cleaned_text
stringlengths
6
2.09k
source
stringclasses
2 values
language
stringclasses
1 value
Ọ̀rọ̀ wá dàbíi “Ẹni tí ófi àdá pa ikùn, ikùn sálọ àdá tún sọnù”
wikipedia
yo
Kí n tó fi gẹ̀gẹ̀Ẹ̀mí sílẹ̀, gbogbo wa lamọ̀ wí pé ní àìsí ìkọ́ni kòleè sí ìmọ̀, ní àìsí ìmọ̀ láti ìran kan dé òmíràn; kò leè sí ìdàgbà sókè, ní àìsí ìdàgbà sókè ẹ̀wẹ̀, kò leè sí ìlọsíwájú, ìlú tí kò bá sì ní ìlọsíwájú ti ṣetán láti parun ni..
wikipedia
yo
Fún ìdí èyí a óo rí pèé ìkọ́ni jẹ́ ohun kan gbógì tí a kò leè fi ṣeré ní àwùjọó wa..
wikipedia
yo
Ẹ̀kọ́ dára púpọ̀ ẹ̀kọ́ lóni ayé táawà yí ṣe ẹ̀kọ́ lóhùn gbéni dépò gíga ẹ̀kọ́ lohun gbéni dépò ọláẹ̀kọ́ dára púpọ̀ ẹ̀kọ́ lóni ayé tí àwa yí ṣe..
wikipedia
yo
Oníbọnòjé – ‘Ìwé ìkọ́ni Yorùbá III.White Shear - ’ Teaching Sast
wikipedia
yo
Àkàndé Saheed ADEFIOrílẹ̀-èdè YorùbáYorùbá Gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè jẹ́ àti-ìran-díran Odùduà pẹ̀lú gbogbo àwọn tí wọ́n ń sin Ọlọ́run ní ọ̀nà tí Odùduà ń gbà sìn-ín; tí wọ́n sì bá a jáde kúrò ní àgbédẹ̀gbẹ́de ìwọ̀ oòrùn nígbà tí ìrúkèrúdò dé nípa ìgbàgbọ́ rẹ yìí..
wikipedia
yo
Akíkanjú yìí pinnu láti lọ tẹ orílẹ̀ èdè míràn dó níbi tí wọn yóò gbé ní àǹfàní àti sin Ọlọ́run ní ọ̀nà tí wọ́n gbà pé ó tọ́ tí ó sì yè..
wikipedia
yo
Bí wọ́n ti ń rìn káàkiri ní Yorùbá, bí orílẹ̀-èdè ń gbòòrò síi, tí ó sì fi jẹ́ pé l'ónìí gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n ń bá ní gbogbo ibi tí wọ́n ti ń jagun tí ó di tí wọn àti ibi tí wọ́n gbé ṣe àtìpó, tí wọ́n sì gbe gba àṣà, àti ìṣe wọn, títí tí ọkùnrin akíkanjú, akọni, olùfọkànsìn, olóògùn, àkàndá ẹ̀dá, yìí fi fi Ilé-Ifẹ̀ ṣe ibùjókòó àti àmù Yorùbá..
wikipedia
yo
Ile-Ife yii si ni awon Yoruba ti fọ́nká kiri si ibi ti won gbe wa l'onìí ti a n pe ni 'Ile K'áàkun, o ji i rewádìí
wikipedia
yo
l'onìí, kì í ṣe ibi tí a pè ní 'Ilẹ̀ K'áàkun, o jí i re' yìí nìkan ni àwọn Yorùbá wà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà kan..
wikipedia
yo
Wọ́n fọ́n yíká ilẹ̀ ènìyàn dúdú ni, àti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn l'abẹ́run ayé..
wikipedia
yo
Gẹ́gẹ́ bí òwe tí ó wí pé ‘Ojú ni a ti ń mọ dídùn ọbẹ̀..
wikipedia
yo
Orílẹ̀ èdè Benin, Togo, Gánà àti Saró àwọn ni Ègùn ilẹ̀ Kútọnu, Ègùn Ìbàrìbá Ilé Benin; Àìná, first ati gàá ní ilẹ̀ Togo ati Gánà; ati àwọn kiriyó (Creoles) ilẹ̀ Saró (Sierra Leone)..
wikipedia
yo
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Odùdù tàn kálẹ̀ bíi èèrùn l'óde òní, ẹ̀rí wà pé orílẹ̀ èdè kan ni wọ́n, ati pé èdè kan náà ni wọ́n ń sọ níbikíbi tí wọ́n lè wà..
wikipedia
yo
Ahọ́n wọn lè lọ tàbí kí ó yí padà nínú ìṣòro síi wọn, ṣùgbọ́n ìṣesí, ìhùwà, àṣà àti ẹ̀sìn wọn kò yàtọ̀; gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa sì ti máa ń pa á l'òwe, a mọ̀ á sí gbà pé; Bí ẹ̀rù bá jọ ẹrú, ilẹ̀ kan náà ni wọ́n ti wátàbí
wikipedia
yo
(b)Ibikíbi tí àwọn akọni yìí bá sì ṣe àtìpó sí tàbí tẹ̀dó sí ni wọ́n ti ń bá ènìyàn..
wikipedia
yo
Òtítọ́ ni wọ́n gba orí l’ọ́wọ́ àwọn tí wọ́n ń bá tí wọ́n sì ń di ‘Akedè gba ẹ̀gbọ́n’, ṣùgbọ́n bí wọ́n bá ti ń di onílé ní ibi tí wọ́n tẹ̀dó, tàbí tí wọ́n ṣe àtìpó sí yìí, ni wọ́n mú díẹ̀-díẹ̀ lọ nínú èdè, àti àṣà wọn nítorí pé bí ewé bá pẹ́ lára ọ̀sẹ̀ bí kò tilẹ̀ di òṣé yóò dà bí ọsẹ; àti pé tí ó bá pe tí Ìjẹ̀ṣà bá ti jẹ iyán, kì í mọ òkèlè ẹ̀ bú mọ́; òkèlè tí ó yẹ kí ó máa bu ńláǹlà yóò di ródóródó..
wikipedia
yo
Eyi ni o si n fa iyatọ diẹ-diẹ ninu ìṣesí àwọn Yorùbá nibi ti wọn ba wa l'onìí.(d)bi àwọn ọmọ Yorùbá ti ṣe n rin jìnnà si, si Ile-Ife ni ahọn àwọn ẹya naa ṣe n yàtọ..
wikipedia
yo
Àwọn tó gba ọ̀nà òkun ló ń fo èdè Yorùbá tí ò lámì, tí a sì ń dàpè ní Ànàgó, àwọn tí wọ́n sì gba ọnà igbó àti ọ̀dàn ló ń sọ ògidì Yorùbá, irú wọn ni a sì ń pè ní ará òkè..
wikipedia
yo
Àwọn tí ó sì gba ẹsẹ̀ odò lọ ní ẹ̀gbà; Ẹ̀gbádò; Ìjẹ̀bú; Ìlàjẹ; Ìkálẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ...
wikipedia
yo
Rògbòdìyàn kò yé ṣẹlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni làásìgbò kò roko ìgbàgbé..
wikipedia
yo
Gbọ́nmisi, omi ò to ko ye waye láàárín ìlú si ilu, Anapa si Anapa..
wikipedia
yo
Tí a bá fi ojú sùnsùn wo Ogun Àgbáyé Kìíní, a óò ri wí pé gbogbo rògbòdìyàn, àjàkú akátá tó wáyé, kò ṣẹ̀yìn ìwà ìgbéraga, owú jíjẹ, èmi ni mo jùọ́ lọ, ìwọ lo jùmí lọ láàárín àwọn ọmọ adaríwúrun..
wikipedia
yo
Awon agba si bo won ni "aifàgbà fẹnìkan ni ko je káyé o gun"
wikipedia
yo
Nígbà tí ẹnìkan bá rò pé òun ló mọ nǹkan ṣe jù, èrò tòun ló tọ̀nà jù, kò sí ẹni tó gbọdọ̀ ta ko ohun tí òun bá sọ..
wikipedia
yo
Àwọn nǹkan wọ̀nyí tó máa ń bí ogún, nígbà tí èlómira bá ta ko irúfẹ́ èèyàn bẹ́ẹ̀ tàbí kí ó jẹ gàba lé òun lórí..
wikipedia
yo
Bí ogun ṣe máa ń ṣẹlẹ̀ láàárín ìlú sí ìlú ló máa ń ṣẹlẹ̀ láàárín orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè..
wikipedia
yo
Ara àwọn nǹkan tí ó sọkún fá ogun àgbáyé àkọ́kọ́ nìyí..
wikipedia
yo
Ogun Àgbáyé àkọ́kọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ láàárín orílẹ̀-èdè méjì kan tí orúkọ wọn ń jẹ́ Austria-Hungary àti Serbia..
wikipedia
yo
Ìlú kékeré kan ni àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì yìí ń jà lé lórí..
wikipedia
yo
Orílẹ̀-èdè àkọ́kọ́ ló kọ́kọ́ gba ìlú yìí lọ́wọ́ èkejì nínú ogun kan tó wáyé ní ọdún 1908..
wikipedia
yo
Orílẹ̀-èdè kejì wa ń dún kókó làjà láti gba itú yìí padà..
wikipedia
yo
Ṣáájú àsìkò yìí, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣẹlẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ sí mú kí àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé máa ṣe gbùn-ún gbùn-ún gbùn-ún sí ara wọn..
wikipedia
yo
Ṣáájú Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn orílẹ̀-èdè ló máa ń jẹ gàba lórí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn nígbà máa, kò pé kò jìnnà ti àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ní mú sìn yìí bẹ̀rẹ̀ ń jà fún òmìnira..
wikipedia
yo
Orílẹ̀-èdè [Belgium] gba òmìnira ní ọdún 1830, nígbà tí ilẹ̀ [Germany] gba tiwọn ní 1871..
wikipedia
yo
Ìjà òmìnira wa bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè lgbọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jà fún òmìnira..
wikipedia
yo
Àwọn orílẹ̀-èdè amúnisìn kọ́kọ́ tako èyí, síbẹ̀síbẹ̀, wọn kò rí nǹkan ṣe sí èyí..
wikipedia
yo
Gbogbo àwọn tí wọ́n tí wọ́n ti jẹ gàba lé lórí bẹ̀rẹ̀ sí jà fún òmìnira..
wikipedia
yo
Bí wọ́n ṣe ń ṣe èyí ni ọ̀rọ̀ elẹ́yàmẹyà bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀, àti àwọn ìṣòro tí ó rọ̀ mọ́ ẹlẹ́yàmẹ́yà..
wikipedia
yo
Àwọn nǹkan wọ̀nyí ló ṣokùnfà rògbòdìyàn ogun nígbà náà yàtọ̀ sí èyí, wíwá àwọn Òyìnbó sí ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú [Africa] wà lára àwọn nńkan tó ṣokùnfà Ogun Àgbáyé Kìíní..
wikipedia
yo
Owó ló gbé àwọn òyìnbó dé ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, wọ́n wá ri pé yio rọrùn fún àwọn lati ri nǹkan àlùmọ́ọ́nì ti wọn n fẹ́ ti àwọn bá mú ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú sìn..
wikipedia
yo
Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn òyìnbó wọ̀nyí dé ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, ìjọ bẹ̀rẹ̀ sí wáyé láàárín wọn lórí orílẹ̀-èdè tí oníkálukú wọn yíò mú sìn..
wikipedia
yo
Nígbà tí wọ́n ń pín ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú láàárín ara wọn, bí wọ́n ṣe pín kó tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè amúnisìn kan lọ́run lórí bí wọ́n ṣe pín àwọn orílẹ̀-èdè aláwọ̀ dúdú láàárín ara wọn nígbà náà àyọrísí gbogbo wàhálà yìí ló ṣokùnfà ogun àgbáyé àkọ́kọ́..
wikipedia
yo
Àwọn orílẹ̀-èdè alágbára wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ sí fura sí ara wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní kó nǹkan ìjà olóró jọ..
wikipedia
yo
Àwọn orílẹ̀-èdè kan bẹ̀rẹ̀ sí ní bá ara wọn ṣọ̀rẹ́ láti gbógun ti orílẹ̀-èdè mìíràn..
wikipedia
yo
Nígbà tí ogun yìí yóò fi bẹ̀rẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè alágbára pín ara wọn sí ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀..
wikipedia
yo
Orílẹ̀-èdè [Germany], [Austria-Hungary] ati [Italy] wà ní ẹgbẹ kan, nígbà tí orile-ede [Britain], [France] ati [Russia] wà ninu ẹgbẹ keji, ní ọjọ́ kejidinlogun oṣù kẹfà ọdún 1914 [18/6/1914] ni okunrin kan tó ń jẹ́ Gaàmì Princip tí ó jẹ́ ọmọ Ilẹ̀ Serbia ṣekú pa ọmọ ọba orílẹ̀-èdè lọ́rùnria-Hungary tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Francis Ferdinand Ẹni tó yẹ kó di ọba ní orílẹ̀-èdè náà..
wikipedia
yo
Èyí kò ṣẹ̀yìn ìgbìyànjú Serbia láti gba àwọn ẹ̀yà ti Austria-Hungary ti kó sínú ìgbèkùn nínú ogun tí wọ́n ti jà tẹ́lẹ̀..
wikipedia
yo
Ikú ọmọ ọba yìí ló ṣokùnfà ogun àgbáyé nígbà tí orílẹ̀-èdè tèmilé-Hungary gbaná jẹ..
wikipedia
yo
Bí wọ́n ṣe ń ṣe èyí ní ilẹ̀ Russia tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ ilẹ̀ Serbia kéde pé àwọn yíò gbógun ti ilẹ̀ Austria-Hungary..
wikipedia
yo
Àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé gbìyànjú láti pẹ̀tù sí wàhálà yìí..
wikipedia
yo
Ilẹ̀ Austria-Hungary fún ilẹ̀ Serbia ni àwọn nǹkan tó lè mú ogun yìí wọlé, ṣùgbọ́n ilẹ̀ Serbia kò tẹ̀lé àwọn nǹkan wọ̀nyí..
wikipedia
yo
Látàrí èyí, ilẹ̀ Austria-Hungary kéde ogun lé Serbia lórí ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹjọ ọdún 1914 [28/8/1914]
wikipedia
yo
Bí ilẹ̀ Austria-Hungary ṣe ṣe èyí tán ní orílẹ̀-èdè Russia náà kéde ogun lé ilẹ̀ Austria-Hungary lórí..
wikipedia
yo
Bí ilẹ̀ Russia ṣe ṣe èyí tán ní ilẹ̀ Germany Kitoki fúnwọn pé tí wọ́n bá dánwò, àwọn yíò gbógun tiwọn..
wikipedia
yo
Nígbà tí ilẹ̀ Austria-Hungary ríbi tí ọ̀rọ̀ yìí ń tó, wọ́n tẹsẹ̀ dúró fún ìjíròrò pẹ̀lú ilẹ̀ Russia..
wikipedia
yo
Ilẹ̀ Germany pàṣẹ láti tu àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ti kójọ tẹ́lẹ̀ kò fún ogun yìí ká..
wikipedia
yo
Ilẹ̀ Russia kọ etí ikún sí àṣẹ ti ilẹ̀ Germany lórí àṣẹ yìí..
wikipedia
yo
Èyí ló mú kí ilẹ̀ Germany kéde ogun lé ilẹ̀ Russia lórí ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹjọ ọdún 1914 [1/8/1914..
wikipedia
yo
ní ọjọ́ kejì sí èyí ní ilẹ̀ ní ilé France náà kéde ogun lé ilẹ̀ Germany náà lórí..
wikipedia
yo
ní ọjọ́ kẹta ní ilẹ̀ Germany kede ogún lé ilé France lórí padà..
wikipedia
yo
Ṣáájú kí ogun tó bẹ̀rẹ̀, ilẹ̀ Belgium ti kọ̀wé ranṣẹ sí àwọn orílẹ̀-èdè tó kù pé tí ogun bá bẹ̀rẹ̀, àwọn kò ní lọ́wọ́ síi..
wikipedia
yo
Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí sì fọwọ́ sí ìwé tí ilẹ̀ Belgium kọ síwọn..
wikipedia
yo
Ṣugbọn nígbà tí ogun bẹ̀rẹ̀, ilẹ̀ Germany pinu lati gba ilẹ̀ Belgium kọjá láti kọ lu ilé France..
wikipedia
yo
Ṣùgbọ́n ilẹ̀ Belgium kọ̀ jálẹ̀ pé àwọn ti pinu pé àwọn kò ni da si ìjà..
wikipedia
yo
Eyi mu ki ilẹ̀ Germany binú, wọ́n si pinu lati gbógun ti ilẹ̀ Belgium..
wikipedia
yo
Ìpín ilẹ̀ Germany yìí mú kí ilẹ̀ Britain dá sí oró yìí, wọ́n kìlọ̀ fún ilẹ̀ Germany láti ro ìpín àti gbógun ti ilẹ̀ Belgium ní ẹ̀ẹ̀mejì nítorí pé gbogbo àwọn ni àwọn fi owó sí pé ilẹ̀ Belgium kò ní lọ́wọ́ sí ogun yìí nítorí náà, kí wọ́n má ṣe gbógun ti ilẹ̀ Belgium..
wikipedia
yo
Ilẹ̀ Germany kò jalè lati gba oró yìí yẹ̀wò, èyí si mú kí orílẹ̀-èdè Britan kede ogun lé ilẹ̀ Germany lórí ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹjọ ọdún 1914 [4/8/1914]
wikipedia
yo
Ilẹ̀ Turkey náà dá sí ogun yìí ní oṣù kẹwàá ọdún 1914..
wikipedia
yo
Nígbà tí ilé France náà dá sí ní oṣù Kọkànlá ọdún 1914..
wikipedia
yo
Báyìí ni ogún yìí di ogún agbéyé, tí ó di ìjà Ajáràn..
wikipedia
yo
Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn orílẹ̀-èdè alágbára wọ̀nyí ń ṣe àkóso lé lórí tí wọ́n ń mú sìn pàápàá jùlọ ní ilẹ̀ adúláwọ̀ [Africa] àti ilẹ̀ Lárúbáwá ni gbogbo wọn náà múra láti gbè sẹ́yìn àwọn ọ̀gá wọn láti bá àwọn orílẹ̀-èdè yòókù jà tí èyí sì di iṣu atayàn-an yán-án káàkiri orílẹ̀-èdè àgbáyé..
wikipedia
yo
Ní oṣù kẹrin ọdún 1917 ni ilẹ̀ America náà kéde ogún lé ilẹ̀ Germany lórí látàrí bí wọ́n ṣe kọlu àwọn ará ilẹ̀ America nínú ọkọ̀ ojú-òní tí èyí sì tako ìlànà ogun jíjà..
wikipedia
yo
Òfin sì wà wí pé tí orílẹ̀-èdè meji bá ń jà, àwọn ọmọ ogun ara wọn nìkan ni wọ́n dojú ìjà kọ..
wikipedia
yo
Èyí sì bí ilẹ̀ America nínú, ìdí nìyí tí wọ́n fi dá’ sí Ogun Àgbáyé ní ọdún 1917..
wikipedia
yo
Ogun Àgbáyé tó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù keje ọdún 1914 [28/7/1914 parí ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kọkànlá ọdún 1918[11/11/1918/1918 lẹ́yìn ọdún mẹ́rin, oṣù mẹ́ta àti ọjọ́ mẹ́rìnlá tí ogun ti bẹ̀rẹ̀..
wikipedia
yo
Owó tí àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé ná sí ogún yìí tó ọgọ́rùn-ún méjì bílọ́ọ̀nù dọ́là [two hundred Billons Dollas] owó ilẹ̀ America láyé ìgbà náà tí owó níyì..
wikipedia
yo
Bí i ogójì mílíọ̀nù [Fourty millions] ọmọ ogun orílẹ̀-èdè àgbáyé ló bá ogun yìí lọ kí á ṣẹ̀ṣẹ̀ má sọ ti àwọn ogun ojú-òun bí i mílíọ̀nù mẹ́wàá [ten millions] tí ó ará ìlú ta kìí ṣe sójà ló ṣòfò nínú ogun àgbẹnu yìí..
wikipedia
yo
Síbẹ̀síbẹ̀, wàhálà tó ṣokùnfà ogun àgbáyé àkọ́kọ́ tí àwọn èèyàn rò pé yíò yanjú tàbí níyànjú..
wikipedia
yo
Wàhálà yìí ló tún ṣokùnfà Ogun Àgbáyé Kejì àti àwọn ogun tó tún wáyé lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní..
wikipedia
yo
Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní “Ẹni tí ogun bá pa kú ní ń ròyìn ogun”
wikipedia
yo
Yorùbá tún bọ̀ wọ́n ní "Ẹni tí Ṣàngó bá tọ́jú rẹ̀ jà rí kò ní báwọn bú Olúkókósọ́tọ̀..
wikipedia
yo
Ẹni tí ogun bá jà lójú rẹ̀ rí, kò ní bẹ Ọlọ́run kí ogun tún wáyé ní ojú òun..
wikipedia
yo
ìyísódì nínú ẹ̀ka-èdè Ìkálẹ̀ÌfáàràGẹ́gẹ́ bi ìyísódì ṣe ń jẹ yọ nínú ya, Ìkálẹ̀, tíí ṣe ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá, máa ń ṣe àmúlò oríṣiríṣi wúnrẹ̀n láti fi ìyísódì hàn..
wikipedia
yo
ìyísódì lè jẹ yọ nínú ẹyọ ọ̀rọ̀ kan, ó sì tún lè jẹ yọ nínú ìhun gbólóhùn kan..
wikipedia
yo
Àwọn ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ kan wà tó jẹ́ wí pé wọ́n ní ìtumọ̀ ìyísódì nínú..
wikipedia
yo
Àwọn yìí ni ọ̀rọ̀ tí a ṣẹ̀dà tí wọ́n sì ń fún wa ní oyè ìyísódì..
wikipedia
yo
A pe àwọn ọ̀rọ̀ yìí ní ọ̀rọ̀ aṣẹ̀dá, nítorí pé wọn kì í ṣe ọ̀rọ̀ oní-mófíìmù kan..
wikipedia
yo
tí a bá fẹ́ ṣẹ̀dá àwọn ọ̀rọ̀ yìí, a máa ń lọ mófíìmù ìṣẹ̀dá mọ ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀, èyí tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀-iṣẹ́ ló máa ń jẹ́; àkànpọ̀ àwọn mejeeji máa ń yọrí sí ọ̀rọ̀-orúkọ..
wikipedia
yo
Ọ̀nà tí à ń gbà ṣe èyí ni pé a ó fi ẹ̀rún ni sí ẹ̀yìn fọ́nrán ìhun náà tí a fẹ́ pe àkíyèsí sí..
wikipedia
yo
Àwọn fọ́nrán ìhun tí a lè pe àkíyèsí sí yìí ni a lè yí sódì..
wikipedia
yo
ìyísódì Olúwa ò ṣe jẹ́ wí pé a lè pe àkíyèsí alátẹnumọ́ sí olùwà nínú gbólóhùn, bẹ́ẹ̀ náà ni a lè ṣe ìyísódì fún un..
wikipedia
yo
ÈÉ ṢE NI wúnrẹ̀n ti éí maa n lo fún ìyísódì sí nínu gbólóhùn àakiyesi alatẹnumọ́..
wikipedia
yo
Ṣùgbọ́n nínú yá, ọ̀nà méjì ni a lè gbà ṣe ìyísódì fọ́nrán ìhun tí a pe àkíyèsí sí..
wikipedia
yo
tí a bá sì ti ṣe ìyísódì fọ́nrán ìhun tí a pe àkíyèsí sí, atọ́ka àkíyèsí àlàtẹnumọ́ náà kì í jẹ́ yó mọ́.ìyísódì àbọ̀pípé àkíyèsí àlàtẹnumọ́ sí abo nínú gbólóhùn fara jọ ìgbésẹ̀ ti olúwa..
wikipedia
yo
Ìyàtọ̀ tó kàn wà níbẹ̀ ni pé tí a bá ti gbé àbọ̀ síwájú, ààyè rẹ̀ yóò ṣófo.Tí a bá fẹ́ ṣe ìyísódì àbọ̀ inú gbólóhùn, ẹ̀ẹ́ ṣe náà ní wúnrẹ̀n tí éí máa ń lò..
wikipedia
yo
Bí a ṣe ń ṣe èyí ni pé a ó ṣe àpètúnpè kọ́ńsónáǹtì àkọ́kọ́ tí ọ̀rọ̀-iṣẹ́ náà kí a tó wá fi fáwẹ́lì /i/i olóhùn òkè sí àárín kọ́ńsónáǹtì méjèèjì..
wikipedia
yo
Ìgbésẹ̀ kan wà tí a máa ń ṣe fún èyàn tí a pe àkíyèsí ìṣètẹnumọ́ sí nígbà tí a bá fẹ́ ṣe ìyísódì rẹ̀..
wikipedia
yo
A lè yìí Sodi nínú àpólà-orúkọ tí ó ń yàn, a sì tún lé yìí Sodí láìba àpólà-orúkọ tó ń yan rin..
wikipedia
yo
Tí èyí bá máa wáyé, a gbọ́dọ̀ sọ èyàn náa di àwẹ̀-gbólóhùn ohunpo, kí a tó yìí Sodi..
wikipedia
yo