẹ ni ènìyàn, kò dá títí di ìgbà tí ojú ti là sí i bí ọdún 1935, ẹ̀rù jẹjẹ l'ó tún jẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ìlú láti wò ó nítorí wí pé onírúurú àwọn Enranko búburú l'ó kún ibẹ̀..
wikipedia
yo
Àní ní ọdún 1959, ìkọ́ko ja wọ ile ogunjẹ nlẹ̀ ní ìsàlẹ̀-pinpin gẹ́gẹ́ bí ìròyìn, ikooko ja náà jáde láti inú igbó ìgbàlẹ̀ yìí ni àwọn alágo (àwọn baálẹ̀ tí wọ́n ti kú jẹ́ rí ni Ògbómọ̀sọ́, tí wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́sìn-ìbílẹ̀) máa ń gbé jáde nígbà tí ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀ bá ń ṣe ọdún ọ̀lẹ̀lẹ̀..
wikipedia
yo
Láti pa á mọ́ gẹ́gẹ́ bí òpè títí di òní, nínú gbọ̀ngàn Ògbómọ̀sọ́ ni àwọn alága náà ń ti jáde níwọn ifbá tí ó jẹ́ wí pé ara àwọn ìgbì ìgbàlẹ̀ náà ni ó jẹ́..
wikipedia
yo
Ògúnlọlá kò tí ì tín jìnnà láti ìdí igi ajábọ́n (ó wá di òní) tí ó fi ń rí èéfín..
wikipedia
yo
Èéfín yìí jẹ́ ohun tí ó yà á lẹ́nu nítorí kò mọ̀ wí pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wà ní ìtòsí rẹ̀ Ògúnlọlá pinnu láti tó pàṣẹ èéfín náà ká má bá ọ̀pọ̀ lọ sílẹ̀ ọlọ́rọ̀, àwọn ògbójú ọdẹ náà rí ara wọn, inú swọ́n sì dùn wí pé àwọn jẹ́ pàdé..
wikipedia
yo
Lẹ́yìn tí wọn rí ara wọn tán, tí wọ́n sì mọ ara wọn; wọ́n gbìdánwò láti mọ ibi tí olúkálukú dó sí ibùdó wọn..
wikipedia
yo
Wọ́n sì fi ibùdó Ògúnlọlá ṣe ibi ìnàjú lẹ́yìn iṣẹ́ òòjọ́ wọn..
wikipedia
yo
lọ́run-un-gbẹ́kún ń ṣe ẹ̀wà ta, ó sì tún ń pọn ọtí ká pẹ̀lú; ìdí nìyìí tí ó fi rọrùn fún àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ lọ́rùn-un-gbẹ́kún láti máa takú-ro àti láti máa bá ara wọn dámọ̀ràn..
wikipedia
yo
Ìtàn fi yé wa wí pé ọba Aláàfin tí ó wà nígbà náà ni Ajágbọ́..
wikipedia
yo
rọgbọ deyan ati aápọn sì wà ní àkókò tí Ògúnlọlá gbé arọ kọ́ náà lọ sí ààfin ọba; ogun ni, ogun t'ó sì gbóná gírígírí ni pẹ̀lú-orúkọ ogun ni, ogun náà ni ogun ogbórò..
wikipedia
yo
Sí, ni ó tí ránṣẹ́ sí Aláàfin wí pé bí wọ́n bá le gba òun láàyè òun ni ìfẹ́ sí bí bá wọn ni pa nínú ogun ogbóró náà..
wikipedia
yo
Ẹni tí a fi tì, pàrọwà fún Ògúnlọlá nítorí wí pé ogun náà le púpọ̀ àti wí pé kò sí bí ènìyàn tilẹ̀ le è ní agbára tó tí ó lè ṣẹ́gun ọlọfẹ́ náà..
wikipedia
yo
Wọn kò leè ṣe àpèjúwe ọlọ̀tẹ̀ náà; wọ́n ṣá mọ̀ wí pé ó ń pa kúkúrú, ó sì ń pa gígùn ni..
wikipedia
yo
Aláàfin fún Ògúnlọlá láṣẹ láti ràn ran òun lọ́wọ́ nípa ogun ogbórọ náà..
wikipedia
yo
Alafín ka Ògúnlọlá sí ẹni tí a fẹ́ sùn jẹ́, tí ó fi epo ra ara tí ó tún sùn sí ìdíi àárọ̀, ó mú iṣẹ́ẹ sísun ya ni..
wikipedia
yo
Ògúnlọlá dójú ogun, ó pitú méje ti òde pa nínú igbó ó ṣe gudugudu méje Adu mẹ́fà..
wikipedia
yo
Àwọn jagun-jagun Ọ̀yọ́ fi ibi ọ̀tá gúnwà sí lórí poìyè han atamáàtijọ́ Ògúnlọlá, ogunibùdó sí “gan-an-ni” rẹ̀..
wikipedia
yo
Níbi tí ọ̀tá Aláàfin yìí ti ń gbìyànjú láti yọ ojú síta láti ṣe àwọn jagun-jagun lọ́ṣẹ́ ṣe ọfà tó sì lọ́rọ̀ ni ọlọ̀tẹ̀ yìí ń lọ; mo keje ní ọlọ̀tẹ̀ kò tí ì mórí bọ́ sínú tí ọrun fi yọ lọ́wọ́ Ògúnlọlá; lọ́run ló sì ti bá ọlọ̀tẹ̀; gbirigìdì la gbọ́ tọ ọlọ̀tẹ̀ rẹ̀ lulẹ̀ lọGídò..
wikipedia
yo
Inú gbogbo àwọn jagun-jagun Ọ̀yọ́ sì dùn wọ́n yó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ọmọdé ti ṣẹ̀ẹ́ yọ̀ mọ́ ẹyẹ..
wikipedia
yo
Ògúnlọlá ó gbé e, ó di ọ̀dọ́ Aláàfin; nígbà yìí ni Aláàfin tó mọ̀ wí pé ẹlẹ́mọ̀ṣọ́ ní ń ṣe àlèsa lẹ́yìn àwọn ènìyàn òun..
wikipedia
yo
Báyìí ni Ògúnlọlá ṣe àṣeyọrí ohun tí ó ti ẹ̀rù jẹ́jẹ́ sí ọkàn àyà àwọn ará ìlú Ọ̀yọ́..
wikipedia
yo
Aláàfin gbé òṣìbá fún Ògúnlọlá fún iṣẹ́ takun-takun tí ó ṣe, ó sì rọ̀ ọ́ kìí ó dúró nítòsí òun; ṣùgbọ́n Ògúnlọlá bẹ̀bẹ̀ kí òun pàpa sí ibùdó òun kí ó ó máa ránṣẹ́ sí òun..
wikipedia
yo
Báyìí Aláàfin Tú Ògúnlọlá sílẹ̀ láàfin nínú ìgbèkùn tí a fií sì kò ní jẹ́ àwáwí rárá láti sọ wí pé nínú ìlàkàkà àti làálàá tí Ògúnlọlá ṣe rí ẹ̀yin ẹlẹ́mọ̀ṣọ́ ní kò jọ sí pàbó tí ó sì mú orúkọ Ògbómọ̀sọ́ jáde..
wikipedia
yo
Èrèdí rẹ̀ nìyìí gbàrà tí a tú Ògúnlọlá sílẹ̀ tán pẹ̀lú àṣẹ Aláàfin tí ó sì padà sí ibùdó rẹ̀ ní ìdí igi àjàgbọ́n ní bí ẹ̀rọ bá ń lọ tí wọ́n ń bọ̀, wọn yóò máa ṣe àpèjúwe ibùdó Ògúnlọlá gẹ́gẹ́ bíi bùdó ó-gbé-orí-ẹlẹ́mọ̀ṣọ́; nígbà tí ó tún ṣe ó di Òpa-ẹlẹ́mọ̀ṣọ́ kó tó wá di ọgbẹ́lẹ́mọ́; ṣùgbọ́n lónìí pẹ̀lú ọ̀làjú ó di Ògbómọ̀sọ́ìṣèlú ní Ògbómọ̀sọ́Baálẹ̀ ní Olórí Ìlú Ogbomoso..
wikipedia
yo
Nínú ìlànà ètò ìjọba, agbára rẹ̀ kọ̀ jut i ìgbìmọ̀ àwọn ìjòyè ìlú rẹ̀ lọ..
wikipedia
yo
Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ti ṣe àlàyé wípé irú ètò báyìí wà láti ri pé baálé tàbí ọba kò tàpá sí àwọn ìgbìmọ̀ ìjòyè kí gbogbo nǹkan lè máa lọ déédéé ní ìlú..
wikipedia
yo
Irú ètò yìí yàtọ̀ púpọ̀ sí ìlànà ètò ìjọba àwọn ìlú Aláwọ̀-funfun nínú èyí tí àṣẹ láti ṣe òfin wà lọ́wọ́ ilé aṣòfin, tí ètò ìdájọ́ wà lọ́wọ́ ìgbìmọ̀ ìjọba..
wikipedia
yo
Ẹ̀kíkẹ̀nnì kò gbọdọ̀ yọ ẹnu sí iṣẹ́ ekeji, oníkálùkù lọ ní àyè tirẹ̀..
wikipedia
yo
Ni ti ètò Ijọba Yorùbá, Ọba àti àwọn Ìjòyè nfi àga gbà'ga ni ninú eyi ti ó jọ pé ijà lè ṣẹlẹ̀ laarin wọn bi ọ̀kan bá tayọ diẹ si eyi..
wikipedia
yo
Ohun tí ó mú un yàtọ̀ ni wípé sóun, baba ńlá ìdílé àwọn baálẹ̀, dé sí ibi tí ó di Ògbómọ̀sọ́ lónìí lẹ́hìn tí àwọn mẹ́ta ti ṣáájú rẹ̀ dé ibẹ̀..
wikipedia
yo
Nípa ákíkan rẹ̀ ló fi gba ipò aṣíwájú lọ́wọ́ àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yókù..
wikipedia
yo
Akedè sì di ẹ̀gbọ́n láti ìgbà yí lọ títí di òní, àwọn baálẹ̀ tí a ti jẹ ní Ògbómọ̀sọ́ kò jẹ́ kí àwọn ìdílé ẹni mẹ́ta tí ó ṣáájú sóun dé ìlú jẹ́ oyè pàtàkì kan..
wikipedia
yo
Ẹ̀rù mbá wọn pé ìkan nínú àwọn ọmọ ẹni mẹ́ta yìí lè sọ wípé òun ní ẹ̀tọ́ láti ṣe olórí ìlú..
wikipedia
yo
Nitorina ni o fi jẹ pe awọn ijoye ilu ti o mba Baale dámọ̀ràn laarin awọn ẹni ti o de si ilu lẹhin sọ́hùn ni a ti yan wọn..
wikipedia
yo
Sibẹ náà, baálé kan kò gbọdọ̀ tàpá sí ìmọ̀ràn àwọn ìjòyè ìlú, pàápàá ninu àwọn ọ̀rọ̀ tí ó jẹ mọ́ ìṣẹ̀dálẹ̀..
wikipedia
yo
Eyi ṣe pataki ju ni nǹkan ọgọrun ọdun si akoko ti a nsọ nipa rẹ yìí..
wikipedia
yo
Àwọn òpìtàn ìlú Ògbómọ̀sọ́ sọ pé gbogbo àwọn baálẹ̀ tí wọ́n tàpá sí ìmọ̀ràn ìjòyè ìlú ni aláàfin rọ̀ lóyè..
wikipedia
yo
Abẹ́ Aláàfin ni Ògbómọ̀sọ́ wà ní ìgbà náà....olùdáre Ọlájubù Ìwé Àṣà Ìbílẹ̀ Yorùbá, ojú-ìwé 1–11, Ikeja; Longman Nigeria Limited, 1975.Babátúndé Agírí..
wikipedia
yo
Eto iṣelu ni Ògbómọ̀sọ́ ni iwọn ọgọrun ọdun sẹhin; oju-iwe 97-104.àwọn itọkasi awọn ilu ati abule ni Naijiria..
wikipedia
yo
Ìlú ọmú-ó- Èkìtì jẹ́ ìlú nlá kan tí ó wà ní apá ìlà Oòrùn Èkìtì ní Olùó Òkè wà..
wikipedia
yo
Ijoba ibile ila oorun ni ipinle Ekiti ni ọmúo-oke tedo si..
wikipedia
yo
ọmuo-oke to kilomita méjìlélẹ́ẹ̀gbẹ́ si Adó-Ekiti ti o je olu-ilu ipinle Ekiti..
wikipedia
yo
Ọmúọ-òkè ní ìpínlẹ̀ Èkìtì parí sí kí a tó máa- lọ sí ìpínlẹ̀ kogi..
wikipedia
yo
Ìdí nìyí tí ó fi bá àwọn ìlú bí i, Yagba, ijùmú, ìyàmòye pààlà..
wikipedia
yo
Bákan náà ni ó tún bá ẹ̀rítí àkókò pààlà ní ìpínlẹ̀ Òndó..
wikipedia
yo
Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ ọwọ́ ni wí pé, ọmú òkè ni wọ́n ti máa ń kó ẹrù lọ sí òkè ọ̀yà..
wikipedia
yo
Ẹ̀ka èdè ọ̀muó-òkè yàtọ̀ sí ọmúó kọ́ta ọmúọ ọbadoore..
wikipedia
yo
ọmú-ó-òkè Èkìtì Oòó kọ́ta Ọ̀wúwo ọbadèdè Ọ̀wúwo-ó farapẹ́ èdè Kabba, ìgbàgún àti Yagun ní ìpínlẹ̀ kogi..
wikipedia
yo
Ó ṣe é ṣe kí èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí ọmú-ó lọ bá ìpínlẹ̀ kogi pààlà..
wikipedia
yo
Bákan náà ni àwọn ènìyàn Oòo-òkè máa ń sọ olórí ẹ̀ka èdè Yorùbá àti èdè Gẹ̀ẹ́sì ni pàápàá àwọn tó mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́ká.Ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ rẹ̀ìtàn àgbọ́sọ ni ó rọ̀ mọ́ ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ìlú ọmúó-òkè gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí ní àwọn ilẹ̀ Yorùbá káàkiri..
wikipedia
yo
Ilé-Ifẹ̀ ni orírun gbogbo ilẹ̀ Yorùbá bẹ́ẹ̀ ló ṣe rí ni Olùo-Òkè..
wikipedia
yo
Olúmọya pinnu láti sá kúrò ní ìfẹ́ nítorí kò faramọ́ ìyá tí wọ́n fi ń jẹ ẹ́ ní ìfẹ́..
wikipedia
yo
Kí ó tó kúrò ní Ilé-Ifẹ̀, ó lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ Ifá..
wikipedia
yo
Àyẹ̀wò tí ó lọ ṣe yìí fihàn wí pé yóò rí àwọn àmì mẹ́ta pàtàkì kan ní ibi tí ó máa tẹ̀dó sí..
wikipedia
yo
Ibi tí ó ti rí àwọn àmì mẹta yìí ni kí ó tẹ̀dó sibẹ..
wikipedia
yo