cleaned_text
stringlengths
6
2.09k
source
stringclasses
2 values
language
stringclasses
1 value
Oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn ríya ati ìkansáárásí ni bámijí ọjọ́ gbà nígbà tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba..
wikipedia
yo
Fun ori pi pé ati imo ijinle re ti o fi han ni ilẹ̀ Germany..
wikipedia
yo
Ó gba onírúurú ẹ̀bùn fún àṣeyọrí àti àṣeyege ní òpin ẹ̀kọ́ náà..
wikipedia
yo
Pẹlu iriri ati ẹkọ to kọ ni 'London’ ati 'Germany'o di ọmọ ẹgbẹ ti a mọ si 'Overseas Broadcasters' Associationtabi Association
wikipedia
yo
Ni odun 1990 ni Ọ̀gágun Abujagun Kaká Adisa fún bámiji Ojo ni ẹbun ikansáárá sí, èyí ni ‘Oyo State Merit Award for the Best producer or The Yearcannot
wikipedia
yo
Fun imo riri eto ti o n se ni ori 'Television Broadcasting Co-operation Oyo State (bcos) so dáa dáa tí àwọn ènìyàn ń jẹ́ anfaani rẹ̀, aláyélúwà ọba Oba Emmanuel Adegboyega Adelow Oiku 1..
wikipedia
yo
Ni o fi oye Majeọba jẹ ti ilu Ibadan da a lola, ninu osu Kọkànlá ọdun 1994..
wikipedia
yo
1.5bámiJí ọjọ́ gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé Ìwé Ìtàn Àròsọ Yorùbá Ìwé Kíkọ jẹ́ ohun tí bámijí Ọjọ́ nífẹ̀ẹ́ sí..
wikipedia
yo
Ọba Adikuta jẹ́ òkèn lára ìwé méjì sí mẹ́ta tí ó ti kọ jáde.Ìwé àkọ́kọ́ tí bamijí ọjọ́ kò jáde ní mòmọ́mọ́..
wikipedia
yo
Nígbà tí bámijí ọjọ́ wà ní ilé iṣẹ́ “Radio Nigeria” ni ó ti kọ́kọ́ kọ ìwé kan tí ó pè ní Àsà àti Òrìṣà Ilẹ̀ Yorùbá..
wikipedia
yo
Ìwé yìí wà lọ́dọ̀ àwọn atẹ̀wéta tí ó gbàgbé sí wọn lọ́dọ̀ tí kò sì jáde di òní olónìí..
wikipedia
yo
Ó tún ní àwọn ìwé meji tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí yóo jáde ní àìpẹ́..
wikipedia
yo
Ìwé yìí jẹ́ àbájáde ètò kan tí ó ṣe pàtàkì lórí rédíò..
wikipedia
yo
bámijí ọjọ́ ni ó dá ètò náà sílẹ̀,ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹrin ọdún 1984..
wikipedia
yo
Ní ilẹ̀ Yorùbá pàápàá jù lọ “South West”, oun ni ó bệrệ rè, ko sí ilé iṣé redio tí ó siwaju rẹ bệrệ ètò yìí “phone in” èyí ara.a.O..
wikipedia
yo
Adéoyè (2000), 'Ìtàn Ìgbésí ayé bámijí Ofe', láti inú atupele Iwe Oba Adikuta ti bamiji Ojo Kozion Aroko fún oye Biee, Dall, OAU, Ifẹ Nigeria.Àwọn ará Nàìjíríà..
wikipedia
yo
Ìlú Ojiji jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìlú pàtàkì tó wà ni agbègbè àríwá àkọ́kọ́ ni ìpínlẹ̀ Òndó..
wikipedia
yo
Ìlú yìí wà láàárín irẹ̀ àti irun tó jẹ́ ààlà àríwá àkókò àti Èkìtì..
wikipedia
yo
Ìlú Ogi wà ní ojú ọ̀nà tó wá láti Adó-Èkìtì sí Ìkà-Àkókó ó sì jẹ́ kìlómítà mẹ́rinlàá sí ilú Ìkàlẹ̀..
wikipedia
yo
Láti Ìkàlẹ̀, Ìlú Ọgbàgi wà ní apá ìwọ̀ oòrùn tí ó sì jé pé títí tí a yó ọ̀dà sí ló so ó pọ̀ mó ìlú Ìkà tó jẹ́ ibùjókòó ìjọba ìbílẹ̀ àríwá àkókò..
wikipedia
yo
Ìlú Ogi kò jìnnà sí àwọn ìlú ńlá mìíràn ní agbègbè rẹ..
wikipedia
yo
Ní ìlà oòrùn ọgbàgi, a lè rí ilú bí i Ìkàẹní àti Arígìdì àti ní ìwọ̀ oòrùn ìlú yìí ni ìlú irun wà ní ọ̀nà tó lọ sí Adó-Èkìtì..
wikipedia
yo
Ogi jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìlú mẹ́fà tí ó tóbi jùlọ ní agbègbè àríwá àkọ́kọ́ nírorí ìwádìí sọ fún wa pé gẹ́gẹ́ bí ètò ìkànìyàn, ti ọdún `963, àwọn ènìyàn ìlú yìí ju ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n lọ nígbà náà ṣùgbọ́n èyí yóò pọntí ó ìlọ́po méjì rẹ̀ lóde òní..
wikipedia
yo
Ìlú yìí jẹ́ ìlú tí a tẹ̀dó sí ibi tí ó tẹ́jú ṣùgbọ́n tí òkè yí i po, lára àwọn òkè wọ̀nyí sì ni a ti rí òkè orókè tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn òfọ́nbọ òrìṣà òkè Orù..
wikipedia
yo
`Ojú ọ̀nà wo ìlú yìí láti àwọn ìlú tó yí i pot i ó sì jẹ́ pé èyí mú ìrìnǹjọ́ láti ọgbàgi sí ìlúkílùú ní ìpínlẹ̀ Oǹdó rọrùn..
wikipedia
yo
Àwọn ọ̀nà wọ̀nyí mú un rọrùn láti máa kó àwọn irè oko wọ̀lú láti gbogbo ìgbèríko tó yí ìlú Ogi ká..
wikipedia
yo
Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ni ó wà ní ilẹ̀ Yorùbá láyé àtijọ́ àti lóde òní, bẹ́ẹ̀ náà ni a lè rí i ní ìlú Ogbẹ̀gì níbi tó jẹ́ pé púpọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtijọ́ ní ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n ń ṣe..
wikipedia
yo
IṢẸ́ ÀGBẸ̀ TÓ JẸ́ PÀTÀKÌ IṢẸ́ ÀWỌN YORÙBÁ LÓ RÍ ÀWỌN Oríṣìíríṣìí IṢẸ́ MÌÍRÀN..
wikipedia
yo
Iṣẹ́ àwọn ọkùnrin ni ẹmu-dídá tó tún ṣe pàtàki tẹ́lẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀..
wikipedia
yo
Òwò ṣíṣe, oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà tàbí iṣẹ́ ọwọ́ bí i agbọ̀n híhun, irun gígẹ̀, iṣẹ́ alágbẹ̀dẹ, ilẹ̀ mímọ́ àti iṣẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà..
wikipedia
yo
Iṣẹ́ àwọn obìrin sì ni aṣọ híhun, irun dídì, òwò ṣíṣe àti àwọn oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ìjọba tí ọkùnrin àti obìnrin ń ṣe..
wikipedia
yo
Nípa iṣẹ́ àgbẹ̀ tí wọn ń ṣe, púpọ̀ nínú oúnjẹ wọn ló wá láti ìlú yìí tí ó sì jẹ́ ìwọ̀nba díẹ̀ ní oúnjẹ tí a ń kó wọ̀lú..
wikipedia
yo
Iṣẹ́ ẹmu-dídá pàápàá ti fẹ́ ẹ bori iṣẹ́ mìíràn gbogbo nitori èrè púpọ̀ ni àwọn tó n dá a n ri lórí rẹ̀ ti ó si jẹ pé àwọn àgbẹ̀ oníkókó kò lè fọwọ́ rọ́ àwọn àdému sẹhin nitori ẹmu-dídá kò ni àsìkò kan pàtó, yípo ọdún ni wọ́n ń dá a..
wikipedia
yo
IṢẸ́ ẹmu-dida yìí ṣe pàtàkì nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kíwọ́ ni a lè rí ní ìlú yìí àti ní gbogbo ọkọ̀ wọn..
wikipedia
yo
Àwọn àdému wọ̀nyí máa ń gbin igi ògùrọ̀ sí àwọn bèbè odò bí àwọn àgbẹ̀ oníkókó ṣe máa ń gbin kòkó wọn..
wikipedia
yo
Èyí ló sì mú kí àwọn tó ń ta ẹmu ní Ìkà, Arigìdì, Ugbe, irun àti Ósanm máa wá sí ìlú Orù wá ra ẹmu ní ojoojúmọ́..
wikipedia
yo
Bí a ti rí àwọn òṣìṣẹ́ ìjóná tí iṣẹ́ ń gbé wá sí ìlù ọgbàgi náà ni a rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ọgbàgi tí iṣẹ́ ìjọba gbé lọ sí ibòmíràn, nítorí náà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí ìbá wà láàárín ìlú yìí ni wọ́n wà lẹ́hìn odi..
wikipedia
yo
Awon osise ijoba ti a le ri ni aarin ilu naa ni awon oluko awon olopaa, osise ile ifowopamo, osise ile ifiweranṣẹ ati awon osise ijoba ibile..
wikipedia
yo
Ìdí tí a Fir i àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba wọ̀nyí ní àwọn àǹfààní tí ìjọba mú dé ìlú yìí bí i kíkọ́ ilé ìgbẹ̀bí àti Igboogun, ilé ìdájọ́ ìbílẹ̀, ilé ìfìwéránṣẹ́, ilé ìfowópamọ́, ọjà kíkọ́, ilé ọlọ́pàá àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-ẹ̀kọ́ gíga àti ilé-ẹ̀kọ́ kéékèèkéé..
wikipedia
yo
Nípa ti ẹ̀sìn, àwọn oríṣìí ẹ̀sìn mẹta pàtàki ti a lè ri lóde òni ni ilẹ̀ Yorùbá naa ló wà ni ọgbagi..
wikipedia
yo
Fún àpẹẹrẹ, a lè rí ẹ̀sìn ìbílẹ̀ àti àwọn ẹ̀sìn ìgbàlódé tó jẹ́ ẹ̀sìn Kirisite àti ẹ̀sìn Mùsùlùmí..
wikipedia
yo
Ninu ẹ̀sìn ìbílẹ̀ ni a ti rí oríṣìíríṣìí àwọn oriṣa tí wọn ń sìn, èyí tí oriṣa òkè ọgbàgi jẹ́ ọ̀kan pataki tó wà fún gbogbo ìlú Ogi..
wikipedia
yo
Bí a ti rí àwọn tó jẹ́ pé wọn kò ní ẹ̀sìn méjì ju ẹ̀sìn ìbílẹ̀ ni a rí àwọn mìíràn tó wà nínú àwọn ẹ̀sìn ìgbàlódé wọ̀nyí síbẹ̀ tí wọ́n tún ń nípa nínú bíbọ àwọn òrìṣà inú ẹ̀sìn ìbílẹ̀..
wikipedia
yo
Eléyìí le jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹṣin ìdílé tàbí àwọn àwòrò òrìṣà tó jẹ́ dandan fún wọn láti jẹ oyè àwòrò bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́sìn mìíràn ni wọ́n nítorí ìdílé wọn ló ń jẹ oyè náà..
wikipedia
yo
Esin ìbílẹ̀ ko jẹ alatako fun esinkesin ni wongba ti esin naa ba le mu ire ba awon olùsìn..
wikipedia
yo
Àpèjúwe mi yìí kò ní kún tó tí mo bá fẹnu ba gbogbo nǹkan láìsọ ẹ̀yà èdè tí ìlú Ogbẹ̀ ń sọ..
wikipedia
yo
Ní agbègbè àkọ́kọ́, oríṣìíríṣìí èdè àdúgbò tó jẹ́ ara ẹ̀yà èdè Yorùbá ni a lè rí, nítorí ìdí èyí, ó ṣe é ṣe kí ọmọ ìlú kan máa gbọ́ èdè ìlú kejì tí kò ju kìlómítà méjì sí ara wọn..
wikipedia
yo
Nítorí náà, ó dàbí ẹni pé iye ìlú tí a lè rí ní agbègbè àríwá àkókò tàbí ní àkọ́kọ́ ní àpapọ̀ ní iye ẹ̀yà èdè tí a lè rí..
wikipedia
yo
Ṣugbọn a rí àwọn ìlú díẹ̀ tí wọ́n gbọ́ èdè ara wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyàtọ̀ wà díẹ̀díẹ̀ ninu wọn..
wikipedia
yo
Ó ṣe é ṣe kí irú ìyàtọ̀-sára èdè yìí ṣẹlẹ̀ nípa oríṣìíríṣìí ogun abẹ́lé tí ó ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá láyé àtijọ́ nítorí èyí mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti oríṣìíríṣìí ẹ̀yà tẹ̀dó sí agbègbè yìí tí ó sì fa sísọ onírúurú èdè tó yàtọ̀ sí ara wọn nítorí agbègbè yìí jẹ́ ààlà láàárín ìpínlẹ̀ Òndó, Kwara àti Bendel lóde òní.Nítorí ìdí èyí, èdè Ogi jẹ́ àdàpọ̀ èdè Èkìtì àti ti àkọ́kọ́ ṣùgbọ́n èdè Èkìtì ló fara mọ́ jùlọ nítorí ìwọ̀nba ni àwọn ìyàtọ̀ tó wà nínú èdè Ogi àti ti Èkìtì gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn nínú àwọn orin àti ewì tí mo gbà sílẹ̀..
wikipedia
yo
Fún ìdí èyí, kò ní ṣòro rárá fún ẹni tó wá láti Èkìtì láti gbọ́ èdè Ogi tàbí láti sọ èdè Ogi ṣùgbọ́n ìṣòro ni fún ẹni tó wá láti ìlú mìíràn ní àkọ́kọ́ láti gbọ́ èdè Ogi tàbí láti sọ ó yàtọ̀ sí àwọn ìlú díẹ̀ ní àkókò tí wọ́n tún ń sọ ẹ̀yà èdè Èkìtì bẹ́ẹ̀..
wikipedia
yo
Fún àpẹẹrẹ, ọmọ ìlú irun, àfin, ẹsẹ̀ àti ìró tí wọ́n wà ni agbègbè kan náà pẹ̀lú ọgbàgi lè sọ tàbí gbọ́ èdè Ogi pẹ̀lú ìrọ̀rùn..
wikipedia
yo
Bí ó ti wù kí ìṣòro gbígbọ́ èdè yìí pọ̀ tó, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àǹfààní tí mo ní láti ṣiṣẹ́ láàárín àwọn ará ìlú yìí fún ọdún márùn ún tí ó mú kí n lè gbọ́ díẹ̀ nínú èdè Ogigì bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lè sọ ọ́ ṣùgbọ́n mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Olóyè Òdú tó jẹ́ Olùtọ́nisọ́nà àti Olùrànlọ́wọ́ mi tó jẹ́ ọmọ Ọgbàgi tó sì gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Yorùbá láti ṣe àlàyé lórí àwọn nǹkan tó ta kókó èyí tí ó sì mú kí iṣẹ́ ìwádìí yìí rọrùn láti ṣe.Ẹ lè kà síwájú Sila.
wikipedia
yo
Adulójú (1981), ‘Ìlú Ogi', Láti Inú ’Ọdún Òrìṣà Òkè Ogi ní Ìlú Ogi Akoko', Àpilẹ̀kọ fún Oyè Bíee, Dall Ód Oodua, Ifẹ̀, ojú-ìwé 1.Àwọn
wikipedia
yo
Ibitòye (1981), ‘Ilu ire-Ekiti', lati inu ’ Ogun ni ilu ìrẹ-Ekiti apileko fun oye biEE, Dall, OAU, Ife, Nigeria, ojú-iwe 1-3.I-Ekiti je ilu kan ni agbegbe Ariwa Ekiti ni Ipinle Ondo; eyi ti o je okan ninu awon omo bibi inu Ipinle Iwọ-oorun atijọ..
wikipedia
yo
Tí eniyan bá gba ojú títì ọlọ́dà wọ ìlú ire, ó rí bí kilomita marundinlogoji sí ìkọ́lé-Èkìtì tí í ṣe olú ìlú fún gbogbo agbègbè àríwá Èkìtì..
wikipedia
yo
Ṣugbọn ó fi díẹ̀ lé ní ogóje kìlómítà láti Ilé-Ifẹ̀..
wikipedia
yo
Nígbà tí a bá gba ọ̀nà yìí, lẹ́hìn tí a dé ìlúpéjú-Èkìtì ni a óò wá yà kúrò ní títì ọlọ́dà sí apá ọ̀tún..
wikipedia
yo
Ọ̀nà apá ọ̀tún yẹn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣe ni a óo wà tó dé ire-Ekiti, kilomita marun-un ibi tí a ti máa yà jẹ sí ìlú ire-Ekiti..
wikipedia
yo
Àwọn gan-an pàápàá sì tilẹ̀ fi ọwọ́ sọ aya pé láti Ilé-Ifẹ̀ ni àwọn ti wá..
wikipedia
yo
Wọ́n tún tẹnu mọ́ ọ dáradára pé ibẹ̀ ni àwọn ti gbé adé ọba wọn wá..
wikipedia
yo
Nítorí náà, títí di oní olónìí, Onírè ti ilú ìrẹ-Èkìtì jẹ́ ògbóntagí kan nínú àwọn Ọba aládé tí ó wà ní Èkìtì..
wikipedia
yo
Gẹ́gẹ́ bí n óo ti ṣe àlàyé ní orí keji ìwé àpilẹ̀kọ yìí, “Òní-eré” ni ìtàn sọ fún wa pé wọ́n gé kúrú sí “Onírè” ti ìsinyìí..
wikipedia
yo
Àlàyé Samuel Johnson nínú The History of the Yorùbá..
wikipedia
yo
sì ti fi yé wa pé nítorí oríṣìíríṣìí òkè tí ó yí gbogbo ẹ̀yà Yorùbá tí a ń pè ní Èkìtì ká, ni a ṣe n pè wọ́n bẹ́ẹ̀..
wikipedia
yo
Ìtàn sì tún fi yé mi pé ìlú kékeré kan tí ó ń jẹ́ “Igbó Irun” ni àwọn ará ìrẹ-Èkìtì ti sì wá sí ibi tí wọ́n wà báyìí; àìsàn kan ló sì lé wọn kúrò níbẹ̀..
wikipedia
yo
"Igbó irun" ti di igbó ní ìsinyìí, ṣùgbọ́n apá àríwá iré-Èkìtì ló wà..
wikipedia
yo
Ìṣesí àwọn ará iré-Èkìtì kò yàtọ̀ sí ti àwọn ìlú Yorùbá yòókù, yálà nípa aṣọ wíwọ̀ tàbí àṣà mìíràn..
wikipedia
yo
Àwọn náà kò kéré nípa gbígba ẹ̀sìn òkèèrè mọ́ra nígbà tí gbogbo ilẹ̀ Yorùbá mìíràn ń ṣe èyí..
wikipedia
yo
ẹṣin ìjọ páádi àti ti Lárúbáwá ni a gbọ́ pé wọ́n gbárùkù mọ́ jù..
wikipedia
yo
Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n ṣì ń ráyè gbọ́ ti ẹ̀sìn ìbílẹ̀ Yorùbá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní àwọn àdúgbò tí èyí múmú láyà wọn jù..
wikipedia
yo
Fun àpẹrẹ, mo tọ́ka si àwọn àdúgbò ti wọ́n ti mọ̀ nípa òrìṣà ogun dáadáa nínú àwòrán..
wikipedia
yo
Nitori naa, ìyàtọ̀ ti o wa laarin èdè Ekiti ati ti Yoruba Kariaye naa lo wa ni tiwọn..
wikipedia
yo
Fún àpẹẹrẹ wọn a máa pa àwọn kọ́ńsónáǹtì kan bíi 'w' jẹ..
wikipedia
yo
Wọ́n á pe “Owó,” ‘Tun' “àwòrò” ní “eo", “Ouro",a”a”
wikipedia
yo
Wọ́n tún lè pa ‘H’ gan-an jẹ; kí wọ́n pe "Alanini “Aére..
wikipedia
yo
Àbá yóò dípò baba ìjọ yóò dípò ọjọ́ gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀, àwọn náà tún máa ń fi fáwẹ́lì ‘u’ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀..
wikipedia
yo
Nítorí náà, mo kàn sì ń ṣe àlàyé rẹ̀ léré ni, n óo tún máa mẹ́nu bà wọ́n nígbà tí a bá ń ṣe atupayá èdè orin ogun..
wikipedia
yo
Ọ̀rá Igbóminaagbègbè Ila-Ọ̀ràngún ni Ọ̀rá-Ìgbómìnà Wà..
wikipedia
yo
Ìlú Ọra-Ìgbómìnà ló dúró bí afárá tí a lè gùn kọjá sí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ìpínlẹ̀ Òndó, àti ìpínlẹ̀ Kwara..
wikipedia
yo
ìkóríta ìpínlẹ̀ mẹtẹ̀ẹ̀ta ni ọrá-Ìgbómìnà wà, ṣùgbọ́n ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni wó ṣírò rẹ̀ mọ́..
wikipedia
yo
kilomita mẹtala ni ọrá-Ìgbómìnà si ila-Ọ̀ràngún to wà ní ìpínlẹ̀ Oyo, kilomita mẹta péré ni ọ̀rá si aránorin tó wà ní ìpínlẹ̀ Kwara, ó sì jẹ́ kìlómítà kan péré sí ọ̀sán Èkìtì tó wà ní ìpínlẹ̀ Ondo.Ilé-Ifẹ̀ ni àwọm ọrá ti wà ni òòró òjò..
wikipedia
yo
Ìtàn àtẹnudẹ́nu fi yẹ ní pé kì í ṣe ọ̀rá àkọ́kọ́ ni wọ́n wà báyìí..
wikipedia
yo
Ni nkan bi ọ̀rìnlé-ẹdẹgbẹta ọdun sẹhin ni wọn tẹ ibi ti wọn wa báyìí dó..
wikipedia
yo
Ọ̀rá-Ìgbómìnà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìlú tí ogun dààmú-púpọ̀ ní ayé àtijọ́..
wikipedia
yo
Ninu àwọn ogun tí itan sọ fun ni po dààmú ọ̀rá ni - ogun Ìyápọ̀ (ìyáàpọ̀), ogun jalumi, Ekiti parapo, ati ogun Ògbun-ẹ̀fọn..
wikipedia
yo
Ní àkókò náà, àwọn akọni pọ̀ ní ọrá lábẹ́ ìsoko Akesin ọba wọn..
wikipedia
yo
Àwọn ògbógi olórí ogun nígbà náà ni ‘Ẹkìn ajagunmo àti ẹnikò lmodi la ti òkè-ọ̀pọ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ológun mìíràn..
wikipedia
yo
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló fi ìbẹ̀rù-bojo sá kúrò ní ìlú ní àkókò ogun..
wikipedia
yo
Nígbà tí ogun rọlẹ̀, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ nínú àwọn tó ti ságun lọ padà wá sí ọ̀rá ṣùgbọ́n àwọn mìíràn kò padà mọ́ títí di òní olónìí..
wikipedia
yo
Àwọn òkèewu tó jẹ́ aládùúgbò ọ̀rá náà sì kúrò ni kéṣagbe ìlú wọn, wọ́n sì wá sí ọ̀rá..
wikipedia
yo
Nínú àwọn tí kò padà sí ọ̀rá mọ́, a rí àwọn tó wà ní rorẹ́, ọmú-àrán, ìlòfa àti Ìbàdàn..
wikipedia
yo
Ní àkókò tí mò ń kọ ìwé yìí, ìlú méjì ló papò tí a ń pè ní Ọ̀rá-Ìgbómìnà - Ọ̀rá àti Òkèẹ̀wù, ìlù ọlọ́ba sin i méjèèjì..
wikipedia
yo
ÌṢẸ̀DÁ ÌLÚ Ọ̀rá-Ìgbómìnà nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàn ìṣẹ̀dá àwọn ìlú Yorùbá jẹ́ Àtẹnudẹ́nu, Ó máa ń ṣòro láti sọ ní pàtó pé báyìí-báyìí ni ìlú kan ṣe ṣe..
wikipedia
yo
Nígbà míràn a lè gbọ́ tó bí ìtàn méjì, mẹ́ta, tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nípa bí ìlú kan ṣe ṣe..
wikipedia
yo
Ohun tí a gbọ́ ni a kọ sílẹ̀ ní eréfèé nítorí kì í kúkú ṣe orí ìtàn ìlú ọ̀rá-Ìgbómìnà gan-an ni mo ń kó ìwé lé, ṣùgbọ́n bí òǹkàwé bá mọ díẹ̀ nínú ìtàn tó jẹ mọ́ ìṣẹ̀dá ìlú ọ̀rá-Ìgbómìnà, yóò le gbádùn gbogbo ohun tí a bá sọ nípa ọdún òrìṣà eléfọn ní ọ̀rá-Ìgbómìnà tí mo ń kọ ìwé nípa rẹ̀..
wikipedia
yo
Ìtàn kan sọ pé àwọn ènìyàn ìlú Irà Ìgbómìnà kì í ṣe ọ̀kan náà láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ wá..
wikipedia
yo
Àwọn òkè-òpó àti òkè kànga wá láti Ọ̀yọ́ ilẹ̀, àwọn mìíràn sì wá láti èpè àti ilẹ̀ tapa..
wikipedia
yo
Kò sí ẹni tó lè sọ pé àwọn ilé báyìí-báyìí ló kọ́kọ́ dé ṣùgbọ́n gbogbo àwọn agbolé náà parapọ̀ sábẹ́ àkóso Akesin tó jẹ́ ọmọ alápá-Ménì láti ilẹ̀ ọ̀ọ̀rámifẹ́ ní Ilé-Ifẹ̀..
wikipedia
yo
Orúkọ ibi tí àwọn ọmọ àlàpà ti sì wá sí ọ̀rá-Ìgbómìnà náà ni wọ́n fi sọ ìlú ọ̀rá títí di oní-ọ̀rá oríjà ni wọ́n ti ṣì wá, wọ́n sì sọ ibi tí wọ́n dó sí ní ọ̀rá..
wikipedia
yo