cleaned_text
stringlengths
6
2.09k
source
stringclasses
2 values
language
stringclasses
1 value
Àmọ́, ìfẹ́ yí ni Ọbàtálá pàdánù rẹ̀ ṣòwò Odùduwà àtẹ̀wọ̀nrọ, èyí ni ó fàá tí fàá ká jà ṣe wà láàrín àwọn méjèèjì..
wikipedia
yo
Odùduwà ni ó bẹ̀rẹ̀ ìjọba ní Ifẹ̀, ní èyí tí àwọn ọmọ rẹ̀ gbogbo náà sí di adarí àti olórí ìlú ní ẹlẹ́ka-ó-jẹ̀ka ibi tí wọ́n tẹ̀dó sí káàkiri orílẹ̀ Yorùbá lọ́..
wikipedia
yo
Gẹ́gẹ́ bí a ti kàá nínú ìtàn, Ọọ̀ni àkọ́kọ́ tí yóò kọ́kọ́ jẹ́ ni Ifẹ̀ ni ó jẹ́ ọmọ bíbí inú Odùduwà tí ó jẹ́ ọ̀kànlélógójì òrìṣà fúnra rẹ̀, nígbà tí Ọọ̀ni tí ó wà níbẹ̀ lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyí jẹ́ Ọọ̀ni Adéyẹyè Ẹnitàn Ògúnwúsì Oja Kejì(ii) tí wọ́n jẹ́ ní ọdún 2015..
wikipedia
yo
Bákan náà ni Ile-Ife ní ọ̀kanlélúgba òrìṣà tí wọ́n ma ń bọ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan yípo ọdún..
wikipedia
yo
Ilé-Ifẹ̀ ìlú ńlá tí òkìkí rẹ̀ kàn jákè-jádò àgbáyé fún àwọn iṣẹ́ ọnà wọn bíi eré orí Odùduwà àti àwọn ohun ọnà míràn tí wọ́n lààmì-laaka ní nkan bí ọdún 1200 àti 1400 A.D sẹ́yìn.Orin ìwúrí ẹ̀-Ifẹ̀ Ilé Ifẹ̀, ìfẹ́ẹ̀ Tèmi Ilé Ifẹ̀, ìlú àwọn akọni ibùgbé àwọn ènìyàn Jankande Ibi Ìsọsọ oríi Yoòbá Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, Bí mo purọ́, ẹ sọ ibẹ̀ nílẹ̀ Àdìyé Ọọ̀ni Ifẹ̀laye Ọlọ́fin Oẹ̀rẹ̀ Ọba alayé lu jára on tíí gba àdúgbò ẹ̀là Ìwọ rí, Ikọ́ ajá lọ́run 10 Òrìṣà Balta Balta a fi rọ̀mọ́ ẹ̀dá ẹ̀dá padà Ifẹ̀, Ìlú àwọn oluda ayé Ifẹ̀, Ìlú àwọn àtọ̀runbọ Ifẹ̀ ni wọ́n gbé gbogun bí dúdú, funfun ìyìn lèèyàn pàápàá forí rìn rìn dé 15 Ìwọ Ifẹ̀ Okà Òpin dàbọ̀, Olórí gbogbo mo rántí bíyàá mi àgbà àgbà ṣe-ọn ń fi ó kọrin Odò ẹ̀sìn ẹ̀sìnn kò rí ọ rí ká sọ pàtó mọ́ riya tó ó jẹ́ lóríi wa 20 20 mi kò sa ìtẹ́ rèéjẹ́ tó o ta sílẹ̀ fún wa tó tọwọ́ ìyá ìyá wa ìyà tó tọwọ́ iṣẹ́ wa tó tọwọ́ ẹ̀gbìn lẹ́ó 25 Nígbà tọ́mọ tá a bí Dewáá fọwọ́ ọ̀rọ̀ júwe baba etí funfun dé wáá kó o lẹ́rùtó kó e tọmọ sarwe ó wa la fi ọtí 30 ta a mọ́lẹ̀ ti di tí lọ*_
wikipedia
yo
Kọ́lá Akínlàdéìtàn ìgbésí ayé òǹkọ̀wéa bí Kọ́lá Akínlàdé ní ọdún 1924, ní ìlú Ayétòrò ní ìpínlẹ̀ Ògùn ní ilẹ̀ Nàìjíríà..
wikipedia
yo
Àwọn òbí rẹ̀ ni Michel Akínlàdé àti Elizabeth Akínlàdé..
wikipedia
yo
Lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ yìí ni ó kọjá sí Ìlaròó tí ó sì dá iṣẹ́ tẹ̀wétẹ̀wé sílẹ̀ ńbẹ̀ fúnrarẹ̀ ni ó ka ìwé gba ìwé-ẹ̀rí G.C..
wikipedia
yo
O sise labẹ ijoba ipinle iwo-oorun atijọ ni ile Naijiria..
wikipedia
yo
Kị́lá Akínlàdé lọ kàwé ní Yunifásítì Ifẹ̀ ní ilẹ̀ Nàìjíríà ó sì tún padà sí ẹnu iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwọ̀-oòrùn Nàìjíríà..
wikipedia
yo
Ní ọdún 1980, ó tún gba iṣẹ́ olùkọ́ sí ìbàdàn Boys High School, Ìbàdàn, Nàìjíríà..
wikipedia
yo
Lára wọn ni Ajá to n lépa Ẹkùn, ọwọ́ tẹ Amòòkùnṣìkà, Àgbákò nílé Tẹ́tẹ́, Baṣọ̀run Oluyọlé, Ajayi, the Bishop, Chaka, The Zulu, Esther, Esther, The Queen, Abraham, ThénFriend of God, Sheu Usman Dan fodio, Òwe àti Ìtumọ̀ rẹ̀, Sàngbá fọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ..
wikipedia
yo
Ìyá rẹ̀ kú ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, ìyẹ̀ ni pé ó kú ní ọdún mẹ́ta ṣáájú bàbá rẹ̀..
wikipedia
yo
Ikú bàbá rẹ̀ tí ó gbọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ ni ó gbé e wálé..
wikipedia
yo
Ìyàwó mẹ́rin ni Àkàndé Orímóògùnjẹ́ tí ó jẹ́ ìyá Dúró ti kú, ó ku mẹ́ta..
wikipedia
yo
Ọmọ márùn-ún ni Àkàngbé Orímóògùnjẹ́ bí Dúró sì ní àgbà gbogbo wọn..
wikipedia
yo
Ìyaa folúké, ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó wọ̀nyí, ni ìríjú àkándé, Orímóògùnjẹ, ìyẹn ni pé òun ni ó fẹ́ran jù..
wikipedia
yo
Ìya fólúké yìí ni ó mú kọ́kọ́rọ́ séèfù jáde tí ó ṣí i tí wọn kò sì bá nnkan kan ní ibẹ̀..
wikipedia
yo
Ìgbà tí Àkàndé mú owó kẹ́yìn nínú séèfù yìí kí ó tó kú, owó tí ó wà nínú rẹ̀ ju ẹgbàáta náírà (N30,000.00)lọ..
wikipedia
yo
Ohun tí ó yani lẹ́nu ni pé Ogóje náírà (N140.00) péré ni wọ́n bá ní abẹ́ ìrọ̀rí Àkàngbé nígbà tí ó kú..
wikipedia
yo
Àgbẹ̀ oníkòkó ni Àkàngbé Orímóògùnjẹ́, bàbá Dúró nígbà ayé rẹ̀..
wikipedia
yo
Túndé Atọ̀pinpin àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ máa ń sùn ní ilé Àkàngbé nígbà ti wọ́n bá ń lọ sí ìhà Odò Ọya..
wikipedia
yo
Olófìn-íntótó, ọmọ olusínà kọ̀wé sí Túndé Atọ̀pinpìn..
wikipedia
yo
Ó dá mọ́tọ̀ dúró ni kí ó tó lọ mú un Nígbà tí wọ́n dé ojà, dírébà jẹ ẹ̀bà, ilésanmí jẹ iyán ó sì ra òòyà ní irinwó náírà (400.00ni ọjà, Olófìn-íntótó bá obìnrin kan pàdé..
wikipedia
yo
Obìnrin yìí sì mu ìgò otí kan tán ó sì mu ìkejì dé ìdajì..
wikipedia
yo
Ó yẹ kí a ṣe àkíyèsí obìnrin yìí dáadáa nítorí pé òun ni a wá fi hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó jí owó Àkàngbé Orímóògùnjẹ́ jí ní iwájú..
wikipedia
yo
Nígbà ti Olófìn-íntótó àti Ilésanmí dé Ilé-Ifẹ̀ tí wọn ń lọ, ọ̀dọ̀ Àlàó ni wọ́n dé sí..
wikipedia
yo
Àlàó ra obì àti ọtí fún Olófìn-íntótó Olófìn-íntótó mu bíà mẹ́ta..
wikipedia
yo
Àlàó ń mu ẹmu lẹ́yìn tí ó jẹun tán Ilésan sì ń mu ògógóró..
wikipedia
yo
Olófìn-íntótó gbádùn láti máà fi ọwọ pa túbọ̀mu rẹ̀..
wikipedia
yo
Irun tí ó hù sí orí ètè òkè ní ìsàlẹ̀ ibi tí imú wà ni ó ń jẹ́ túbọ̀mu..
wikipedia
yo
Ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ṣùgbọ́n ó dàbí ọmọ ọdún mọ́kànlélógún..
wikipedia
yo
Kò kàwe ṣùgbọ́n o ní ọ̀yàyà o sì máa ń ṣe àyẹ́sí ènìyàn..
wikipedia
yo
Ní ọjọ́ tí àwọn Olófin-íntótó kọ́kọ́ dé ilé rẹ̀ tí wọ́n ń gbàdúrà ó ní kí gbgbo wọn kọ orin wá bá mì gbé olúwa..
wikipedia
yo
Àwọn ọmọ Àlàó kò bá wọn kọ ẹsẹ kejì tí ó sọ wí pé 'Ọjọ́ ayée mi ń sáré lọ sópinoṣù
wikipedia
yo
Àsàmú tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Àlàó ni ó ṣe àlàyé fún bàbá rẹ̀ ìdí tí wọn kò ṣe kọ ẹsẹ kejì orin náà..
wikipedia
yo
Ilésanmí rọ́ àlá tí ó lá fún Akin Atọ̀pinpin ọmọ Olúṣínà..
wikipedia
yo
rí ẹni tí ó gbé owó ṣùgbọ́n òun kò rí ojú rẹ̀ tí òun fi ta jí..
wikipedia
yo
Ẹ jẹ́ kí á ṣe àkíyèsí àwọn nǹkan wọ̀nyí tí wọ́n mẹ́nu bà ní orí yìí..
wikipedia
yo
Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni Fólúkẹ́ - Ọmọ Àkàngbé Orímóògùnjẹ́ ni òun náà..
wikipedia
yo
Ọmọ́wùmí- Ọmọ Àkàngbé Orímóògùnjẹ́ ni òun náà Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni..
wikipedia
yo
Àṣàkẹ́ ni ó bíi yàtọ̀ sí Àkàngbé Orímóògùnjẹ́, Yéwándé nìkan ni ó tún máa ń mú owó nínú séèfù..
wikipedia
yo
Àìsàn Orímóògùnjẹ́ kò ju ọjọ́ mẹ́wàá lọ tí ó fi kú..
wikipedia
yo
Nígbà tí àwọn Olófìn-íntótó dé ilé Orímóògùnjẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí..
wikipedia
yo
Yéwándé ni ó mú wọn wọlé Kọ́kọ́rọ́ ojú ńlá séèfù yìí kìí ya Orímóògùnjẹ́..
wikipedia
yo
Àṣàkẹ́ wọlé bá wọn níbi tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìwádìí nílé Orímóògùnjẹ́..
wikipedia
yo
Wọ́n máa ń há ilẹ̀kùn yàrá Orímóògùnjẹ́ ṣùgbọ́n wọ́n máa ń fi kọ́kọ́rọ́ ibẹ̀ há orí itẹgọ́gbara..
wikipedia
yo
Ẹnikẹ́ni ní inú ilé ni ó lè mú un ní ibẹ̀ kí ó sì fi sí ilẹ̀kùn Yéwándé ni ó máa ń tọ́jú Orímóògùnjẹ́ lóru nígbà tí ó ń ṣe àìsàn..
wikipedia
yo
Yéwándé àti àwọn ọmọ náà máa ń wá tọ́jú Orímóògùnjẹ́ nígbà tí ó ń ṣàìsàn lọ́wọ́ tí àìsàn rẹ̀ bá ń yọnu..
wikipedia
yo
Ọjà Ajégbémilékè ni Yéwándé fẹ́ lọ ní ọjọ́ tí ọkọ rẹ̀ kú..
wikipedia
yo
Àlàó ni ó kó ogóje náírà (N140.00) tí wọ́n bá níbi ìgbèré Orímóògùnjẹ́ fún Yéwándé láti tójú..
wikipedia
yo
Orúkọ mìíràn tí Àkàngbé Orímóògùnjẹ́ tún ń jẹ́ ni Bándélé..
wikipedia
yo
Ẹ rántí pé eléyìí yàtọ̀ sí Bándélé orúkọ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ..
wikipedia
yo
Àwọn kan rò pé bóyá òun ni ó jí owó Orímóògùnjẹ́ tí ó sọnù..
wikipedia
yo
Nílé Orímóògùnjẹ́ níbití wọ́n ti ń ṣe ìwádìí, Ọlọ́fìn-íntótó rí ẹ̀já òwú kan tí ó wà lára ọ̀kan nínú àwọn ojú kéékèèkéé inú séèfù ó sì mú un..
wikipedia
yo
Gbọ̀ngàn ni Fọláṣadé ìyàwó àfẹ́kẹ́yìn Orímóògùnjẹ́ ń gbé..
wikipedia
yo
Ó máa ń lò tó ọjọ́ márùn-ún tàbí ọ̀sẹ̀ kan ni Ifẹ̀ ní ilé Orímóògùnjẹ́ kí ó tó padà sí Gbọ̀ngán..
wikipedia
yo
Ó yẹ kí a ṣe àkíyèsí Fọláṣadé dáadáa nítorí pé òun ni Olófìn-íntótó ra otí fún ní ọjà tíó mu ìgò otí kan àbọ̀..
wikipedia
yo
Òun ni a sì rí ní òpin ìwé pé òun ni ó jí owó Orímóògùnjẹ́ gbé..
wikipedia
yo
Ó ti tó ọdún mẹ́fà kí Akin Olófìn-íntótó ọmọ Olúṣínà àti Ọmọ́tọ́ṣọ̀ọ́ ti rí ara wọn mọ kí wọn tún tó rí ara wọn yìí..
wikipedia
yo
Àbúrò Orímóògùnjẹ́ ni Ilésanmí tí òun àti Olófìn-íntótó jọ wá ṣe ìwádìí ní ilé-Ifè..
wikipedia
yo
Bíọlá ni orúkọ ẹni tí ó ń ta ọtí Lóòótọ́, oníṣèẹ̀gùn ni Ọ̀sanyìnnínbí síbẹ̀, kò wo ẹgbẹ́ àwọn oníṣèẹ̀gùn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ ẹgbẹ́ ìlera loògùn ọ̀rọ̀..
wikipedia
yo
Awóyẹmí ni orúkọ ẹni tí ó bá àwọn Ọlọ́fìn-íntótó níbi tí wọ́n ti ń gbádùn lọ́dọ̀ Ọmọtókù..
wikipedia
yo
Ilésanmí àti Ọlọ́fin-íntótó sọ nípa ara wọn pé àwọn mọ ilẹ̀ tẹ̀ múyẹ́ (Ẹ rántí pé iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀lmúyẹ́ ni wọ́n ń ṣe)..)..
wikipedia
yo
Ajúṣefínní, ọ̀rẹ́ orímóògùnjẹ́ ni ó bá Orímóògùnjẹ́ ra ilẹ̀ tí ó ń kọ́ ilẹ̀ sí..
wikipedia
yo
Ọwọ́ Òṣúnlékè ni wọ́n ti r ailẹ̀ tí Orímóògùnjẹ́ fi ń kólé náà..
wikipedia
yo
Káyọ̀dé akọ̀wé Ọmọ́tọ́ṣọ̀ọ́ sùn ní ẹnu iṣẹ́ ìgbà tí wọ́n bi í pé kí ló dé tí ó fi sùn ni ó dáhùn pé olè ajẹ́rangbé tí àwọn ń lé ní òru ni kò jẹ́ kí àwọn sùn dáadáa..
wikipedia
yo
Ó yẹ kí á ṣe àkíyèsí pé oníṣèẹ̀gùn Ọ̀sanyìnnínbí ni olórí àwọn olè ajẹ́rangbe yìí gẹ́gẹ́ bí a ó ṣe rí i kà ní iwájú..
wikipedia
yo
Ẹran tí ó ń jí gbé yìí wà lára ohun tí ó jẹ́ kí àwọn ènìyàn fura sí Ọ̀sanyìnnínbí pé òun ló jí owó Orímóògùnjẹ́ gbé níbi tí ó ti ń tọ́jú rẹ̀ nígbà tí ó ń ṣe àìsàn..
wikipedia
yo
Ẹran mẹ́ta ni wọ́n bá ni ilé àwọn olè wọ̀nyí nítorí pé wọ́n ti jí méjì tẹ́lẹ̀..
wikipedia
yo
Nítorí pé Ọ̀sanyìnnínbí jẹ́ ọ̀gá fún àwọn olè wọ̀nyí, wọ́n mú un lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá tí ó wà ní Morèmi ní ilé-Ifè.6..
wikipedia
yo
Nígbà ti Ọlọ́fìn-íntótó gbọ́ pé wọ́n mú Ọ̀sanyìnnínbí sí àgọ́ ọlọ́pàá Morèmi, òun àti Ilésanmí lọ́ sí ibẹ̀..
wikipedia
yo
Aago mẹ́fà sí mẹ́jọ ni ọ̀gá ọlọ́pàá máa ń rí ènìyàn ṣùgbọ́n ó gbà láti rí Akin àti Ilésanmí lẹ́yìn ìgbà tí ó ti rí káàdì Akin..
wikipedia
yo
Abeokuta ni Pópóọlá wà tẹ́lẹ̀ kí wọ́n ti wá gbé e wá sí Morèmi ní Ifẹ̀ níbi tí ó ti jẹ́ ọ̀gá àwọn ọlọ́pàá ibẹ̀..
wikipedia
yo
Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n tí wọ́n ti ṣe àlàyé pé ọ̀rọ́ Ọ̀sanyìnnínbí tí wọ́n mú ni ó gbé àwọn wá ni wọ́n ṣe àlàyé pé tí ó bá jẹ́ pé òun ni ó jí owó Orímóògùnjẹ́, yóò ti ná tó ẹgbẹ̀jọ náírà (N1,600.00) nínú owó náà..
wikipedia
yo
Ẹran ti Ọ̀sanyìnnínbí jí gbé ni ó jẹ́ kí wọ́n ní ànfààní láti yẹ ilé rẹ̀ wò..
wikipedia
yo
Àwọn ọ̀rọ̀ kan wà tí àwọn eniyan sọ ní òru yìí tí ó yẹ kí á ṣe akiyesi..
wikipedia
yo
Ilésanmí ni ó kọrin pé, ‘Iyán lóúnjẹ.’Akin ni ó sọ pé, ajímutí kìí tí’akin náà ni ó sọ pé, ‘Ẹni fojú di pópó á gba póńpó lórí…’.
wikipedia
yo
Pópóọlá sọ pé, ‘Ẹni tí ó pe tóró, Á ṣẹnu tọ́ńtọ́..’ Ó yẹ kí á ṣe àkíyèsí pé Àlàó ni oríkì Pópóọlá..
wikipedia
yo
Eléyìí yàtò sí Àlàó tí ó tójú àwọn Olófìn-íntótó tí a ti ṣe àkíyèsí rẹ̀ ṣáájú..
wikipedia
yo
Nígbà tí wọ́n lọ yẹ ilé Ọ̀sanyìnnínbí wò, owó tí wọ́n bá ní ibẹ̀ jẹ́ ọgọ́sàn-án náírà (N180.00) Níní orí yìí, a ó rí òwe, ‘Afàgò kẹ́yin àparò…’ Ohun tí ó fa òwe yìí ni ẹran tí Ọ̀sanyìnnínbí jí gbé àti ẹ̀wọ̀n tí wọ́n ní yóò lọ tí ìyàwó rẹ̀ yóò sì ti bímọ kí ó tó dé..
wikipedia
yo
Àpatán òwe yìí ni, ‘Afàgò kẹ́yin àparò, ohun ojú ń wá lojú ń rí..
wikipedia
yo
Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, òògùn ni Ọ̀sanyìnnínbí wá ṣe..
wikipedia
yo
Orí yìí ni a ti mọ ìdí tí Ọ̀sanyìnnínbí fi fẹ́ràn Orímóògùnjẹ́..
wikipedia
yo
Ìdí tí ó fi fẹ́ràn rẹ̀ nip é nígbà tí Ọ̀sanyìnnínbí ń ṣe òkú ìyá rẹ̀, ó fún un ní ọgọ́rùn-ún náírà (N100.00) níbi tí kò ti sí ẹni tí ó tún fún un ju náírà márùn-ún lọ..
wikipedia
yo
Wọ́n sọ fún un pé ẹnì kan ń rọbí àti pé yóò nílò oníṣèẹ̀gùn..
wikipedia
yo
Òun sì ni àbíkẹ́yìn Yéwándé Bándélé jẹ́ ọmọ odún mẹ́jọ..
wikipedia
yo
Nípa aṣọ tí ó wọ̀ ní ọjọ́ tí ó wá sí ọ̀dọ̀ Orímóògùnjẹ́, ẹni kan sọ pé aṣọ sáfẹ́ẹ̀tì pẹ̀lú aṣọ òfì ni ó wọ̀..
wikipedia
yo
Ẹni kan sọ pé sán-ányán ni aṣọ tí ó wọ̀ níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé àwọn ọmọ́dé kìí tètè gbàgbé nnkan, Akin Olúṣínà ní kí awọ́n bèèrè ìbéèrè nípá Fáwọlé lówó Fólúkẹ́ àti Bándélé..
wikipedia
yo
Ó ní ó dé filà sán-ányán, ó wọ́ bàtà aláwọ̀ funfun ràkọ̀ràkọ̀Bándélé ni ó bomi fún Fáwọlé ní ọjọ́ tí ó wá sí ọ̀dọ̀ Orímóògùnjẹ́.folútọ ni ojoojúmọ́ ni Ọ̀sanyìnnínbí máa ń wá sọ́dọ̀ Orímóògùnjẹ́ nígbà tí Orímóògùnjẹ́ ń sàìsàn ó sì máa ń dúró di ìgbà tí wọ́n bá ń pe alẹ́ kí ó tó kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀..
wikipedia
yo
folúké ni òun rí nnkan kan bí ológbò ní àpò rẹ̀ ní ọjọ́ kan..
wikipedia
yo
Àlàó kò gbọ́ nípa ẹni tí ó ń fi kọ́kọ́rọ́ dán séèfù wò nítorí pé ó lọ sí ibì òkú ìyá Báyọ̀ ní ọjọ́ náà..
wikipedia
yo
Ìyà Bándélé ni ẹni tí ó fi kọ́kọ́rọ́ dán séèfù wò náà Orímóògùnjẹ́ kò sọ ọ̀rọ̀ ẹni tí ó fi kọ́kọ́rọ́ dán séèfù wò yìí fún Àlàó..
wikipedia
yo
Igba náírà (N200.00) ni wọ́n bá ní ilé Àṣàkẹ́, ìyẹn ìyá Bándélé nígbà tí àwọn Akin Ọlọ́fìn-íntótó yẹ ilé rẹ̀ wò..
wikipedia
yo
Ẹni tí ó fi kọ́kọ́rọ́ dán séèfù wò tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè ni Àṣàkẹ́ ìyá Bándélé..
wikipedia
yo
folúké ni ó sọ fún ìyá rẹ̀ pé Àṣàkẹ́ ń fi kọ́kọ́rọ́ dán séèfù wò..
wikipedia
yo
Aṣọ òfì ni Yéwándé wọ̀ nígbà tó wọn ń ṣe ìwádìí yìí torí òtútù..
wikipedia
yo
Ọjọ́ kejì Ọjà Ajágbénulékè ni Àṣàkẹ́ rí kọ́kọ́rọ́ tí ó fi dán séèfù wò nínú yàrá rẹ̀..
wikipedia
yo
Alaa, Akin àti Ilésanmí fi kọ́kọ́rọ́ náà dán séèfù wò, kò sí i..
wikipedia
yo
Lẹ́yìn ìwádìí ti ọjọ́ yìí, Akin Ọlọ́fìn-íntótó àti ilésanmí padà sí Ìbàdàn..
wikipedia
yo