cleaned_text
stringlengths
6
2.09k
source
stringclasses
2 values
language
stringclasses
1 value
A ka àwọn ìwà tí ọwọ́ wa tẹ̀ ní agbègbè náà, a sì rí ọkọ̀ tó wúlò fún wa lórí orí ọ̀rọ̀ tí ìṣe wa yìí dá lé..
wikipedia
yo
Iṣẹ́ ìwádìí yìí fi hàn pé àkọ́jinlẹ̀ orin nípa ṣíṣe àtúpalẹ̀ kókó ohun tí à ń lo orin fún pọn dandan kí a tó lè ní òye iṣẹ́ ọ̀nà àti ìtumọ̀ orin ní àpapọ̀..
wikipedia
yo
Iṣẹ́ yìí tún jẹ́ kí n ní ìmọ̀ nípa ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀, ẹ̀sìn ati ètò ìṣèlú àwọn ará Àkúrẹ́..
wikipedia
yo
Iṣẹ yìí tún fi hàn pé ẹ̀sìn ni ó máa ń bi àwọn orin ẹ̀sìn ní àwùjọ Àkúrẹ́ ati pé aṣa ati ìṣe àwùjọ ni ó maa n ṣe okùnfà fún àwọn orin aláijómẹ́sìn..
wikipedia
yo
Èétàgún tí n ó sọ nípa bí eégún ṣe délé ayé yìí, mo gbọ́ ọ láti ẹnu baba bàbáa mi ni kí ó tó di pé wọ́n jẹ́ ìpè Olódùmarà ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá sẹ́hìn..
wikipedia
yo
Ìdí pàtàkì tí ó jẹ́ kí n fi ara mọ́ ìtàn náà ni pé ó fi ara jọ ìtàn tí mo kà lórí nǹkan kan náà ìwé ọ̀mọ̀wé J.A..
wikipedia
yo
Ìdí mìíràn tí ó jẹ́ kí n fi ara mọ́ ìtàn náà yàtọ̀ sí òmíràn nipé ẹ ẹnu àwọn tí mo ṣe ìwádìí lọ́wọ́ wọn kò kọ lórí ọ̀rọ̀ náà..
wikipedia
yo
Ó dà bí ẹni pé olúkálukú ni ó fẹ́ fi bu iyì kún ìlú tirẹ̀ pé ní ìlú tòun ni àwọ̀ ìṣẹ́gun ti bẹ̀rẹ̀..
wikipedia
yo
Ọ̀gbẹ́ni Semeta sasálọla tí ó ń gbé ni ìlú Òndó tilẹ̀ sọ fún mi pé ní ìlú Ọ̀fà ni eégún ti ṣe..
wikipedia
yo
Nígbà tí mo sì fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, mo rí i pé ọmọ ọfà ni baba rẹ..
wikipedia
yo
Ọmọ ìwékọsẹ̀ tún sọ fún mi pé ó dá òun lójú pé ní ìlú Òkè-igbó lẹ́bàá Òǹdó ni eégún ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀.Nínú ìdàrúdàpọ̀ yìí ni mo wá rò ó pé bí ènìyàn bá fẹ́ẹ́ mọ òtítọ́ tí ó wà nídìí ọ̀rọ̀ náà, àfi bí ènìyàn bá tọ Ifá lọ nítorí pé ifá kò ní í gbé sẹ́hìn ẹnikẹ́ni..
wikipedia
yo
Ìdí tí mo sì ṣe fi ara mọ́ ọn náà nipé ẹ ó jọ ìtàn tí mo ti gbọ́ lẹ́nu Bàbá bàbáa mi..
wikipedia
yo
Ìtàn keji yìí nítorí pé ó tún là wá lọ́yẹ̀ lórí bí orúkọ náà, “Eégún”, tí ṣe bẹ̀rẹ̀..
wikipedia
yo
Èyí tí ó wà láàyè wáá sunkún títí, ni wọ́n bá dọ́gbọ́n, wọ́n daṣọ eegun..
wikipedia
yo
Èyí tí ó wà láàyè bẹ̀rẹ̀ síí sunkún, 1.Abimbola Wande, àwọn Odù mẹrẹẹrindim..
wikipedia
yo
Aṣọ tí a dà bo alààyè lórí ni a ń pè ní eku eégún..
wikipedia
yo
Ẹkú ayé o, eku orun, n a n pe ní èjì eku." Ìtàn kẹ̀ jí wa nínú ìwé ọ̀mọ̀wé J.A..
wikipedia
yo
Ìrònú ọ̀ràn náà pọ̀ dé bi pé èyí ákúkú tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún gbogbo wọn fi ìlú sílẹ̀..
wikipedia
yo
Bẹ́ẹ̀ ni èyí àtẹ̀lé rẹ̀, árukú, mú ìmọ̀ràn wá pé kí àwọn ó ta òkú náà1..
wikipedia
yo
Èyí àbúrò wọn, àròkú-rọ̀-jà-ta-tà, bá kiri òkú náà lọ..
wikipedia
yo
Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ti kiri fún ìgbà díẹ̀ tí kò ti rí ẹni ra òkú náà ni ó ti sú u, ó sì wọ́ òkú náà jùnù sínú igbó; ó bá tirẹ̀ lọ..
wikipedia
yo
Lẹhin igbà díẹ̀, eyi ẹ̀gbọ́n di Baálẹ̀ ilé, ó si gba ipò Bàbá rẹ gẹ́gẹ́ bi ológbi..
wikipedia
yo
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé abuké ni, Aláàfin fún un ní ìyàwó kan, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ ìyá Mose..
wikipedia
yo
Ṣùgbọ́n fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, Mósè kò gbọ́ mọ́kọ̀ọ́ 1.Wọn a máa ta òkú láyé àtijọ́ fún àwọn olóògùn tí wọ́n fẹ́ lo ẹ̀yà ara òkú náà..
wikipedia
yo
Nígbà tí ó débá tí ó débẹ̀, ó ní “Èmi ló dé tí ìyàwó òun fi rọ́mọ lẹ́hìn adìẹ tó bú pùrù sẹ́kún?” Ọ̀rúnmìlà sì sọ fún un pé àfi tí ó bá lè ṣe ẹ̀yẹ ìkẹhìn fún bàbá rẹ̀ tí ó ti kú kí ìyàwó rẹ̀ ó tó le bímọ..
wikipedia
yo
Ní àkókò yìí, ìyá Mose ti lọ sọ́dọ̀ Amúṣan láti lọ ṣe ìwádìí ohun tí ó fa sábàbí..
wikipedia
yo
Bí ìyá Mose ti ń bọ̀ láti ọ̀dọ̀ àṣà níjọ́ kan ni Elégbèdè kan jáde sí i láti inú igbó tí ó sì bá a lòpọ̀..
wikipedia
yo
Ó sì fọ́n ọn ò di ọ̀dọ́ ọlọ́pọ́ndá tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ìyá mọ́ṣẹ́..
wikipedia
yo
Nígbà tíítijú pọ̀ fún Mose, ó tún fọ́n ọn, ó di ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀..
wikipedia
yo
Nígbà tí ó dìjọ kéje ní àtọ̀ tí ó jẹ́ ìyàwó àǹgó tí ó jẹ́ ọmọ Ìgbórí rí ìjímèrè igbó..
wikipedia
yo
O ti lọ si ọ̀dọ̀ Ọ̀rúnmìlà, Ifá sì ti sọ fún un pé sùúrù lẹbọ..
wikipedia
yo
Ifá ni ki ológbin máà tọ́jú abàmì ọmọ náà, ṣùgbọ́n ki ó tún ṣe ẹyẹ ìkóhìn fún bàbá rẹ̀ nípa lílọ sí igbó níbi tí wọ́n ti rí abàmì ọmọ náà láti lọ ya eégún bàbá rẹ̀..
wikipedia
yo
Àwọn ohun tí ìfà pa láṣẹ ètùtù náà ni ẹgbẹ̀rin àkàrà, ẹgbẹ̀rin ẹ̀kọ́, ẹgbẹ̀rin pàṣán àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹmu..
wikipedia
yo
Igbó tí wọ́n ti ṣe ètùtù náà ni a mọ̀ sí igbó ìgbàlẹ̀ di òní olónìí..
wikipedia
yo
aláràn-án òfì tí ó jẹ́ ìyekan ọlọ́gbín ni ó gbé aṣọ òdòdó ti baba ológbín tí ó ti kú ń lọ nígbà ayé rẹ̀ bora, tí ó sì tún gbẹ abàmì ọmọ náà pọ̀n sẹ́hìn, tí ó sì ń jó bọ̀ wá sí ààrin ìlú láti inú igbó náà pẹlu ìlù ati ọpọlọpọ eniyan lẹhin rẹ̀..
wikipedia
yo
Ọlọgbín ti fi lọ tẹlẹ̀ pé òun yóo ṣe ẹ̀yẹ ikẹhin fún bàbá òun tí ó ti kú nítorí náà nígbà tí wọ́n rí aláràn-án orí ninú aṣọ òdòdó, wọ́n ṣe bí ológbín tí ó ti kú ni, pàápàá ti abàmì ọmọ tí ó pọ́n dà bí ike ẹ̀hìn rẹ̀..
wikipedia
yo
Àwọn ènìyàn ń sún mọ́ ọn láti wò ó dáadáa ṣùgbọ́n pàṣán tí wọ́n fi ń nà wọ́n kò jẹ́ kí wọn sì wọ ilé baba ọlọ́gbín tí ó ti kú lọ..
wikipedia
yo
Ninu kaa yìí ní ògógó ti ó jẹ́ oko Ato, ti n wọ ọmọ náà nígbàkúùgbà..
wikipedia
yo
Àwọn ènìyàn inú ilẹ̀ a sì máa pé ògogó ni ṣàánú-wà..
wikipedia
yo
Jagun-wà yìí ni ó sì di alágbàá (Bàbá màrìwò) títí di òní olónìí..
wikipedia
yo
Òkú tá a gbé rójà tí ó ta; 1.Ìtumọ̀ èyí ni ẹni tí ó gbọ́ tí ó wá..
wikipedia
yo
Òun la tún gbé wálé, tá a daṣọ bò, tá à ń pe léegun.A dífá fún ọ̀wọ̀nrin iṣanyín tó kù tí àwọn ọmọ rẹ̀ kò rówó sin ín.1Bí a bá sì tún wo oríkì eégún, ọ̀rọ̀ nípa bí eégún ṣe kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ yóò túbọ̀ tún yé wá sí i..
wikipedia
yo
Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀, oríkì ni ọ̀rọ̀ tí ó júwe ìwà, ìṣe2 àti ìtàn ìbí àwọn òrìṣà, ènìyàn àti àwọn nǹkan mìíràn..
wikipedia
yo
the study of a Yorùbá theatrical art from its origin to the present times..
wikipedia
yo
ÌGBÀ TÍ Ń KÒ Sọ́ràn ÒKUN,KÍ LÈ FỌ̀RỌ̀ SỌ MÍ Lápá SÍ? ỌMỌ kẹkẹ MO SA, MO MÚ FTER LÀgbú..
wikipedia
yo
Ggon ni mo wà,mo mu ṣẹ̀we nígbórí ‘Torí Ìgbórí mi lóyó mokó..
wikipedia
yo
Òkú tá a gbé rójà tá ò ta, òun lá dáṣọ fún tá à ń pe léegun..
wikipedia
yo
Baba àtọ̀ kékeré a-bẹnu wéwẹ̀jẹ́.2 Báyìí a ti mọ bí eégún ṣe kọ́kọ́ dé inú ayé nígbà ìwáṣẹ̀..
wikipedia
yo
The alárìnjó Theatre; (the study of a Yoruba theatrical art from its origin to the present times.) Ph.D..
wikipedia
yo
Ṣugbọn láyé òde òní ń kọ́? Báwo ni a ṣe ń ‘ṣe’ eégún? Ó ṣòroó sọ pàtó pé kò níí sí ìyàtọ̀ díẹ̀ láti ìlú dé ìlú lórí ọ̀rọ̀ bí a ṣe ń ‘ṣe’ eégún..
wikipedia
yo
obìn in a sì máa mọ́ àwo, ṣùgbọ́n bí wọ́n bá tilẹ̀ mọ̀ ọ́n, wọn kò gbọdọ̀ wí..
wikipedia
yo
Àgbàlagbà ọ̀jẹ̀ nìkan ni wọ́n ń ‘ṣẹ́’ eégún rẹ̀ bí ó bá kú..
wikipedia
yo
Bí a bá ti fẹ́ ‘ṣẹ́’ eégún ẹni tí ó ti kú yìí, a ó wá pàṣán mẹ́ta, a ó wá aṣọ funfun tí ó tóbi, a ó tún wá ẹni tí kò ṣẹ̀ kò yẹ gíga ẹni tí a fẹ́ ’ṣẹ́’ eégún rẹ̀ náà..
wikipedia
yo
Ìtàn sọ fún mi pé láyé àtijọ́, tí wọ́n bá pe òkú ọ̀jẹ̀ nígbà tí wọn kò bá tíì sin ín, pé ó máa ń dáhùn tí yóo sì bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀..
wikipedia
yo
Ṣugbọn èké ti dáyé, afihàn ti dàpọ̀, nǹkan ò rí bí i ti í rí mọ́ nítorí pé a kò le ṣe é bí a ti í ṣe é tẹ́lẹ̀..
wikipedia
yo
Bí àwọn èròjà tí a kà sílẹ̀ wọ̀nyí bá ti dé ọwọ́ àwọn àgbà ọ̀jẹ̀, a ó mú ọkùnrin tí kò ṣẹ̀ kò yẹ gíga òkú ọ̀jẹ̀ náà lọ sínú igbó ìgbàlẹ̀..
wikipedia
yo
Lẹhin eyi, àwọn ọ̀jẹ̀ yoku àti àwọn ènìyàn yóò máa lu ilú Eégún ni ibi ti wọn ti pa ṣisẹ́ lẹ́bàá igbó ìgbàlẹ̀ náà..
wikipedia
yo
Tí wọ́n bá ti ń lu ìlù báyìí, àgbá òjé kan yóo máa mú ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu pàṣán yẹn, yóo 1.Ọ̀pá àtorí tí a fi irin gbígbóná ṣe ọ̀nà sí lára tí àwọn tí ó máa ń tẹ̀lé eegun lọ sóde fi ń na eniyan..
wikipedia
yo
2.àparun tabi igi tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́, tí a sì ṣe é pẹlẹbẹ pẹlẹbẹ.Sì máa fín a ilé lẹẹmẹta mẹta..
wikipedia
yo
Bí ó bá ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni yóo máa pe orúkọ ẹni tí ó ti kú náà tí a sì fẹ́ ‘Ṣe’ eegun rẹ̀ yìí..
wikipedia
yo
Nígbà tí ó bá ti fi pàṣán kẹta na ilé lẹ́ẹ̀kẹta tí ó sì tún pe orúkọ ẹni tí ó ti kú náà, ẹni tí ó ti wà nínú igbó ìgbàlẹ̀ yóò dáun, yóò sì máa bọ̀ pẹ̀lú aṣọ funfun báláú lórí rẹ̀..
wikipedia
yo
Àwọn eniyan yóo sì máa yọ̀ pé baba àwọn dáhùn, pé kò tilẹ̀ kú rárá..
wikipedia
yo
Bí baba bá ti jáde báyìí ni àwọn eniyan yóo máa bèèrè oríṣìíríṣìí nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀, tí baba náà yóo sì máa dá wọn lóhùn..
wikipedia
yo
Nígbà tí ó bá ti jó dáadáa fún ìgbà díẹ̀, yóò súre fún àwọn ènìyàn kí ó tó padà bá inú igbó ìgbàlẹ̀ lọ..
wikipedia
yo
Eyi jẹ itọkasi kan lati fi han pe lati Oyo ni Eégún ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ki o to tan ká gbogbo ilẹ̀ Yorùbá..
wikipedia
yo
Ni ayé àtijọ́, nígbà ti ogun àti òté pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni ogun kó láti ìlú kan dé òmíràn..
wikipedia
yo
Àwọn mìíràn lè ṣe àtìpó níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ kí wọn ó sì padà sílé nígbà tí wọ́n bá ti ra ara..
wikipedia
yo
Àwọn mìíràn a tilẹ̀ kúkú jókòó sí ìlú náà wọ́n a sì fẹ́ ìyàwó níbẹ̀..
wikipedia
yo
Àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò gbàgbé ẹ̀sìn wọn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń gbé eb.A..
wikipedia
yo
AkinDúró (1977), bí eégún ṣe bèrè', Dall OAU, Ifẹ̀ NigeriaYorùbá..
wikipedia
yo
rárà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ewì àbáláyé ní ilẹ̀ e Yorùbá..
wikipedia
yo
Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe ṣe àlàyé nínú ọ̀rọ̀ àkọ́so, agbègbè Ìbàdàn àti Ọ̀yọ́ ni irú ewì báyìí ti wọ́pọ̀..
wikipedia
yo
Òun ni ọ̀kan nínú àwọn ewì `tí a máa ń fi ń yín ẹnikẹ́ni tí a bá ń sun ún fún yálà ní ìgbà tí ó bá ń ṣe ìnáwó tàbí àríyá kan..
wikipedia
yo
bí ó ti jẹ́ ohun tí a fi ń yin eniyan náà ni ó tún jẹ́ ohun tí a lè fi pe akiyesi eniyan sí ìwà àléébù tí ó ń hù..
wikipedia
yo
Bákan náà, rárá jẹ́ ọ̀nà kan tí a fi máa ń ṣe àpọ́nlé ènìyàn ju bí ó ti yẹ lọ, nígbà tí a bá sọ pé ó ṣe ohun tí ó dà bí ẹni pé ó ju agbára rẹ̀ lọ..
wikipedia
yo
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ ni a máa ń bá pàdé nínú un rárá ó sì dà bí ẹni pé àwọn orúkọ wọ̀nyí jẹ́ orúkọ àwọn ẹni àtijọ́ tí ó jẹ́ bí i baba ńlá ènìyàn tí ó ṣeni sílẹ̀..
wikipedia
yo
nítorí pé ọ̀rọ̀ ìyìn àti ẹ̀pọ́n la máa ń bá pàdé nínú un rárá, èyí máa ń mú inú àwọn ènìyàn tí ó bá ń gbó rárá náà dùn, orí a sì máa wú..
wikipedia
yo
Ní ààrin orí wíwú ati yíya báyìí ni àwọn ènìyàn tí a ń sun rárà fún yíò ti máa fún àwọn àworara náà ní ẹ̀bùn tí wọ́n bá rò pé ó tọ́ sí wọn..
wikipedia
yo
Rárá sísun báyìí pé oríṣi meji tabi mẹta ni agbègbè ibi tí wọ́n ti ń ṣuún..
wikipedia
yo
Ìgbà ti ọmọ-ilé kan ọkùnrin tàbí ọmọ-oṣù, tàbí ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó ilé bá ń ṣe ìnáwó ni wọ́n tóó sùn tì wọ́n..
wikipedia
yo
Oríṣi kejì nit i àwọn ọkùnrin tí ó máa ń lù ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀..
wikipedia
yo
ii.Ìgbà tí a máa ń sún rarajakejado ilẹ̀ e Yorùbá, ó ní ìgbá tí a máa ń sábà ń kéwì..
wikipedia
yo
Gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ àti bí òwe àwọn Yorùbá tí ó sọ wí pé “Ẹ̀ṣẹ̀ kì í ṣe lásán”, bákan náà ni fún rara, a kì í déédé sùn rárá láìjẹ́ pé ó ní nǹkankan pàtàkì tí à ń ṣe.Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i àti bí a ṣe gbọ́ láti ẹnu àwọn àsunrara tí a wádìí lọ́dọ̀ ọ wọn, àwọn àsìkò tí a máa ń sùn rárá jẹ́ àsìkò tí a bá ń ṣe àríyá tàbí àjọyọ̀..
wikipedia
yo
Gẹ́gẹ́ bí àwọn àsùnrara Aláàfin ìlú Ọ̀yọ́ ti wó, ó jẹ́ ìwà àti ìṣe wọn láti máa lò ó sun rárà fún Aláàfin ní anfin rẹ̀..
wikipedia
yo
lẹ́hìn tí ààfin sísun fún yìí, wọ́n a tún máa sùn tẹ̀lé ọba yìí bí ó bá nlọ sí ìdálẹ̀ kan..
wikipedia
yo
wọ́n ń ṣe èyí kí àwọn ẹni tí ọba náà kọjá ní ìlú u wọn lè mọ ẹni tí ń kọjá lọ..
wikipedia
yo
Ni ilu Oyo ati Ibadan, o da bi eni pe a ya ojo kan sọ́tọ̀ fun rara sísun yii..
wikipedia
yo
Ọjọ́ yìí máa ń pẹ́ ní ọjọ́ òṣìṣẹ́dílọ́gbọ̀n sí ara wọn..
wikipedia
yo
Ọjọ́ yìí ni a gbọ́ pé ó ṣe pàtàkì nínú ìkà oṣù àwọn Yorùbá..
wikipedia
yo
Ọjọ́ yìí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé wa sí àárín ìlú láti ọkọ tí wọ́n ń gbé yálà láti wá sọ ìpàdé ẹ̀ mọ̀lẹ́bí tàbí láti wá ṣe ohun pàtàkì míràn..
wikipedia
yo
Ní ọjọ́ yìí, àwọn eniyan máa ń pọ̀ ninu ìlú ju bí ó ṣe máa ń wà tẹ́lẹ̀ lọ..
wikipedia
yo
Ni Ọ̀yọ́ ni ọjọ́ jímọ̀ọ́ olóyín yìí, àwọn àsun náà yíò maa káàkiri ilẹ̀ àwọn Ọ̀yọ́ méṣì àti àwọn ìjòyè ìlú yókù..
wikipedia
yo
Lẹ́hìn tí èyí wọn ó padà sí ààfin láti wá jókòó sí ojú àgànjù..
wikipedia
yo
Níhi ni wọn yíò ti máa sun rárà kí gbogbo àwọn àlejò tí ó bá ń lọ kí Aláàfin..
wikipedia
yo
Wọ́n ń ṣe èyí láti le rí ẹ̀bùn gbà lọ́wọ́ àwọn àlejò náà; àti láti lè jẹ́ kí Aláàfin mọ irú àlejò tí ń bọ̀..
wikipedia
yo
Bákan náà a gbọ́ pé ní ayé àtijọ́ ni ìgbà tí ogun wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá, àwọn jagunjagun máa ń ní àsùnrárà tí í máa sùn rárà tẹ̀ lé wọn bí wọ́n bá nlọ sí ogun1..
wikipedia
yo
Mo rò pé wọ́n ń ṣe èyí láti lè fún àwọn jagunjagun náà ní ìṣírí..
wikipedia
yo
Bákan náà wọn a tún máa sọ fún wọn bí ó ti ṣe yẹ kí wọ́n ṣe lójú ogun..
wikipedia
yo
Lẹ́hìn tí kí a sun rárà fún àwọn ọba, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà tí a tún ń sun rárà jẹ́ àwọn àsìkò ìnáwó tàbí àríyá..
wikipedia
yo
Ni igba ti eniyan ba n se igbeyawo awọn onirara a maa sun rara fun oninawo naa..
wikipedia
yo